ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/03 ojú ìwé 8
  • Òtítọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òtítọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . Ń Sa Agbára”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . Ń Sa Agbára”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Ṣó O Máa Ń Ṣalágbàwí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • ‘Ẹ Máa Rìn Nínú Òtítọ́’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 5/03 ojú ìwé 8

Òtítọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

1. Àwọn ìsọfúnni pàtàkì wo ló wà nínú Bíbélì?

1 Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Òtítọ́ ni kókó inú ọ̀rọ̀ rẹ.” (Sm. 119:160) Jèhófà ń tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí fún wa ní ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé. Ó ń fún àwọn tó bá ní ìṣòro ní ìtùnú àti ìrètí. Ó tún ń fọ̀nà tá a lè gbà sún mọ́ òun hàn wá. Obìnrin onímọrírì kan sọ pé: “Ńṣe ni kíkẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látinú Bíbélì dà bí ìgbà tẹ́nì kan bá fi ibì kan tó ṣókùnkùn biribiri sílẹ̀ tó wá wọnú yàrá kan tó mọ́lẹ̀ rekete, tó sì tuni lára pẹ̀sẹ̀.” Ǹjẹ́ ò ń sakun láti sọ fáwọn ẹlòmíràn nípa òtítọ́ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà táǹfààní rẹ̀ bá ṣí sílẹ̀?

2. Báwo ni Bíbélì ṣe ń mú ìgbésí ayé àwọn èèyàn sunwọ̀n sí i?

2 Agbára Àtiyíni Padà àti Láti Fani Mọ́ra Jákèjádò Ayé: Òtítọ́ Bíbélì lágbára láti gún ọkàn-àyà ní kẹ́sẹ́ àti láti yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn padà. (Héb. 4:12) Ìṣekúṣe, ọtí àmujù àti ìjoògùnyó ti wọ̀ ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Rosa lẹ́wù. Ó ní: “Lọ́jọ́ kan, tí gbogbo nǹkan tojú sú mi, tọkọtaya Ẹlẹ́rìí kan bá mi sọ̀rọ̀ nípa bí Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro wa. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì gbádùn mọ́ mi gan-an. Láàárín oṣù kan péré, ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ti fún mi lágbára láti bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésí ayé ọmọlúwàbí. Ní báyìí tí mo ti ní ète nínú ìgbésí ayé, mi ò gbára lé ọtí líle àti oògùn mọ́. Níwọ̀n bó ti jẹ mí lọ́kàn gidigidi láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, mo pinnu láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀. Bí kì í bá ṣe ọgbọ́n Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ṣeé mú lò, ó dá mi lójú pé ní báyìí, mi ò bá ti gbẹ̀mí ara mi.”—Sm. 119:92.

3. Kí nìdí tá ò fi gbọ́dọ̀ fà sẹ́yìn láti ṣàjọpín ìsọfúnni tó wà nínú Bíbélì pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn?

3 Láìdàbí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìwé lónìí, onírúurú èèyàn látinú ‘gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, ènìyàn àti ahọ́n’ ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ń fà lọ́kàn mọ́ra. (Ìṣí. 7:9) Ohun tí Ọlọ́run sì fẹ́ ni “pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Nítorí náà, a kò gbọ́dọ̀ ronú láé pé ẹnì kan ò ní fetí sílẹ̀ sí ìhìn rere náà tìtorí ibi tó ti wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní láti ṣàjọpín ìhìn Ìjọba náà pẹ̀lú gbogbo èèyàn, kí a sì máa ṣe èyí tààràtà látinú Bíbélì nígbàkigbà tó bá ṣeé ṣe.

4. Báwo la ṣe lè lo Bíbélì nígbà tá a bá ń jẹ́rìí?

4 Máa Lo Ìwé Mímọ́: Ọ̀pọ̀ àǹfààní la ní láti lo Bíbélì lóde ẹ̀rí. Nígbà tó o bá ń fi ìwé ìròyìn lọni, gbìyànjú láti fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ìgbékalẹ̀ tá a dábàá kún un. Nígbà táwọn kan bá ń lo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni fún oṣù náà, wọ́n ń rí i pé ó gbéṣẹ́ láti fi kíka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí wọ́n ti fara balẹ̀ yàn kún ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn. Nígbàkigbà tó o bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú onílé kó o lè ràn án lọ́wọ́ láti gba ìmọ̀ pípéye ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Nígbà tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, jẹ́ kí ìjíròrò náà dá lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣe kókó. Láwọn ìgbà tí kì í bá ṣe pé o wà nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, jẹ́ kí Bíbélì máa wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún lílò torí ìgbà tí àǹfààní láti wàásù lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà bá máa ṣí sílẹ̀.—2 Tím. 2:15.

5. Kí nìdí tá a fi ní láti sakun láti lo Bíbélì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

5 Ǹjẹ́ kí a ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti jàǹfààní nínú agbára òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ń súnni ṣiṣẹ́ nípa lílo Bíbélì ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní rẹ̀ bá ṣí sílẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.—1 Tẹs. 2:13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́