Apá Kẹsàn-án: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
Bó O Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Láti Jẹ́rìí Láìjẹ́ bí Àṣà
1 Nígbà tí Áńdérù àti Fílípì ti rí àrídájú pé Jésù ni Mèsáyà náà tó ń bọ̀, wọn ò lè bò ó mọ́ra ńṣe ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ fáwọn ẹlòmíràn nípa ìròyìn ayọ̀ náà. (Jòh. 1:40-45) Bákan náà lónìí, bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bá ní ìgbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n ń kọ́, àwọn náà á máa fẹ́ láti sọ fáwọn ẹlòmíràn. (2 Kọ́r. 4:13) Báwo wá la ṣe lè fún wọn ní ìṣírí pé kí wọ́n máa wàásù láìjẹ́ bí àṣà, báwo la sì ṣe lè kọ́ wọn lọ́nà tí wọ́n á fi lè ṣe é dáadáa?
2 O kàn lè bi akẹ́kọ̀ọ́ náà bóyá ó ti ń sọ nípa ẹ̀kọ́ tó ti kọ́ látinú Bíbélì fáwọn ẹlòmíràn. Ó ṣeé ṣe kó láwọn ọ̀rẹ́ tàbí àwọn míì nínú ìdílé rẹ̀ tó lè pè wá síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Tún bi í bóyá ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere wà lára àwọn tí wọ́n jọ ń ṣíṣẹ níbi kan náà, lára àwọn tí wọ́n jọ wà nílé ìwé, tàbí lára àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ mìíràn. Tó bá ń pe àwọn ẹlòmíràn síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tó sì ń sọ nípa ìhìn rere fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí i, ó máa lè tipa bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wàásù. Ràn án lọ́wọ́ láti lóye bó ṣe yẹ kó máa lo ìfòyemọ̀ kó sì máa fohùn pẹ̀lẹ́ bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn ohun tó fẹ́ gbé ṣe.—Kól. 4:6; 2 Tím. 2:24, 25.
3 Kí Wọ́n Máa Sọ̀rọ̀ Nípa Ìgbàgbọ́ Wọn: Ó ṣe pàtàkì pé ká kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Bẹ́ ẹ bá kẹ́kọ̀ọ́ dórí àwọn kókó kan, bi akẹ́kọ̀ọ́ náà pé: “Báwo lo ṣe máa fi Bíbélì ṣàlàyé òtítọ́ yìí fáwọn ará ilé rẹ?” tàbí “Ẹsẹ Bíbélì wo ló máa fi mú kí èyí dá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lójú?” Kíyè sí bó bá ṣe dáhùn, kó o sì wá fi hàn án bó ṣe lè máa fi Ìwé Mímọ́ ti ẹ̀kọ́ tó bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́yìn. (2 Tím. 2:15) Bó o ti ń ṣe èyí, ńṣe lò ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà bí yóò ṣe máa wàásù láìjẹ́ bí àṣà, àti bí yóò ṣe máa bá ìjọ jáde nínú iṣẹ́ ìwàásù nígbà tó bá tóótun.
4 Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa bí wọ́n ṣe lè kojú inúnibíni. (Mát. 10:36; Lúùkù 8:13; 2 Tím. 3:12) Bí àwọn kan bá béèrè ìbéèrè tàbí tí wọ́n sọ nǹkan kan nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìyẹn lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti wàásù. Ìwé pẹlẹbẹ náà Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́? lè mú kí wọ́n “wà ní ìmúratán . . . láti ṣe ìgbèjà.” (1 Pét. 3:15) Nínú ìwé yìí làwọn ẹni tuntun ti lè rí ìsọfúnni tó péye tí wọ́n lè fi ran àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn lọ́wọ́ bí wọ́n bá fẹ́ mọ ìdí tá a fi gba àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì gbọ́ tí wọ́n sì fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni wa.