ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/01 ojú ìwé 1
  • “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . Ń Sa Agbára”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . Ń Sa Agbára”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . Ń Sa Agbára”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Jẹ́ Kí Ẹ̀kọ́ Rẹ Máa Yíni Lérò Pa Dà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Máa Lo Bíbélì Lọ́nà Tó Múná Dóko
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Ṣó O Máa Ń Ṣalágbàwí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 5/01 ojú ìwé 1

“Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run . . . Ń Sa Agbára”

1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.” (Héb. 4:12) Kí lóhun tó sọ yẹn túmọ̀ sí? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí ìhìn rẹ̀, tó wà nínú Bíbélì lè ní ipa tó lágbára lórí àwọn èèyàn. Ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ní agbára láti yí ìgbésí ayé ẹni padà sí rere. Ìtùnú àti ìrètí tó ń fúnni ń mú àwọn èèyàn sún mọ́ Olùfúnni-Ní-Ìyè, Jèhófà Ọlọ́run. Ìhìn rẹ̀ lè mú kí àwọn olóòótọ́ ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí rìn ní ọ̀nà tó lọ sí ìyè ayérayé. Ṣùgbọ́n, láti lè ṣe àṣeyọrí yìí, a gbọ́dọ̀ lo Bíbélì nígbà tí a bá ń jẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn.

2 Ka Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Kan Ní Gbogbo Ìgbà Tí Àǹfààní Bá Ṣí Sílẹ̀: Ó dà bíi pé ọ̀pọ̀ akéde tí sọ ọ́ di àṣà pé kí wọ́n má máa fi bẹ́ẹ̀ lo Bíbélì lóde ẹ̀rí. Ṣé ìwọ náà ń ṣe bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ó dà bí ẹni pé ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ ní àkókò fún ìjíròrò gígùn, bóyá o ti wá sọ ọ́ dàṣà ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ pé kí o fi ìwé nìkan lọni tàbí kí o kàn tún ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan sọ lọ́rọ̀ ẹnu. A fún gbogbo akéde níṣìírí pé kí wọ́n máa sapá gidigidi láti ka ẹsẹ kan ó kéré tán látinú Bíbélì nígbà tí wọ́n bá ń wàásù ìhìn rere náà, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ẹni náà rí i pé inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni iṣẹ́ tí a ń jẹ́ ti wá ní tòótọ́.

3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé díẹ̀ làwọn èèyàn tó sọ kíka Bíbélì dàṣà, wọ́n ṣì ń bọ̀wọ̀ fún un ní gbogbo gbòò. Kódà àwọn èèyàn tọ́wọ́ wọn máa ń dì sábà máa ń lo ìṣẹ́jú díẹ̀ láti tẹ́tí sí ìhìn tí a bá kà ní tààràtà látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tí a bá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yíyẹ kan tọ̀yàyàtọ̀yàyà tí a sì ṣe àlàyé rẹ̀ ní ṣókí, agbára tí ọ̀rọ̀ Jèhófà ní lè ní ipa rere lórí ẹni tó bá gbọ́ ọ. Ṣùgbọ́n báwo lo ṣe lè so ọ̀rọ̀ tí o sọ ní ìbẹ̀rẹ̀ mọ́ kíka ẹsẹ kan látinú Bíbélì?

4 Gbìyànjú Èyí Nínú Iṣẹ́ Ìwé Ìròyìn: Alábòójútó arìnrìn-àjò kan lo Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́ nígbà tó ń kópa nínú iṣẹ́ ìwé ìròyìn. Ó fi Bíbélì kékeré kan sínú àpò aṣọ rẹ̀. Lẹ́yìn tó bá ti fi ìwé ìròyìn lọni tí ó sì sọ̀rọ̀ nípa àpilẹ̀kọ kan ní ṣókí, yóò ṣí Bíbélì láìsí pé ó ń fọ̀rọ̀ falẹ̀, yóò sì ka ẹsẹ kan tó bá àpilẹ̀kọ náà mu. O lè ṣe èyí nípa wíwulẹ̀ béèrè pé, “Kí lèrò rẹ nípa ìlérí tó ń fúnni níṣìírí yìí?” kí o sì wá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí o yàn.

5 Fi í ṣe góńgó rẹ láti bá gbogbo ẹni tó bá fetí sílẹ̀ ṣàjọpín ẹsẹ Bíbélì kan tàbí méjì. Agbára rẹ̀ tí ń súnni ṣiṣẹ́ lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn èèyàn púpọ̀ sí i láti sún mọ́ Ọlọ́run.—Jòh. 6:44.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́