Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Ìṣọ́ Apr. 15
“Àwọn kan máa ń rò pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni gbogbo ohun tó bá ṣẹlẹ̀ láyé, títí kan àjálù. Ǹjẹ́ o tíì ronú nípa ìyẹn rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ èèyàn mọ àdúrà yìí. [Ka Mátíù 6:10b.] Kí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé, ìgbà wo sì ni ìfẹ́ rẹ̀ yìí yóò ṣẹ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́? Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí Bíbélì ṣe dáhùn ìbéèrè yìí.”
Ile Ìṣọ́ May 1
“Àwọn olórí ìsìn kan máa ń lọ́wọ́ nínú ìṣèlú nítorí kí wọ́n lè mú kí ipò nǹkan dára sí i láwùjọ. Àmọ́ o, kíyè sí ohun tí Jésù ṣe nígbà tí àwọn èèyàn fẹ́ láti fi jọba. [Ka Jòhánù 6:15.] Ohun tó máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní títí láé ni Jésù gbájú mọ́. Ìwé ìròyìn yìí jíròrò ohun náà.”
Jí! May 8
“Láyé òde òní, ó máa ń ṣe àwọn èèyàn kan bíi pé wọn ò nírètí. Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀ nígbà míì? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn èyí ka Róòmù 15:4.] Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti ní ìrètí. Wàá gbádùn bí ìwé ìròyìn Jí! yìí ṣe sọ ohun méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Ìwé Mímọ́ fi hàn pé ó jẹ́ ìdí tá a fi lè ní ìrètí.”
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bá onírúurú ìṣòro pàdé níbi iṣẹ́. Kódà, àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ máa ń yọ àwọn èèyàn kan lẹ́nu. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ìmọ̀ràn tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ wà nínú Bíbélì? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn èyí ka Òwe 15:1.] Ìwé ìròyìn yìí pèsè àwọn àbá tó wúlò nípa bá a ṣe lè wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn níbi iṣẹ́.”