Ẹ Fi Ọpẹ́ fún Jèhófà Nítorí Inú Rere Rẹ̀ Onífẹ̀ẹ́
A Ó Ṣe Ìṣe Ìrántí Ikú Kristi ní March 24
1. Báwo ni Jèhófà ṣe fi inú rere hàn sí wa?
1 Onísáàmù sọ pé: “Kí àwọn ènìyàn máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà nítorí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ àti nítorí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ fún àwọn ọmọ ènìyàn.” (Sm. 107:8) Inú rere onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kò mọ sí sùúrù àti ìgbatẹnirò tó fi ń bá aráyé lò. Ọ̀rọ̀ ìyìn kan tí Ọlọ́run mí sí jẹ́ kí kókó yìí yé wa yékéyéké, ìyẹn: “Jèhófà, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni ó ń gbé mi ró.” (Sm. 94:18) Dájúdájú, bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo kú nítorí tiwa fi hàn pé inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ pọ̀ gidigidi!—1 Jòh. 4:9, 10.
2. Báwo la ṣe lè fi ọpẹ́ fún Jèhófà?
2 Nísinsìnyí tí Ìṣe Ìrántí ikú Kristi ń sún mọ́lé, báwo la ṣe lè dúpẹ́ lọ́wọ́ “Ọlọ́run tí ń ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́”? (Sm. 59:17) Ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa wá àyè láti ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ tí Jésù lò gbẹ̀yìn lórí ilẹ̀ ayé. (Sm. 143:5) Ó tún máa dára kí á ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a dìídì ṣètò pé kí a kà lákòókò Ìṣe Ìrántí, èyí tó wà nínú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ ti ọdún 2005. Bákan náà, a tún lè ka àkòrí 112 sí 116 nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ, àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mìíràn láti lè ṣèwádìí sí i. Ronú jinlẹ̀ lórí ohun tó o kà, kó o sì jẹ́ kó wọ̀ ọ́ lọ́kàn. (1 Tím. 4:15) Tá a bá ń gbàdúrà bá a ṣe ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, yóò fún wa lókun, yóò sì tún fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.—Mát. 22:37.
3, 4. (a) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ará wa ní Làìbéríà? (b) Àwọn wo lo fẹ́ pè wá sí Ìṣe Ìrántí?
3 Fún Àwọn Ẹlòmíràn Níṣìírí Láti Fi Ọpẹ́ fún Ọlọ́run: Lọ́dún tó kọjá, àwọn èèyàn tí iye wọn jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún ó lé ọ̀kẹ́ méjìdínlógójì àti ẹgbẹ̀ta ó lé méje (16,760,607) ló wá síbi Ìṣe Ìrántí jákèjádò ayé. Ní abúlé kan lórílẹ̀-èdè Làìbéríà, pápá tí wọ́n ti ń gbá bọ́ọ̀lù ní ìlú ni àwọn ará ti ṣe Ìṣe Ìrántí yìí, baálẹ̀ ibẹ̀ sì ní kí wọ́n kéde fún gbogbo àwọn tó ń gbé àgbègbè náà pé kí wọ́n wá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé akéde márùn-ún péré ló wà ní abúlé yìí, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mẹ́rìndínlógójì (636) èèyàn ló wá síbi Ìṣe Ìrántí náà!
4 Bákan náà, ẹ jẹ́ ká rí i pé a pe ọ̀pọ̀ èèyàn pé kí wọ́n wá bá wa ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí yìí. O ò ṣe kọ orúkọ gbogbo àwọn tó o fẹ́ pè wá sílẹ̀? A lè lo àlàyé tó wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn Jí! March 8 àti Ilé Ìṣọ́ March 15 láti fi pè wọ́n wá. A tún lè lo ìwé pélébé tá a tẹ̀ láti fi pe àwọn èèyàn wá síbi Ìṣe Ìrántí. O lè lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tàbí kó o rọra fi ọwọ́ kọ ibi tá a ti máa ṣayẹyẹ yìí àti àkókò tá a máa ṣe é sára ìwé pélébé náà, kó o sì mú un fún gbogbo àwọn tó o fẹ́ pè wá. Bí March 24 ṣe ń sún mọ́lé, tún lọ rán gbogbo wọn létí, kẹ́ ẹ sì jọ ṣe gbogbo ètò tó yẹ ní ṣíṣe kí wọ́n lè wá.
5. Báwo la ṣe lè fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa níṣìírí pé kí wọ́n wá?
5 Báwo la ṣe lè ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí wá sí ìpàdé lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ayẹyẹ yìí? Ní gbogbo ìgbà tẹ́ ẹ bá ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́, máa lo ìṣẹ́jú díẹ̀ láti fi ṣàlàyé bí ayẹyẹ yìí ti ṣe pàtàkì tó fún wọn. O lè lo ohun tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ March 15, 2004, ojú ìwé 3 sí 7 àti nínú ìwé Reasoning, ojú ìwé 266 sí 269 nígbà tó o bá ń ṣàlàyé fún wọn.
6. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká kí àwọn àlejò káàbọ̀ níbi Ìṣe Ìrántí?
6 Kí Àwọn Àlejò Káàbọ̀: Níbi ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí, lọ bá àwọn àlejò kó o sì kí wọn káàbọ̀. (Róòmù 12:13) Jókòó sọ́dọ̀ àwọn tó o pè wá, kó o sì rí i dájú pé wọ́n ní Bíbélì àti ìwé orin. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká fi ọ̀yàyà kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó jẹ́ aláìṣiṣẹ́mọ́ tí wọ́n bá gbìyànjú tí wọ́n wá. Ìfẹ́ tá a ní sí wọn lè jẹ́ kí wọ́n tún máa wá sí ìpàdé déédéé. (Lúùkù 15:3-7) Níbi ayẹyẹ tó ṣe pàtàkì jù lọ yìí, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí pé kí àwọn náà wá bá wa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí “àgbàyanu inú-rere-onífẹ̀ẹ́” rẹ̀.—Sm. 31:21.