ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/05 ojú ìwé 7
  • Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Fi Ohun Tá À Ń Kọ́ Sílò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Fi Ohun Tá À Ń Kọ́ Sílò
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jẹ́ Kí Àwùjọ Rí Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Mímúra Ọ̀rọ̀ Tó O Máa Sọ fún Ìjọ Sílẹ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Mú Wa Gbára Dì fún Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nígbèésí Ayé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Jàǹfààní Láti Inú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun fún 1996—Apá 2
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 12/05 ojú ìwé 7

Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Fi Ohun Tá À Ń Kọ́ Sílò

1 Bí a ó ṣe máa jíròrò àwọn kókó ẹ̀kọ́ inú Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run fún ọdún 2006, ẹ jẹ́ ká sapá láti lè jàǹfààní àwọn ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́ náà nípa lílò wọ́n nínú iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ tá à ń ṣe àti nínú gbogbo ìdáwọ́lé wa ojoojúmọ́. Ẹ jẹ́ ká pinnu láti rí i pé à ń fi àwọn ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ ṣèwà hù.—Jòh. 13:17; Fílí. 4:9.

2 Nígbà Tá A Bá Ń Dáhùn: Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọdún yìí fi ìṣẹ́jú kan kún iye ìṣẹ́jú tí àwùjọ máa fi ń lóhùn sí àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé, arákùnrin tó máa ṣe iṣẹ́ yẹn gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àlàyé òun ò kọjá ìṣẹ́jú márùn-ún dípò ìṣẹ́jú mẹ́fà. Àwọn tó máa lóhùn sí i náà gbọ́dọ̀ rí i pé àwọn ò jẹ àkókò. Bí ẹni tó fẹ́ lóhùn sí i bá ti ronú dáadáa lórí ìdáhùn rẹ̀ ṣáájú, ààbọ̀ ìṣẹ́jú á tó láti fa kókó tó wúlò jáde. Ní ìpíndọ́gba, ó yẹ kí ìṣẹ́jú márùn-ún yìí lè tó fún èèyàn mẹ́wàá láti lóhùn sí i.

3 Àsọyé Tó Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́: Ẹni tó bá bójú tó àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì àti ọ̀rọ̀ ìtọ́ni gbọ́dọ̀ tẹnu mọ́ bí iṣẹ́ náà ṣe wúlò tó ní ti ọ̀nà tó gbà tan mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa àtàwọn ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́. Kì í ṣe pé kí olùbánisọ̀rọ̀ kàn sún àwùjọ láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tó sọ nìkan ni. Ó gbọ́dọ̀ sọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, ọ̀nà tí wọ́n á gbà ṣe é, kó sì sọ àǹfààní tó máa tìdí irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ yọ. Ó lè sọ pé, “Ìtọ́ni tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fún wa rèé,” tàbí “Ọ̀nà tá a lè gbà lo àwọn ẹsẹ yìí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wà rèé.” Àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí wọ́n bá mọ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ wọn gbọ́dọ̀ sapá láti ṣàlàyé ọ̀nà tí kókó tí wọ́n ń jíròrò yẹn fi ṣeé múlò ní pàtó.

4 Àwọn ará á túbọ̀ rí bí ẹ̀kọ́ náà ṣe wúlò tó, bí olùbánisọ̀rọ̀ náà bá mẹ́nu kan àwọn àpẹẹrẹ látinú Bíbélì. Lẹ́yìn tí olùbánisọ̀rọ̀ bá ti mẹ́nu kan àwọn àpẹẹrẹ kan látinú Ìwé Mímọ́, ó lè sọ pé, “Ìwọ alára lè bá ara ẹ nínú irú ipò tó fara jọ èyí.” Ó gbọ́dọ̀ rí i pé àpẹẹrẹ inú Bíbélì tóun lò bá kókó tóun ń jíròrò mu, kó bá Bíbélì mu látòkèdélẹ̀ kó sì ṣe rẹ́gí pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà ti tẹ̀ jáde.—Mát. 24:45.

5 Ọgbọ́n ni ohun tó ń jẹ́ kéèyàn lè lo ìmọ̀ àti òye lọ́nà tó dáa. “Ọgbọ́n ni ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ.” (Òwe 4:7) Bá a ṣe ń bá a lọ láti máa ṣàlékún ọgbọ́n wíwúlò tá a ní nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ǹjẹ́ ká máa sapá láti túbọ̀ mọ̀ sí i nípa ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́