Bí A Ṣe Lè Rí Ìtẹ́lọ́rùn Nípa Tẹ̀mí Gbà
1 Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” tí à ń wọ̀nà fún yóò fún wa ní àgbàyanu àǹfààní láti rí ìtẹ́lọ́rùn nípa tẹ̀mí gbà. Gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ nípa tara ṣe ń ṣara lóore, ó dájú pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí á ṣe wa lóore nípa tẹ̀mí nípa fífi “àwọn ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́” bọ́ wa. (1 Tím. 4:6) Yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. A tún ń retí láti gba ìmọ̀ràn àti ìṣírí tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àwọn àdánwò tí à ń kojú nínú ìgbésí ayé. Jèhófà mú un dá wa lójú pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” (Sm. 32:8) Tiwá mà kúkú ti dára o, pé ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ló ń darí ìgbésí ayé wa! Wo àwọn ohun kan tá a lè ṣe ká bàa lè jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ látinú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà.
2 A Ní Láti Múra Ọkàn Wa Sílẹ̀: Ojúṣe olúkúlùkù wa ni láti pa ọkàn ìṣàpẹẹrẹ wa mọ́. (Òwe 4:23) Èyí ń béèrè pé ká máa kára wa lọ́wọ́ kò, ká má sì tan ara wa jẹ. Ìgbà àpéjọ jẹ́ àkókò láti ronú jinlẹ̀ lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà, ó sì tún jẹ́ àkókò láti “wo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín.” Láti múra ọkàn wa sílẹ̀ kó lè ṣeé ṣe fún wa láti “tẹ́wọ́ gba gbígbin ọ̀rọ̀ náà sínú,” a ní láti fi tọkàntọkàn bẹ Jèhófà pé kó ṣàyẹ̀wò wa látòkèdélẹ̀, kó jẹ́ ká mọ ‘ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára’ tí ó nílò àtúnṣe lára wa, kí ó sì ṣamọ̀nà wa ní “ọ̀nà àkókò tí ó lọ kánrin.”—Ják. 1:21, 25; Sm. 139:23, 24.
3 Fetí Sílẹ̀ Kó O sì Ṣàṣàrò: Jésù kan sáárá sí Màríà nítorí bó ṣe tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Màríà yan ìpín rere, a kì yóò sì gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.” (Lúùkù 10:39, 42) Bí a bá ní irú ẹ̀mí kan náà, a ò ní gba àwọn ọ̀ràn tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì láyè láti pín ọkàn wa níyà. A ó rí i dájú pé a wà lórí ìjókòó láti gbádùn gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, a ó sì fetí sílẹ̀ dáadáa. A ò kàn ní máa sọ̀rọ̀ ṣáá tàbí ká máa rìn kiri láìnídìí, a ó sì tún ṣọ́ra láti má ṣe pín ọkàn àwọn ẹlòmíràn níyà pẹ̀lú tẹlifóònù alágbèérìn, ohun èlò atanilólobó, kámẹ́rà, àti ẹ̀rọ tí a fi ń gba ohùn àti àwòrán sílẹ̀.
4 Nígbà tá a bá ń fetí sí àsọyé, ó dára láti máa kọ àkọsílẹ̀ tó ṣe ṣókí tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bí olùbánisọ̀rọ̀ ṣe ń ṣàlàyé kókó ọ̀rọ̀ náà. A ní láti so ohun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gbọ́ mọ́ ohun tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Èyí yóò jẹ́ ká lóye ọ̀rọ̀ náà, yóò sì jẹ́ kó máa wà lọ́kàn wa fún ìgbà pípẹ́. Nígbà tá a bá ń ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ wa, ńṣe ló yẹ ká máa ṣe é pẹ̀lú ète àtifi ọ̀rọ̀ náà sílò. Kálukú wa lè béèrè pé: ‘Báwo ni èyí ṣe kan àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà? Àwọn àtúnṣe wo ló yẹ kí n ṣe nínú ìgbésí ayé mi? Báwo ni mo ṣe lè fi ìsọfúnni yìí sílò nínú àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn? Báwo ni mo ṣe lè lò ó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi?’ Ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn kókó tá a gbádùn gan-an pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ṣíṣe nǹkan wọ̀nyí yóò ṣèrànwọ́ fún wa láti máa ‘pa àwọn àsọjáde Jèhófà mọ́ sínú ọkàn-àyà wa.’—Òwe 4:20, 21.
5 Ẹ Jẹ́ Ká Máa Fi Ohun Tí À Ń Kọ́ Sílò: Lẹ́yìn tí arákùnrin kan dé láti àpéjọ àgbègbè kan tó lọ, ó sọ pé: “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà jẹ́ èyí tó kan ẹnì kọ̀ọ̀kan gbọ̀ngbọ̀n, ó ń gbúnni ní kẹ́ṣẹ́ láti ṣàyẹ̀wò ohun tó wà lọ́kàn ẹni, àti ohun tó wà lọ́kàn àwọn yòókù nínú ìdílé ẹni, ó sì tún ń súnni láti pèsè ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ látinú Ìwé Mímọ́ nígbà tó bá yẹ. Ó ti jẹ́ kí n túbọ̀ mọ ojúṣe mi dunjú láti ṣèrànwọ́ púpọ̀ sí i fún ìjọ.” Ọ̀pọ̀ lára wa lè ti ronú bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Àmọ́ kò tó láti kàn kúrò ní àpéjọ ní ríronú pé a kúkú ti gba ìṣírí, ó sì ti fún wa lókun. Jésù sọ pé: “Bí ẹ bá mọ nǹkan wọ̀nyí, aláyọ̀ ni yín bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.” (Jòh. 13:17) A ní láti máa sapá taápọntaápọn láti fi àwọn kókó tó bá kálukú wa wí sílò. (Fílí. 4:9) Èyí gan-an lohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti rì ìtẹ́lọ́rùn nípa tẹ̀mí gbà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Ṣàṣàrò Lórí Ohun Tó O Gbọ́:
■ Báwo ló ṣe kan àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà?
■ Báwo ló ṣe nípa lórí àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn?
■ Báwo ni mo ṣe lè fi í sílò nínú ìgbésí ayé mi àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi?