Máa Bá A Nìṣó Láti Jàǹfààní Nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí!
Níwọ̀n bí kò ti ní sí ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! mọ́, ó yẹ ká sapá láti rí i pé àwa akéde ìjọ àtàwọn tá à ń wàásù fún kò pàdánù èyíkéyìí lára àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn wa bó bá ti ń dé.
Ẹ̀dà Ti Olúkúlùkù: Tí ìwé ìròyìn tó ò ń gbà nípasẹ̀ ètò ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn bá ti tán, fi kún iye tó o fẹ́ máa gbà láti ìsinsìnyí lọ lórí káńtà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kí àwọn òbí sọ iye ìwé ìròyìn tó máa tó gbogbo ìdílé láti lò kí kálukú lè ní ẹ̀dà tirẹ̀. Bó o bá kọ orúkọ rẹ sórí ẹ̀dà tìrẹ, o ò ní ṣèèṣì fi síta nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Nígbà tí àwọn ìwé ìròyìn tuntun bá ti dé, kí arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìròyìn jẹ́ kí àwọn tó bá fẹ́ gbà wọ́n ní Gbọ̀ngàn Ìjọba rí ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan gbà lójú ẹsẹ̀.
Àwọn Tá À Ń Mú Ìwé Ìròyìn Lọ Fún Déédéé: Kí àwọn akéde sapá láti máa mú ìwé ìròyìn tuntun lọ fún gbogbo àwọn olùfìfẹ́hàn tó bá nífẹ̀ẹ́ láti máa gba ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan. Mímú ìwé ìròyìn lọ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ á fún wa láǹfààní láti mú kí ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn túbọ̀ pọ̀ sí i, àti láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, October 1998, ojú ewé 8.
Àwọn Tí Wọ́n Nílò Ètò Àkànṣe: Bí ẹnì kan bá fi ojúlówó ìfẹ́ hàn àmọ́ tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ tí a kò yàn fúnni, a lè ṣètò fún un lákànṣe kó lè máa gba ìwé ìròyìn nípasẹ̀ ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn. Bí ẹnì kan tí ń gbé ní ìpínlẹ̀ ìjọ bá nífẹ̀ẹ́ láti máa gba ìwé ìròyìn àmọ́ tí kò ṣeé ṣe láti máa mú un lọ fún un déédéé, a lè jíròrò èyí pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ. Bí wọ́n bá fọwọ́ sí i, a lè ṣètò ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn fún olùfìfẹ́hàn náà. A lè lo àwọn fọ́ọ̀mù tá a dìídì ṣe fún ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn (M-1-YR àti M-101-YR) láti ṣe èyí.
Ó dá wa lójú pé Jèhófà yóò máa bá a nìṣó láti bù kún gbogbo ìsapá wa láti pòkìkí Ìjọba náà nípasẹ̀ Ilé Ìṣọ́ àti Jí!