ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/05 ojú ìwé 7
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Ọ̀nà Wo La Lè Gbà Ṣèrànwọ́?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Kí Là Ń Ṣe ní Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa?
    Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà Lóde Òní?
  • Bá A Ṣe Ń Ti Iṣẹ́ Ìwàásù Lẹ́yìn ní Ìjọ Kọ̀ọ̀kan àti Kárí Ayé
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 1/05 ojú ìwé 7

Àpótí Ìbéèrè

◼ Ọ̀nà wo ló dára jù lọ ká gbà máa fi owó ṣètìlẹyìn fún àǹfààní àwọn ará wa tó jẹ́ aláìní láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn?

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a máa ń gbọ́ pé àwọn ará wa láwọn ilẹ̀ kan ò ní àwọn ohun kòṣeémánìí nítorí inúnibíni, ìjábá tàbí àwọn ìṣòro mìíràn. Èyí ti mú kí àwọn ará kan fi owó ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà láwọn orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀. Wọ́n lè sọ pé ẹnì kan tàbí ìjọ kan pàtó, tàbí iṣẹ́ ìkọ́lé kan ni ká lo owó náà fún.—2 Kọ́r. 8:1-4.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a yin àwọn ará wọ̀nyí nítorí ẹ̀mí ọ̀làwọ́ wọn sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn ohun tá a rí pé ó ń fẹ́ àbójútó lójú ẹsẹ̀ yàtọ̀ sí èyí tí àwọn olùtọrẹ náà ní lọ́kàn. Nígbà míì sì rèé, kí irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ tó dé a lè ti bójú tó àwọn ohun tí olùtọrẹ náà ń fẹ́ ká fi ọrẹ náà ṣe. Bó ti wù kó rí, ìdánilójú wà pé tẹ́ ẹ bá fi owó ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè tí ẹ̀ ń gbé, a óò lò ó fún ohun tí olùtọrẹ náà bá sọ pé ká lò ó fún, ì báà jẹ́ ọrẹ fún ìtìlẹyìn iṣẹ́ kárí ayé, Owó Àkànlò fún Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, tàbí ètò ìrànwọ́ fún àwọn tí àjálù dé bá.

A ti kọ́ àwọn ará tó wà ní gbogbo ẹ̀ka ọ́fíìsì ní ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe lójú ẹsẹ̀ bí ọ̀ràn pàjáwìrì bá dé bá àwọn arákùnrin wa. Kò sì sí èyí tó máa ṣẹlẹ̀ tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ò ní fi tó Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso létí. Tí ìnáwó náà bá pọ̀ ju èyí tí apá ẹ̀ka ọ́fíìsì lè ká, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso lè ké sí àwọn ẹ̀ka tó bá sún mọ́ orílẹ̀-èdè náà láti ṣèrànlọ́wọ́ tàbí kí wọ́n fi owó ránṣẹ́ láti orílé-iṣẹ́.—2 Kọ́r. 8:14, 15.

Nítorí náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè tí ẹ̀ ń gbé ni kí ẹ máa fi ọrẹ tí ẹ bá fẹ́ fi ṣètìlẹyìn ránṣẹ́ sí, ì báà jẹ́ ọrẹ fún iṣẹ́ kárí ayé, ti ètò ìrànwọ́ fún àwọn tí àjálù dé bá tàbí ti iṣẹ́ ìkọ́lé láwọn ilẹ̀ mìíràn. Ẹ lè fi ránṣẹ́ nípasẹ̀ ìjọ tàbí kẹ́ ẹ fúnra yín fi ránṣẹ́. Lọ́nà yìí, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” yóò lè máa bójú tó àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó láàárín gbogbo ẹgbẹ́ ará kárí ayé létòlétò nípasẹ̀ ètò tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso gbé kalẹ̀.—Mát. 24:45-47; 1 Kọ́r. 14:33, 40.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́