ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/04 ojú ìwé 8
  • Máa Lo Bíbélì Lọ́nà Tó Múná Dóko

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Lo Bíbélì Lọ́nà Tó Múná Dóko
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Bó Ṣe Tọ́ àti Bó Ṣe Yẹ?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Mímúra Bá A Ṣe Máa Lo Ìwé Ìròyìn Sílẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Apá Kẹta: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Nínasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 9/04 ojú ìwé 8

Máa Lo Bíbélì Lọ́nà Tó Múná Dóko

1. Kí lo lè ṣe láti múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá?

1 Ìwé yòówù ká fẹ́ fi lọni lóde ẹ̀rí, ó dára gan-an pé ká máa wá ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó ń múni ronú jinlẹ̀ tá a máa kà fún àwọn tó bá fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. (Héb. 4:12) Lílo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan látinú ìwé tá a fẹ́ fi lọni á jẹ́ kó rọrùn fún wa láti mú ọ̀rọ̀ wa bá ohun tí ìwé náà ń sọ mu. Láwọn ibì kan, àwọn akéde ti rí i pé ó dára láti yọ Bíbélì wọn dání nígbà tí wọ́n bá fẹ́ dé ọ̀dọ̀ ẹnì kan tàbí tí wọ́n bá ń wàásù láti ilé dé ilé.

2. (a) Báwo la ṣe lè fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wa? (b) Àwọn ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ wo làwọn èèyàn máa ń nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìjọ?

2 Fi Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ: Bí àwọn akéde kan bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn, wọ́n á béèrè ìbéèrè kan tí onílé á fi sọ èrò rẹ̀ lórí ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n máa kà lẹ́yìn ìbéèrè náà. Èyí á jẹ́ kí wọ́n lè tètè mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọnú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà. Ǹjẹ́ o lè lo díẹ̀ lára àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín?

◼ “Bó o bá lágbára rẹ̀, ǹjẹ́ o lè ṣe àwọn àyípadà wọ̀nyí?” Ka Ìṣípayá 21:4.

◼ “Kí nìdí tá a fi ń gbé ní àkókò tó le koko báyìí?” Ka 2 Tímótì 3:1-5.

◼ “Ǹjẹ́ o rò pé àdúgbò wa lè dára ju bó ṣe wà lónìí bí gbogbo èèyàn bá ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò?” Ka Mátíù 7:12.

◼ “ Ǹjẹ́ o rò pé ó lè ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ rẹ gbé irú ayé dáadáa tí ibí yìí ń sọ?” Ka Sáàmù 37:10, 11.

◼ “Ǹjẹ́ o rò pé àkókò kan máa wà tí ọ̀rọ̀ yìí á ṣẹ?” Ka Aísáyà 33:24.

◼ “Ǹjẹ́ o mọ ìjọba tí ibí yìí sọ pé ó ń bọ̀?” Ka Dáníẹ́lì 2:44.

◼ “Ǹjẹ́ o ti máa ń ronú pé o fẹ́ béèrè irú ìbéèrè yìí lọ́wọ́ Ọlọ́run?” Ka Jóòbù 21:7.

◼ “Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti tún rí àwọn èèyàn wa tó ti kú?” Ka Jòhánù 5:28, 29.

◼ “Ǹjẹ́ àwọn òkú mọ ohun táwọn alààyè ń ṣe?” Ka Oníwàásù 9:5.

3. Báwo la ṣe lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye ẹsẹ Bíbélì tá a kà?

3 Ṣàlàyé Ẹsẹ Ìwé Mímọ́, Lo Àpèjúwe, Kó O sì Sọ Bí A Ṣe Lè Fi Sílò: Bí ẹnì kan bá fàyè sílẹ̀ fún ìfọ̀rọ̀wérọ̀, má ṣe fi ìkánjú sọ̀rọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, fara balẹ̀ ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o bá kà, lo àpèjúwe, kó o sì sọ bó ṣe lè fi í sílò, kí ẹni náà bàa lè lóye ohun tó o kà. (Neh. 8:8) Báwọn èèyàn bá lóye ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì gbà pé òtítọ́ ni, ó lè mú kí wọ́n ṣe àwọn ìyípadà tó pabanbarì nígbèésí ayé wọn.—1 Tẹs. 2:13.

4. Báwo la ṣe lè lo Bíbélì lọ́nà tó múná dóko nígbà ìpadàbẹ̀wò?

4 Máa lo Bíbélì lọ́nà tó múná dóko bó o ṣe ń padà lọ bẹ ẹni náà wò. O lè ṣe ohun yìí nígbà tó o bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò: (1) Wá ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó máa ti ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ lẹ́yìn. (2) Béèrè ìbéèrè kan nípa ẹsẹ Bíbélì tó o fẹ́ ka, kí onílé lè sọ èrò ọkàn rẹ̀. Lẹ́yìn náà kà á. (3) Ṣàlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o kà, lo àpèjúwe kí ọ̀rọ̀ ibẹ̀ lè túbọ̀ yé e, kó o sì sọ bó ṣe lè fi i sílò. Ní gbogbo ìgbà tó o bá bẹ̀ ẹ́ wò, sapá láti mú kó rí ohun kan kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Láìpẹ́, ìpadàbẹ̀wò náà lè di ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́