Fi Ohun Tó Dáa Kọ́ra Kó O Lè Rí Ìbùkún Rẹpẹtẹ Gbà
1. Àǹfààní wo ló wà nínú kó o máa ṣàyẹ̀wò bó ṣe ń ṣe sí nídìí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run?
1 Nígbà tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni, ó ṣeé ṣe kó o ti máa sakun láti má ṣe jẹ́ kí àwọn ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run bíi kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni, wíwàásù àti gbígbàdúrà já létí. Ìsapá rẹ tí Jèhófà tì lẹ́yìn ló jẹ́ kí àárín ìwọ àtiẹ̀ máa dán mọ́rán sí i. Ó ṣeé ṣe kí ọdún mélòó kan ti kọjá lẹ́yìn tó o ṣèrìbọmi. Ṣó o ṣì máa ń ṣe àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, èyí tó ò ń ṣe nígbà tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ ń di Kristẹni?
2. Àǹfààní wo là ń rí nínú kíka Bíbélì lójoojúmọ́?
2 Fojú Ṣùnnùkùn Wo Àwọn Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Rẹ: Ṣó o ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́? Ìbùkún tá a máa rí gbà tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀ á mà pọ̀ o! (Jóṣ. 1:8; Sm. 1:2, 3) Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, gbogbo ọba tó bá jẹ ló gbọ́dọ̀ ka ẹ̀dà ìwé Òfin tirẹ̀ “ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀.” Èrè wo ló máa ń tìdí rẹ̀ yọ? Ó máa mú kí ọba rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ kó sì kọ́ láti bẹ̀rù Jèhófà kó má bàa yà kúrò nínú àwọn òfin Rẹ̀. (Diu. 17:18-20) Lónìí, bí àwa náà ṣe ń ka Bíbélì lójoojúmọ́ máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ aláìlẹ́bi àti ọlọ́wọ́ mímọ́ nínú ayé búburú oníwà abèṣe yìí. Ó sì tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbára dì ní kíkún fún iṣẹ́ òjíṣẹ́.—Fílí. 2:15; 2 Tím. 3:17.
3. Èrè wo ló wà nínú lílọ sí gbogbo ìpàdé?
3 Àṣà Jésù ni láti máa lọ sí sínágọ́gù níbi tí wọ́n ti máa ń jíròrò Ìwé Mímọ́. (Lúùkù 4:16) Ó dájú pé ìyẹn mú kó lè fàyà rán àdánwò tó dojú kọ ọ́. Àwọn ìtọ́ni táwa náà ń gbà láwọn ìpàdé ìjọ àtàwọn “pàṣípààrọ̀ ìṣírí” tó gbámúṣé máa ń fún wa lókun. (Róòmù 1:12) Bá a ṣe ń pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro tó ń bá àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí rìn. (Héb. 10:24, 25) Ṣó ò tíì máa pa ìpàdé jẹ?
4. Ọ̀nà wo ni lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ gbà ń ṣe wá lóore?
4 Ìwé Mímọ́ fi yé wa pé ṣe làwọn àpọ́sítélì máa ń wàásù ìhìn rere ní “ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé.” (Ìṣe 5:42) Ká tiẹ̀ ní kò lè ṣeé ṣe fún wa láti máa wàásù lójoojúmọ́, ṣé a lè jẹ́ kó mọ́ wa lára láti máa lọ́wọ́ nínú àwọn apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀? Bá a bá ń ṣe ohun tá a sọ yìí, ó dájú pé a máa túbọ̀ mọwọ́ lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ó sì lè máa nírìírí tí ń gbéni ró lẹ́nu wíwàásù òtítọ́ inú Bíbélì fáwọn èèyàn.
5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa gbàdúrà déédéé?
5 Nítorí pé Dáníẹ́lì jọ́sìn Jèhófà “láìyẹsẹ̀” jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀, ìbùkún ńlá ló rí gbà. Lára ọ̀nà tó gbà ń jọ́sìn ni pé ó máa ń gbàdúrà sí Jèhófà déédéé. (Dán. 6:10, 16, 20) Bákan náà, bá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà déédéé, ó máa fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ jíǹkí wa. (Lúùkù 11:9-13) Láfikún síyẹn, Jèhófà máa dá wa lóhùn nípa sísún mọ́ wa, á jẹ́ kí àárín àwa àtòun túbọ̀ dán mọ́rán. (Sm. 25:14; Ják. 4:8) Èrè tí ò láfiwé gbáà ni! Ǹjẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti lè rí i pé àwọn nǹkan rere tá a máa ń ṣe nínú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run ò pẹ̀dín ká bàa lè gba ìbùkún tó pọ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà.