Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Mar. 15
“Ǹjẹ́ o gbà pé ìṣàkóso òdodo lè mú kí ayé yìí dára láti gbé ju bó ṣe wà yìí lọ? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jọ̀wọ́ kíyè sí ìlérí tí Bíbélì ṣe. [Ka Sáàmù 37:11.] A lè gbádùn irú àlàáfíà bẹ́ẹ̀. Àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí sọ̀rọ̀ nípa Aṣáájú tó pegedé kan tó máa mú ìlérí àlàáfíà yìí ṣẹ.”
Jí! Apr. 8
“Ìsẹ̀lẹ̀ ti gbẹ̀mí àìmọye èèyàn, ó sì ti ba ọ̀pọ̀ ohun ìní jẹ́. Àwọn tó bá rù ú là sábà máa ń di aláìnílélórí, láìsí ìrètí bí wọ́n ṣe lè rí ilé mìíràn. Ìtẹ̀jáde Jí! yìí jẹ́ ká mọ bí àwọn tó ti kàgbákò ìsẹ̀lẹ̀ ṣe kojú àwọn àbájáde rẹ̀. Ó tún ṣàlàyé bí ìsẹ̀lẹ̀ ṣe jẹ́ ara àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì kan nínú Bíbélì.”
Ilé Ìṣọ́ Apr. 1
“Jẹ́ kí n fi kókó amọ́kànyọ̀ kan hàn ọ́ látinú Bíbélì. [Ka Mátíù 22:37.] Kí lo rò pé èyí túmọ̀ sí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Wo àpilẹ̀kọ yìí, ‘Fi Ọkàn àti Èrò Inú Rẹ Wá Ọlọ́run.’ Ṣé inú ọkàn nìkan ni ìjọsìn tòótọ́ gbọ́dọ̀ wà ni, àbí ó tún kan èrò inú wa? Ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn á là wá lóye.”
Jí! Apr. 8
“Bí ìwọ náà ṣe mọ̀, bíbójú tó ìdílé kò rọrùn lásìkò tá a wà yìí, iṣẹ́ kékeré sì kọ́ ni àwọn ìyá ń ṣe nínú ìdílé. Ìtẹ̀jáde Jí! yìí ṣàlàyé kókó kan tó fani mọ́ra lórí ipa tí àwọn ìyá ń kó, ìyẹn ni pé ‘Jíjẹ́ Abiyamọ—Ṣé Ó Béèrè Pé Kí Obìnrin Ní Àkànṣe Ànímọ́?’ Inú mi á dùn láti fi ẹ̀dà yìí sílẹ̀ fún ọ.”