Àpótí Ìbéèrè
◼ Ibo ló yẹ ká ti máa gba ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tá a fẹ́ lò fúnra wa?
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ní ẹ̀ka ọ́fíìsì, a ti fòpin sí ètò fíforúkọsílẹ̀ fún gbígba ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí à ń tẹ̀ àti èyí tí à ń ṣe sórí kásẹ́ẹ̀tì àfetígbọ́ ní gbogbo èdè, ìjọ ni kí gbogbo akéde ti máa gba ìwé ìròyìn wọn. Kìkì ohun tí a óò máa bójú tó nípasẹ̀ ìforúkọsílẹ̀ ni ìwé ìròyìn àti kásẹ́ẹ̀tì àfetígbọ́ tó wà fún àwọn afọ́jú (Braille), èyí tá a máa ń fi ránṣẹ́ sáwọn tó yẹ kó gbà wọ́n láìsí pé iléeṣẹ́ ìfìwéránṣẹ́ ń gbowó lórí rẹ̀. Jọ̀wọ́, rántí pé àwọn ìjọ lè lo fọ́ọ̀mù Congregation Requests (M-202) [Fọ́ọ̀mù Tí Ìjọ Fi Ń Béèrè fún Ìwé Ìròyìn àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa] láti fi gba ìwé ìròyìn tí wọ́n nílò. Fọ́ọ̀mù yìí náà ni kí ẹ lò tẹ́ ẹ bá fẹ́ béèrè fún ìwé ìròyìn èdè mìíràn tàbí ìwé ìròyìn onílẹ́tà gàdàgbà.
Bí ẹnì kan ní ìpínlẹ̀ rẹ bá sọ pé kó o máa mú ìwé ìròyìn wá fún òun ní gbogbo ìgbà, jọ̀wọ́ rí i dájú pé ò ń ṣe bẹ́ẹ̀ láìjáfara kí ẹni náà má bàa pàdánù ẹ̀dà èyíkéyìí. Àwọn tí a ti yọ lẹ́gbẹ́ lè gba ìwé ìròyìn tàbí ìwé mìíràn tí wọ́n fẹ́ lò fúnra wọn nídìí káńtà ìgbàwé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kí àwọn akéde má ṣe máa mú ìwé ìròyìn lọ fún àwọn tí a ti yọ lẹ́gbẹ́.
Kìkì ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn tí ẹ̀ka ọ́fíìsì yóò máa bójú tó ni ti àwọn tó jẹ́ pé àwọn akéde ò lè máa mú ìwé ìròyìn lọ fún ní gbogbo ìgbà. Bí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ bá fẹ́ fi ìwé ìbéèrè fún fíforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn ránṣẹ́ sí wa nítorí ẹnì kan tí kò ṣeé ṣe fún láti máa rí ìwé ìròyìn gbà lọ́nà mìíràn, kí akọ̀wé kọ ìwé kékeré kan pẹ̀lú rẹ̀ láti fẹ̀rí hàn pé Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ ti fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìwé ìbéèrè fún fíforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn náà, wọ́n sì ti fọwọ́ sí i.
Èyí túmọ̀ sí pé àwọn akéde kò ní láti kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì láti béèrè fún ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn tiwọn. Bí a bá rí irú ìwé ìbéèrè bẹ́ẹ̀ gbà látọ̀dọ̀ àwọn akéde tàbí olùfìfẹ́hàn, a óò dá a padà sí ìjọ onítọ̀hún.
◼ Báwo ni ẹlẹ́wọ̀n kan ṣe lè rí àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn tó fẹ́ gbà?
Bí ìjọ tó ń wàásù ní ọgbà ẹ̀wọ̀n kan bá lè pèsè ìwé ìròyìn fáwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà níbẹ̀, nígbà náà kí ẹlẹ́wọ̀n tó bá fẹ́ gbàwé máa gba àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó fẹ́ látọ̀dọ̀ àwọn akéde tó ń wá síbẹ̀. Bí èyí kò bá ṣeé ṣe, ẹlẹ́wọ̀n náà lè fúnra rẹ̀ béèrè fún ìforúkọsílẹ̀ fún ìwé ìròyìn nípa kíkọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Jọ̀wọ́, kíyè sí i pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí a ti yọ lẹ́gbẹ́ náà lè gba àwọn ìwé ìròyìn tí wọ́n bá fẹ́ gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣàlàyé nínú ìpínrọ̀ yìí.