Wọ́n Ti Fi Àpẹẹrẹ Ìṣòtítọ́ Lélẹ̀
1 Iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún bímọ tuntun kan lọ́dún 1937. Iṣẹ́ ìsìn tá a máa bẹ̀rẹ̀ sí í pè ní aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lọmọ tuntun ọ̀hún. Àwọn akíkanjú ọkùnrin àtobìnrin tí wọ́n nírìírí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn láti sìn níbi yòówù tí ètò Ọlọ́run bá rán wọn lọ. Láti ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún wá títí di báyìí, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ṣì ń bá a lọ láti máa fi àpẹẹrẹ tó ṣeé fara wé tó bá dọ̀rọ̀ ìṣòtítọ́ lélẹ̀.—Héb. 6:12.
2 Wọ́n Múpò Iwájú: Àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ló gbapò iwájú nínú fifi ẹ̀rọ giramofóònù alágbèéká wàásù láti ojúlé dé ojúlé. Wọ́n tún ń lò ó láti máa fi lu àwo tí wọ́n gba ìjíròrò Bíbélì sí lórí, èyí tí wọ́n máa ń fi jíròrò Bíbélì nígbà ìpadàbẹ̀wò. Àwọn ìlú ńlá níbi tí ìjọ wà ni wọ́n ti lo àwọn ẹ̀rọ náà. Nígbà tó yá, wọ́n rán àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lọ sáwọn àdúgbò tá a ti nílò àwọn oníwàásù tó pọ̀ sí i. Wọ́n máa ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ gbogbo ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere, wọ́n á sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìjọ tuntun ni ìsapá àfọkànṣe wọn yìí bí. Àwọn akíkanjú oníwàásù wọ̀nyí ṣe bẹbẹ láìṣàárẹ̀ láti mú kí ètò Ọlọ́run yìí tóbi débi tó dé lónìí yìí. (Aís. 60:22) Àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tí iye wọn jẹ́ ọ̀tàlélẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá [750] ló wà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n sì ń bá a lọ láti máa ṣe bẹbẹ nínú títan ìhìn rere náà kálẹ̀ “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.”—Kól. 1:23.
3 Ó Tọ́ Ká Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Wọn: Àwọn kan lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe yìí ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún láti ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún. Onírúurú ipò táwọn adúróṣinṣin lọ́kùnrin lóbìnrin yìí ti dojú kọ ti sọ ìgbàgbọ́ wọn dọ̀tun. (1 Pét. 1:6, 7) Wọ́n ti fi ilé àti ọ̀nà sílẹ̀ kí wọ́n bàa lè lọ sìn láwọn ibi tá a ti nílò wọn lójú méjèèjì. Ní báyìí, àwọn kan lára wọn ti dàgbà, ara wọn ò gbé kánkán bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ó sì lè jẹ́ pé àwọn ìṣòro míì ló ń dojú kọ wọ́n. (2 Kọ́r. 4:16, 17) Síbẹ̀, wọ́n ṣì ń “gbèrú nígbà orí ewú” wọn. (Sm. 92:14) Jèhófà ni wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé, ó sì ń bù kún wọn.—Sm. 34:8; Òwe 10:22.
4 Tẹ̀gàn ni hẹ̀, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe yẹ lẹ́ni tá a gbọ́dọ̀ gbóṣùbà fún. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ń sìn ní ìjọ yín, máa sún mọ́ wọn kó o bàa lè jàǹfààní látinú ìrírí wọn. Fi hàn pé o mọrírì wọn gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Jẹ́ kí ìdúróṣinṣin wọn jẹ́ ìṣírí fún ọ. Gbogbo ẹni tó bá fara wé ìgbàgbọ́ wọn lè rí ojúure Jèhófà àti ìbùkún gbà nítorí pé “àwọn tí ń fi ìṣòtítọ́ hùwà jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.”—Òwe 12:22.