Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìdílé—Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Ìdílé
1 Inú Jèhófà máa ń dùn tó bá rí àwọn ọmọdé tí wọ́n ń yin orúkọ rẹ̀. (Sm. 148:12, 13) Lọ́jọ́ Jésù, kódà ‘àwọn ọmọ ọmú àti ìkókó ń fi ìyìn’ fún Ọlọ́run. (Mát. 21:15, 16) Bó ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Ẹ̀yin òbí, báwo lẹ ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ káwọn náà lè dàgbà di ẹni tó ń fi ìtara yin Jèhófà nínú iṣẹ́ ìsìn Kristẹni? Lẹ́ẹ̀kan sí i, gẹ́gẹ́ bá a ṣe tẹnu mọ́ ọn nínú àpilẹ̀kọ tá a ti jíròrò nípa àwọn ìpàdé ìjọ, àpẹẹrẹ tíwọ fúnra ẹ bá fi lélẹ̀ ṣe pàtàkì. Nígbà tí bàbá kan ń sọ ọ̀rọ̀ tá a sábà máa ń gbọ́ lẹ́nu ọ̀pọ̀ òbí, ó ní: “Àwọn ọmọ ò ní ṣe ohun tó o bá kàn fẹnu lásán sọ, ohun tó o bá ṣe ni wọ́n á ṣe!”
2 Arábìnrin kan táwọn òbí tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run tọ́ dàgbà rántí pé: “Ilẹ̀ ọjọ́ Sátidé kan ò mọ́ rí, ká wá máa ronú bóyá à ń lọ sóde ẹ̀rí tàbí a kò lọ. A ti mọ̀ pé lílọ ni.” Bákan náà, o lè gbìn ín sọ́kàn àwọn ọmọ tiẹ̀ náà pé iṣẹ́ ìwàásù ṣe pàtàkì nípa ṣíṣètò ọjọ́ tí ìdílé rẹ á máa lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Yàtọ̀ sí pé àwọn ọmọ á lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú wíwò ọ́, ìwọ fúnra ẹ á tún lè máa ríbi kíyè sí ìṣesí wọn, ìwà wọn àti bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú sí.
3 Máa Kọ́ Wọn ní Ṣísẹ̀-N-Tẹ̀lé: Tí àwọn ọmọ bá máa gbádùn iṣẹ́ ìwàásù, a gbọ́dọ̀ ti kọ́ wọn láti lè mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n ṣe. Arábìnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ sọ síwájú sí i pé: “A kì í ṣe aláìfẹ́kan-án ṣe tó kàn máa ń tẹ̀ lé àwọn òbí wa lọ sẹ́nu iṣẹ́ wọn. A mọ̀ pé a ní láti lọ́wọ́ sí i, kódà bó tiẹ̀ jẹ́ ká tẹ aago ẹnu ọ̀nà lásán ni, ká sì fi ìwé ìkésíni lọ̀ wọ́n. Bá a ṣe ń múra sílẹ̀ dáadáa fún ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù òpin ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, ó máa ń jẹ́ ká mọ ohun tí a ó sọ.” Ìwọ náà lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ bẹ́ẹ̀ nípa fífi ìṣẹ́jú díẹ̀ sílẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti kọ́ wọn bá a ṣe ń wàásù, ó lè jẹ́ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tàbí nígbà mìíràn.
4 Tí ìdílé rẹ bá ń jáde òde ẹ̀rí pa pọ̀, ó máa jẹ́ kó o lè ráyè gbin òtítọ́ sọ́kàn àwọn ọmọ rẹ. Baba kan tó jẹ́ Kristẹni máa ń mú ọmọbìnrin rẹ̀ lọ́wọ́ bó bá ń fẹsẹ̀ rin ogún kìlómítà ní àlọ àtàbọ̀ láti pín ìwé àṣàrò kúkúrú Bíbélì fáwọn ará abúlé tó wà ní àfonífojì kejì. Ó níran ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì fayọ̀ sọ pé: “Òrí ìrìn yẹn ni baba mi ti ń gbin òtítọ́ sí mi lọ́kàn.” (Diu. 6:7) A retí pé kíwọ náà rí ìbùkún látinú fífi iṣẹ́ ìsìn pápá kún ìṣètò ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ìdílé rẹ.