“Ẹ Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, Gbogbo Ẹ̀yin Ẹni Ìdúróṣinṣin”
A Óò Ṣe Ìrántí Ikú Jésù ní April 4
1 Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, nígbà tí orílẹ̀-èdè Ukraine ṣì wà lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì, àwọn aláṣẹ máa ń ṣọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí lójú méjèèjì, pàápàá nígbà tí ọjọ́ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa bá ti ń sún mọ́lé, kí wọ́n lè mọ ibi tí wọ́n ti fẹ́ ṣe ìpàdé náà. Èyí sábà máa ń jẹ́ ìṣòro níwọ̀n bí àwọn aláṣẹ ti máa ń mọ àárín ìgbà tí ayẹyẹ náà máa bọ́ sí. Kí làwọn ará lè ṣe? Arábìnrin kan wà tí omi máa ń kún àjàalẹ̀ ilé rẹ̀. Níwọ̀n bí àwọn aláṣẹ ò ti lè retí pé kí àwọn èèyàn kóra jọ síbẹ̀, àwọn ará ṣe pèpéle onígi kan sórí omi tó múni dé eékún náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ní láti lóṣòó lórí pèpéle náà lábẹ́ òrùlé tí kò ga púpọ̀, kò sẹ́ni tó dà wọ́n láàmú bí ìjọ wọn ṣe ń ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí tayọ̀tayọ̀.
2 Bí àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Ukraine ṣe pinnu láti ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé ká máa ṣèrántí ikú òun jẹ́ ẹ̀rí àgbàyanu nípa ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run. (Lúùkù 22:19; 1 Jòh. 5:3) Nígbàkigbà tá a bá ń kojú àwọn ìṣòro kan nígbèésí ayé, irú àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ lè fún wa níṣìírí, wọ́n sì lè mú ká pinnu láti wà níbi ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ní April 4. Nípa bẹ́ẹ̀, a ó fi hàn pé a fara mọ́ ọ̀rọ̀ onísáàmù náà tó kọrin pé: “Ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ẹni ìdúróṣinṣin.”—Sm. 31:23.
3 Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Mú Kí Ìfẹ́ Wọn fún Ọlọ́run Jinlẹ̀ Sí I: Ìfẹ́ fún Ọlọ́run tún ń sún wa láti ké sí àwọn ẹlòmíràn láti bá wa ṣèrántí ikú Jésù. Àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù February rọ gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti kọ orúkọ àwọn tá a fẹ́ pè wá sí Ìṣe Ìrántí sílẹ̀. Ǹjẹ́ ò ń fi tọkàntọkàn gbé ìgbésẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ìyẹn ni pé kó o ké sí gbogbo àwọn tó wà nínú àkọsílẹ̀ rẹ? Wá àyè láti ṣàlàyé fún wọn nípa bí ayẹyẹ náà ṣe ṣe pàtàkì tó. Bó o bá ń fi tìfẹ́tìfẹ́ rán wọn létí nípa ọjọ́ àti àkókò tí Ìṣe Ìrántí yóò wáyé, èyí lè sún wọn láti wá. Síwájú sí i, bó bá pọn dandan, o tún lè sọ pé wàá wá pè wọ́n kẹ́ ẹ jọ lọ síbi ayẹyẹ náà, èyí náà lè mú kí wọ́n wá.
4 Níbi ayẹyẹ náà, sapá láti kí àwọn tá a pè wá káàbọ̀, kó o sì mú kí ara tù wọ́n. Báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mú kí ìfẹ́ wọn fún Jèhófà jinlẹ̀ sí i? Gbìyànjú láti wà lárọ̀ọ́wọ́tó wọn kó o lè dáhùn ìbéèrè wọn. Múra tán láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ wọ́n, bó bá yẹ bẹ́ẹ̀ lákòókò yẹn. Rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa wá sí àwọn ìpàdé ìjọ tí à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ní pàtàkì jù lọ, kí àwọn alàgbà fìfẹ́ hàn sí àwọn aláìṣiṣẹ́mọ́ tó bá wá. Wọ́n lè ṣètò láti bẹ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ wò, kí wọ́n sì fún wọn níṣìírí láti tún bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ lẹ́ẹ̀kan sí i, bóyá nípa ṣíṣe àlàyé síwájú sí i lórí àwọn kókó inú àwíyé tá a sọ níbi Ìṣe Ìrántí.—Róòmù 5:6-8.
5 Mímú Kí Ìfẹ́ Tiwa fún Jèhófà Jinlẹ̀ Sí I: Ríronú jinlẹ̀ nípa ẹ̀bùn ìràpadà lè mú kí ìfẹ́ wa fún Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ jinlẹ̀ sí i. (2 Kọ́r. 5:14, 15) Arábìnrin kan tó ti ń lọ síbi ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ní: “A máa ń wọ̀nà fún Ìṣe Ìrántí. Ọdọọdún ló túbọ̀ máa ń ṣe pàtàkì lójú wa. Mo rántí pé lógún ọdún sẹ́yìn, tí mò ń wo òkú bàbá mi ọ̀wọ́n nígbà tí mo wà nínú ilé ìsìnkú, ni mo wá ní ìmọrírì àtọkànwá fún ìràpadà. Ṣáájú ìgbà yẹn, ìmọ̀ orí lásán ni mo ní nípa rẹ̀. Àní, mo mọ gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa ìràpadà mo sì lè ṣàlàyé wọn! Àmọ́, ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń dorí ẹni kodò yìí wáyé ni ọkàn mi tó wá kún fún ayọ̀ gidigidi lórí ohun tí ìràpadà ṣíṣeyebíye yẹn máa ṣe fún wa.”—Jòh. 5:28, 29.
6 Bí ọjọ́ tí a ó ṣe Ìṣe Ìrántí ti ọdún yìí ti ń sún mọ́lé, wá àyè láti múra ọkàn rẹ sílẹ̀ fún ayẹyẹ náà. (2 Kíró. 19:3) Ṣàṣàrò lórí àkànṣe Bíbélì kíkà fún Ìṣe Ìrántí, èyí tó wà nínú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2004 àti kàlẹ́ńdà wa, 2004 Calendar. Àwọn kan máa ń gbádùn ṣíṣàyẹ̀wò orí 112 sí 116 nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn. Àwọn mìíràn máa ń ṣèwádìí síwájú sí i nípa lílo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mìíràn tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye tẹ̀ jáde. (Mát. 24:45-47) Gbogbo wa lè máa rántí ẹ̀bùn ìràpadà náà nínú àdúrà àtọkànwá wa. (Sm. 50:14, 23) Nígbà Ìṣe Ìrántí yìí, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti ronú jinlẹ̀ lórí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa, ká sì máa wá ọ̀nà tá a lè gbà fi ìfẹ́ wa hàn sí i.—Máàkù 12:30; 1 Jòh. 4:10.