MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Bí Àwọn Tọkọtaya Ṣe Lè Túbọ̀ Ṣe Ara Wọn Lọ́kan
Àpẹẹrẹ àtàtà ni Ábúráhámù àti Sérà jẹ́ fún àwọn tọkọtaya torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn. (Jẹ 12:11-13; 1Pe 3:6) Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni nǹkan máa ń dùn láàárín wọn, àwọn ìgbà kan sì wà tí wọ́n kojú ìṣòro. Ẹ̀kọ́ wo làwọn tọkọtaya lè kọ́ lára wọn?
Ẹ máa bára yín sọ̀rọ̀ déédéé. Máa ṣe sùúrù tí ẹnì kejì rẹ bá fìbínú sọ̀rọ̀ sí ẹ tàbí tó kanra mọ́ ẹ. (Jẹ 16:5, 6) Ẹ máa wáyè fún ara yín. Ẹ jẹ́ kó máa hàn nínú ọ̀rọ̀ yín àti bẹ́ ẹ ṣe ń hùwà pé ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ẹ má ṣe fi àjọṣe yín pẹ̀lú Jèhófà ṣeré rárá. Ìyẹn gba pé kẹ́ ẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kẹ́ ẹ máa gbàdúrà, kẹ́ ẹ sì jọ máa sin Jèhófà. (Onw 4:12) Táwọn tọkọtaya bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, èyí máa fògo fún Jèhófà tó jẹ́ Olùdásílẹ̀ ètò ìgbéyàwó.
WO FÍDÍÒ NÁÀ BÍ TỌKỌTAYA ṢE LÈ TÚBỌ̀ ṢE ARA WỌN LỌ́KAN, KÓ O SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Kí ló fi hàn pé nǹkan ò lọ dáadáa láàárín Shaan àti Kiara?
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn tọkọtaya máa sọ tọkàn wọn nígbà gbogbo?
Ẹ̀kọ́ wo ni Shaan àti Kiara kọ́ lára Ábúráhámù àti Sérà?
Kí ni Shaan àti Kiara ṣe kí nǹkan lè máa lọ dáadáa láàárín wọn?
Kí nìdí tí kò fi yẹ káwọn tọkọtaya máa retí pé kò ní síṣòro nínú ìgbéyàwó wọn?
Ẹ mú kí ìgbéyàwó yín túbọ̀ lágbára!