Fara Wé Ẹ̀mí Ìrònú Jésù
1. Ẹ̀mí ìrònú wo ni Jésù ní?
1 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò rí Ọmọ Ọlọ́run rí, kíka àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ti jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gidigidi. (1 Pét. 1:8) Nítorí àtiṣe ohun tí Baba rẹ̀ fẹ́, ó fi ipò gíga tó wà lọ́run sílẹ̀, ó sì wá sórí ilẹ̀ ayé. Nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi àìmọtara-ẹni-nìkan ṣèránṣẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn, ó sì fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí ìran èèyàn. (Mát. 20:28) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé: “Ẹ pa ẹ̀mí ìrònú yìí mọ́ nínú yín, èyí tí ó wà nínú Kristi Jésù pẹ̀lú.” Báwo la ṣe lè fara wé ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ rẹ̀?—Fílí. 2:5-8.
2. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ lára àwọn Kristẹni, kí ló sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ìṣòro yìí?
2 Nígbà Tó Bá Rẹ̀ Wá: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, ó máa ń rẹ òun náà. Nígbà kan, ó ‘ti rẹ̀ ẹ́ nítorí ìrìn àjò tó rìn,’ síbẹ̀ ó jẹ́rìí kúnnákúnná fún obìnrin ará Samáríà kan. (Jòh. 4:6) Lóde òní, ó máa ń rẹ ọ̀pọ̀ lára àwọn Kristẹni bákan náà. Lẹ́yìn tá a bá ti ṣiṣẹ́ àṣekára láàárín ọ̀sẹ̀, ó lè má rọrùn láti jáde òde ẹ̀rí. Àmọ́ o, bá a bá ń jáde òde ẹ̀rí déédéé, a óò rí i pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni máa ń tuni lára nípa tẹ̀mí.—Jòh. 4:32-34.
3. Báwo la ṣe lè fara wé ẹ̀mí ìmúratán láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ tí Jésù ní?
3 Lákòókò mìíràn, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń lọ sí ibi tó dá kí wọ́n lè sinmi díẹ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn mọ ibi tí wọ́n ń lọ, wọ́n sì sáré lọ pàdé wọn. Dípò kí Jésù máa kanra, ńṣe ni ‘àánú àwọn èèyàn náà ṣe é,’ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí “kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” (Máàkù 6:30-34) A ní láti ní irú ẹ̀mí ìrònú kan náà bá a bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká sì máa darí rẹ̀. Ó pọn dandan pé ká ní ìforítì, ká sì ní ìfẹ́ àtọkànwá fún àwọn èèyàn. Bó ò bá ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kankan tó ò ń darí báyìí, má ṣe juwọ́ sílẹ̀ nínú ìsapá rẹ láti wá ọ̀kan.
4. Báwo ni iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara wé ẹ̀mí ìrònú Kristi?
4 Fi Àwọn Nǹkan Tẹ̀mí Sípò Àkọ́kọ́: Iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Arábìnrin ọ̀dọ́ kan kọ̀wé pé: “Màmá ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi rọ èmi àti ọmọ rẹ̀ pé ká jẹ́ kí àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jọ ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù kan. Inú mi dùn gan-an pé a bá a ṣe é. Inú mi sì tún dùn bí mo ṣe túbọ̀ mọ àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin sí i, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí dà bí mọ̀lẹ́bí mi. Láfikún sí i, mo tún ní ọ̀pọ̀ àǹfààní láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, kí n sì kọ́ wọn ní àwọn àgbàyanu ẹ̀kọ́ òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Gbogbo èyí jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀.”—Sm. 34:8.
5. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó nínú ìsapá wa láti fara wé ẹ̀mí ìrònú Jésù?
5 Gbogbo wa là ń bá ẹran ara aláìpé wa wọ̀yá ìjà bí a ṣe ń sapá láti mú inú Jèhófà dùn. (Róòmù 7:21-23) A gbọ́dọ̀ gbéjà ko ẹ̀mí ìmẹ́lẹ́ tó jẹ́ ẹ̀mí ayé yìí. (Mát. 16:22, 23) Jèhófà lè fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe èyí yọrí. (Gál. 5:16, 17) Bí a ti ń dúró de ìdáǹdè wa sínú ayé tuntun Ọlọ́run níbi tí òdodo yóò ti gbilẹ̀, ǹjẹ́ kí a máa fara wé ẹ̀mí ìrònú Jésù nípa fífi ire Ìjọba Ọlọ́run àti ire àwọn ẹlòmíràn ṣáájú tiwa.—Mát. 6:33; Róòmù 15:1-3.