ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/01 ojú ìwé 8
  • Nítorí Kí Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nítorí Kí Ni?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dídarí Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ sí Ètò Àjọ Náà Tí Ó Wà Lẹ́yìn Orúkọ Wa
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Máa Lọ sí Àwọn Ìpàdé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Bí A Óò Ṣe Fi Ìwé Ìmọ̀ Sọ Àwọn Ènìyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Bá A Ṣe Lè Ran Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Wa Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ṣèrìbọmi—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 10/01 ojú ìwé 8

Nítorí Kí Ni?

1 Nítorí kí la ṣe ń darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé? Ṣe ká ṣáà lè mú káwọn èèyàn ní ìmọ̀, kí ìgbésí ayé wọn sunwọ̀n sí i, tàbí kí wọ́n lè ní ìrètí aláyọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la ni? Rárá o. Ìdí pàtàkì tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a fẹ́ sọ wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi! (Mát. 28:19; Ìṣe 14:21) Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kí àwọn tí a ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ. Bí wọn yóò bá tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó di dandan kí wọ́n lóye ètò àjọ Kristẹni dáadáa.

2 Bí A Ṣe Lè Rí I Ṣe: Láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, máa bá a lọ láti rọ akẹ́kọ̀ọ́ náà pé kí ó máa wá sí àwọn ìpàdé ìjọ. (Héb. 10:24, 25) Ṣàlàyé bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ṣe fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun, tí yóò ràn án lọ́wọ́ nínú ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, tí yóò sì jẹ́ kí ó lè máa gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ tó lárinrin pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn táwọn náà ń sapá láti yin Jèhófà. (Sm. 27:13; 32:8; 35:18) Bí ìwọ alára ti ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ ìjọ àti àwọn ìpàdé Kristẹni tí o sì mọrírì wọn, ìyẹn yóò mú kí akẹ́kọ̀ọ́ náà fẹ́ láti lọ sí ìpàdé.

3 Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ẹni tuntun lóye pé ètò àjọ Jèhófà jẹ́ ẹgbẹ́ ará tó kárí ayé. Fi fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name àti Our Whole Association of Brothers hàn wọ́n. Ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ ni Jèhófà ń lò jákèjádò ayé láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Jẹ́ kí àwọn ẹni tuntun wọ̀nyẹn mọ̀ pé a ké sí àwọn pẹ̀lú láti wá sin Ọlọ́run.—Aísá. 2:2, 3.

4 Ayọ̀ ńláǹlà ló máa ń jẹ́ bí a bá rí i tí ẹnì kan tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní tòótọ́. Ohun tá a fẹ́ ṣe gan-an nìyẹn!—3 Jòh. 4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́