Àpótí Ìbéèrè
◼ Kí la lè ṣe láti ran àwọn aṣáájú-ọ̀nà lọ́wọ́?
Kárí ayé, ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2009, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé àti aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì ọ̀kẹ́ [800,000]. Àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún yìí ti yọ̀ǹda ohun tá a lè pè ní àkọ́so nínú àkókò, okun àtàwọn ohun ìní wọn, kí wọ́n bàa lè tan ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run kálẹ̀. (Òwe 3:9) Ó dájú pé inú Jèhófà ń dùn sí wọn gan-an bí wọ́n ṣe ń sapá yìí. Àwọn ọ̀nà wo làwa náà lè gbà fi hàn pé inú wa dùn sí àwọn aṣáájú-ọ̀nà, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ fi kún ayọ̀ àti ìfaradà wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn?
Ó dájú pé bá a bá ń sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró, èyí lè fún wọn ní ìṣírí táá jẹ́ kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà nìṣó. (Òwe 25:11) Ǹjẹ́ a lè ṣe àwọn ìyípadà kan nínú ìgbòkègbodò wa ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ká bàa lè ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn lóde ẹ̀rí? Láwọn ìgbà míì, a lè fi ọkọ̀ wa gbé wọn tàbí ká san owó ọkọ̀ wọn. (1 Kọ́r. 13:5; Fílí. 2:4) Ọ̀nà míì tá a tún lè gbà fi hàn pé tìfẹ́tìfẹ́ la fi ń ṣètìlẹ́yìn fún wọn ni pé, ká máa pe àwọn aṣáájú-ọ̀nà wá sílé wa lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti wá bá wa jẹun.—1 Pét. 4:8, 9.
Ìwé Mímọ́ fi dá wa lójú pé Jèhófà máa pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí fún àwọn tó bá wá Ìjọba rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́. (Sm. 37:25; Mát. 6:33) Ọ̀kan lára ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣe èyí ni pé ó máa ń lo ẹgbẹ́ ará Kristẹni láti ṣèrànwọ́. (1 Jòh 3:16-18) Ohun kan ni pé, àwọn aṣáájú-ọ̀nà kò retí pé kí àwọn ẹlòmíì máa gbọ́ bùkátà àwọn. Ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n má sọ ohun tí wọ́n nílò fáwọn ẹlòmíì. Síbẹ̀, a lè bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ sìn yìí “dí àìnító wọn” láwọn ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tá a bá ń wà lójúfò tá a sì lákìíyèsí.—2 Kọ́r. 8:14, 15.
Nígbà tí Fébè ajíhìnrere onítara kan ní ìjọ Kẹnkíríà ọ̀rúndún kìíní rìnrìn àjò lọ sí ìlú Róòmù, Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará tó wà ní ìlú Róòmù níyànjú pé: ‘Ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà á nínú Olúwa lọ́nà tí ó yẹ àwọn ẹni mímọ́, kí ẹ sì ṣèrànwọ́ fún un nínú ọ̀ràn èyíkéyìí tí ó ti lè nílò yín.’ (Róòmù 16:1, 2) Àǹfààní ló jẹ́ fún àwa pẹ̀lú láti fi ìfẹ́ ṣètìlẹ́yìn fún àwọn tó wà nínú ìjọ wa tí wọ́n ń wàásù ìhìn rere láìdábọ̀, ìyẹn àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.—Ìṣe 5:42.