Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Ìṣọ́ Mar. 15
“A fẹ́ láti ké sí ọ wá sí ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lọ́jọ́ Sunday, April 4. [Ṣàlàyé nípa títọ́ka sí ìsọfúnni tó wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn yìí tàbí ìwé ìkésíni sí Ìṣe Ìrántí tí a tẹ̀. Lẹ́yìn náà ka Lúùkù 22:19.] Àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé ohun tí ayẹyẹ yìí túmọ̀ sí àti bí a ṣe máa ń ṣe é.”
Ile Ìṣọ́ Apr. 1
“Ṣàṣà ni àyọkà Bíbélì táwọn èèyàn máa ń méfò lé lórí bí àpèjúwe tí Bíbélì ṣe nípa àmì ẹranko náà. Ǹjẹ́ o ti gbọ́ nípa rẹ̀ rí? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Ìṣípayá 13:16-18.] Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tá a lè fi mọ ìtumọ̀ ohun ìjìnlẹ̀ yìí. Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí àwọn nǹkan náà jẹ́.”
Jí! Apr. 8
Lẹ́yìn tó o bá ti mẹ́nu kan ìṣẹ̀lẹ̀ búburú kan táwọn èèyàn ṣì ń ronú nípa rẹ̀, béèrè pé: “Ǹjẹ́ o tíì ronú rí nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ láti máa ṣẹlẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Jákọ́bù 1:13.] Àpilẹ̀kọ yìí, tí a dìídì kọ nítorí àwọn ọ̀dọ́, ṣàlàyé ìdí tí Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ ò ṣe tíì ṣe nǹkan kan láti fòpin sí ìyà tó ń jẹ ọmọ aráyé.”
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ ìtàn ìgbésí ayé Mósè dáadáa. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o mọ̀ pé Mósè sọ nǹkan kan tó ṣe pàtàkì nígbèésí ayé wa lónìí? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Diutarónómì 18:15.] Ìtẹ̀jáde Jí! yìí jíròrò ẹni tí wòlíì tí a sọ tẹ́lẹ̀ náà jẹ́ àti ohun tó máa ṣe fún àǹfààní aráyé.”