ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/03 ojú ìwé 3
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àwọn Òjíṣẹ́ Tó Ń Wàásù Ìhìn Rere
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé—Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Bí Àwọn Alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ Ṣe Ń Fi Ìfẹ́ Àtọkànwá Hàn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 11/03 ojú ìwé 3

Àpótí Ìbéèrè

◼ Ṣé ó yẹ ká ròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a bá darí pẹ̀lú ìdílé ẹni fún ìjọ?

Bí Kristẹni kan tó jẹ́ òbí bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ tí àwọn ọmọ tí kò tíì ṣèrìbọmi sì ń wà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, òbí náà lè máa ròyìn ohun tí kò ju wákàtí kan àti ìpadàbẹ̀wò kan lọ lọ́sẹ̀, kó sì máa ròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lóṣù. Ohun tó yẹ kó ṣe nìyí, bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bá tiẹ̀ ń gbà ju wákàtí kan lọ, tó sì ń darí rẹ̀ ju ẹ̀ẹ̀kan lọ lọ́sẹ̀, tàbí tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọ náà lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.—Wo ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 104.

Bí gbogbo àwọn tó wà nínú agboolé kan bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí tó ti ṣèrìbọmi, ká má ṣe ròyìn àkókò tí a fi darí ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà (àyàfi bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ náà bá ṣì ń ka ìwé kejì lẹ́yìn ìrìbọmi). Ìdí ni pé kìkì ohun tí àkọsílẹ̀ iṣẹ́ ìsìn pápá tí à ń ròyìn wà fún ni àwọn ohun tí à ń ṣe nígbà tí a bá ń wàásù ìhìn rere tí a sì ń fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ àwọn tí kì í ṣe ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ṣe ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Àmọ́ ṣá o, èyí ò dín ìjẹ́pàtàkì dídarí irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ déédéé kù.

Ẹrù iṣẹ́ àwọn Kristẹni tó jẹ́ òbí ni láti máa ṣèkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Àwọn tó bá nílò ìrànlọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tàbí tí wọ́n fẹ́ mú un sunwọ̀n sí i lè ní kí àwọn alàgbà ran àwọn lọ́wọ́. Bó bá bọ́gbọ́n mu pé kí akéde mìíràn darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan pẹ̀lú ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin kan tí kò tíì ṣèrìbọmi láti inú ìdílé èyíkéyìí tí ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ, kí a fi èyí tó alábòójútó olùṣalága tàbí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn létí. Bí wọ́n bá fọwọ́ sí i pé kí a darí irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀, ẹni tó ń darí rẹ̀ lè ròyìn rẹ̀ bó ṣe máa ròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì èyíkéyìí mìíràn.

Kíkọ́ àwọn ọmọ láti máa rìn ní ọ̀nà Jèhófà ṣe pàtàkì gan-an ju àkókò àti ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá tí à ń ròyìn lọ. (Diu. 6:6-9; Òwe 22:6) Ó yẹ ká gbóríyìn fún àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ òbí fún gbígbé ẹrù iṣẹ́ wíwúwo ti títọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfé. 6:4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́