Rírí Ìṣọ̀kan Ará Tòótọ́ Nínú Fídíò, United by Divine Teaching
Alábòójútó àyíká kan wà níbi tí wọ́n ti ń bá obìnrin kan tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí wá sí ìpàdé ìjọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó rọ obìnrin náà láti wo fídíò United by Divine Teaching. Lọ́sẹ̀ yẹn, obìnrin yẹn wá sí ìpàdé, ó sì sọ pé inú òun dùn láti wà níbẹ̀. Kí ló dé tí fídíò yìí fi tètè ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀? Ohun tó wú obìnrin náà lórí ni bí fídíò yìí ṣe ṣàfihàn ìṣọ̀kan ará tí ń bá a lọ nínú ayé tó kún fún ìwà ipá àti ìkórìíra yìí.—Jòh. 13:35.
Wo fídíò yìí kí o lè rí àlàáfíà àti ìfẹ́ tó wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé, kí o sì mọ̀ ọ́n lára. Lẹ́yìn náà, kí o ronú nípa àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:
(1) Kí nìdí tí “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” fi jẹ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ tó bá a mu fún àpéjọpọ̀ ọdún 1993 sí 1994?—Míkà 4:2.
(2) Kí ni òtítọ́ Bíbélì ti ṣe fún àwọn ìdílé kan? Kí ló ti ṣe fún ìdílé tìrẹ?
(3) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí èèyàn jẹ́ ẹni tí Jèhófà kọ́?—Sm. 143:10.
(4) Irú àwọn ìṣòro wo la gbọ́dọ̀ borí láti ṣètò àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé ńláńlá?
(5) Láwọn àpéjọpọ̀ Kristẹni tó o ti lọ, ọ̀nà wo lo fi rí i pé Sáàmù 133:1 àti Mátíù 5:3 ní ìmúṣẹ?
(6) Ẹ̀rí gbangba gbàǹgbà wo ló wà pé ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ní ipa tó lágbára?—Ìṣí. 7:9.
(7) Ìrìbọmi ọlọ́pọ̀ èrò wo ló tóbi jù lọ tí àwọn Kristẹni tòótọ́ tíì ṣe rí?
(8) Àwọn ọ̀rọ̀ wo tí Míkà, Pétérù, àti Jésù sọ ló ń ní ìmúṣẹ láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
(9) Kí ló fi hàn ọ́ pé ìdílé aláyọ̀ tó wà níṣọ̀kan kì í ṣe àlá lásán?
(10) Ta lo máa fi fídíò yìí hàn, kí sì ni ìdí rẹ̀?
Lẹ́yìn tí arábìnrin kan wo fídíò yìí tán, ọ̀rọ̀ àtàtà tó fi ṣàkópọ̀ rẹ̀ ni pé: “Fídíò yìí yóò túbọ̀ ràn mí lọ́wọ́ láti fi sọ́kàn pé ọ̀pọ̀ Kristẹni ará jákèjádò ayé wà táwọn náà ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí. . . . Ìṣọ̀kan ará wa mà ṣeyebíye o!”—Éfé. 4:3.