Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Apr. 15
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló gbà pé lára ohun tó ń mú kí ilé kan jẹ́ ilé aláyọ̀, ọ̀kan ni jíjùmọ̀ sọ̀rọ̀ jẹ́, síbẹ̀ kì í rọrùn fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti máa jùmọ̀ sọ̀rọ̀. Kí lo rò pó fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí dábàá tó lè jẹ́ kéèyàn mọ bá a ṣeé jùmọ̀ sọ̀rọ̀.” Ka Jákọ́bù 1:19.
Ile Iṣọ May 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn káàkiri ayé ni òṣì ń ta. Kí lo rò pé a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka 1 Pétérù 2:21.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù láti gba tàwọn tálákà rò.”
Jí! Apr.–June
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sọ pé àgbélébùú ń ran àwọn lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Síbẹ̀, àwọn kan ṣì ń béèrè pé: Ǹjẹ́ ó tọ́ láti máa jọ́sìn ohun tí wọ́n lò láti ṣekú pa Jésù? Ṣé lóòótọ́ ni Jésù kú sórí àgbélébùú? Àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 12 nínú ìwé ìròyìn yìí ṣàgbéyẹ̀wò bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.” Ka Ìṣe 5:30.
“Ọ̀pọ̀ lára àwa èèyàn tá a ní ẹbí àti ọ̀rẹ́ tó jẹ́ arúgbó nílé la máa ń ṣàníyàn nípa báa ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro ọjọ́ ogbó. Àbí kí lẹ ti rí ọ̀rọ̀ náà sí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí dábàá àwọn ohun tá a lè ṣe láti dín ìnira ọjọ́ ogbó kù. Ó tún ṣàlàyé bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí á ṣe ní ìmúṣẹ.” Ka Jóòbù 33:25.