Wíwàásù Láìsọ̀rọ̀
1 Láìsọ ohunkóhun, àwọn ohun tí Jèhófà dá ń fi àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí hàn kedere. (Sm. 19:1-3; Róòmù 1:20) Bákan náà, ìwà rere tá à ń hù, àwọn ànímọ́ Kristẹni tá a ní àti ìmúra wa tó bá ti ọmọlúwàbí mu ń wàásù fáwọn èèyàn. (1 Pét. 2:12; 3:1-4) Ó yẹ kó máa wu gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan láti máa fìwà wa “ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́ nínú ohun gbogbo.”—Títù 2:10.
2 Báwo làwa èèyàn tá a jẹ́ aláìpé ṣe lè mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ kìkì tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń jẹ́ kí agbára ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ máa darí wa. (Sm. 119:105; 143:10) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run “yè, ó sì ń sa agbára, ó mú ju idà olójú méjì èyíkéyìí lọ.” (Héb. 4:12) Ó máa ń dénú ọkàn wa, ó sì máa ń jẹ́ ká lè yí irú ẹni tá a jẹ́ pa dà sí rere. (Kól. 3:9, 10) Ẹ̀mí mímọ́ ló máa ń jẹ́ ká láwọn ànímọ́ bí inú rere, ìwà rere, ìwà tútù àti ìkóra-ẹni-níjàánu. (Gál. 5:22, 23) Ṣé gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan là ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ máa darí ìgbésí ayé wa?—Éfé. 4:30; 1 Tẹs. 2:13.
3 Àwọn Ẹlòmíì Ń Wò Wá: Àwọn èèyàn ń rí wa bá a ṣe ń tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, tá a sì ń sapá láti fìwà jọ ọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gbẹ́ni kan wà táwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ máa ń fi ṣe yẹ̀yẹ́ torí pó jẹ́ èèyàn kúkúrú. Àmọ́, arábìnrin wa kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì kan náà sábà máa ń yẹ́ ọ̀gbẹ́ni yìí sí, ó sì máa ń bọ̀wọ̀ fún un. Ìyẹn mú kí ọ̀gbẹ́ni náà fẹ́ láti mọ ìdí tí arábìnrin wa fi yàtọ̀. Arábìnrin wa ṣàlàyé fún un pé torí pé òun ń fi ìlànà Bíbélì sílò ló jẹ́ kóun máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn. Ó tún sọ fún un nípa àwọn ohun àgbàyanu tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe. Ọ̀gbẹ́ni yìí bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà tó sì yá ó ṣèrìbọmi. Nígbà tó padà sílùú rẹ̀, ìwà rere tó ń hù wú àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lórí débi pé ọ̀pọ̀ nínú wọn kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
4 Yálà a wà níbi iṣẹ́, nílé ìwé, tàbí nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn aládùúgbò wa, a lè mú káwọn ẹlòmíì máa fìyìn fún Ọlọ́run nípasẹ̀ ìwà rere tá a bá ń hù àti iṣẹ́ ìwàásù wa.—Mát. 5:16.