Àpótí Ìbéèrè
◼ Àwọn ewu wo ló wà nínú bíbá ẹni tá ò mọ̀ rí sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?
Ọ̀pọ̀ ìkànnì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló wà táwọn èèyàn ti lè pàdé kí wọ́n sì fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀. Èyí tó pọ̀ lára àwọn ìkànnì wọ̀nyí lẹni kẹ́ni lè kọ ìsọfúnni nípa ara ẹ̀ sí tàbí kó tiẹ̀ fi ìsọfúnni, fọ́tò, àtàwọn nǹkan pàtàkì míì nípa ara ẹ̀ síbẹ̀ kẹ́ni tó bá fẹ́ sì wò ó tàbí kó kà á. Gbogbo ẹni tó bá rí ìsọfúnni náà ló lè kàn sẹ́ni tó ni ín. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló mọ̀ nípa irú àwọn ìkànnì yìí, àwọn ọ̀dọ́ kan nínú ìjọ sì ti ń ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ń pera wọn ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí àwọn ìkànnì náà.
Ó rọrùn fẹ́ni téèyàn bá pàdé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti parọ́ nípa irú ẹni tó jẹ́, nípa àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà àti nípa ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. (Sm. 26:4) Bá a bá wá a lọ wá a bọ̀, ó lè jẹ́ pé aláìgbàgbọ́ nirú ẹni bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ ẹni tí ètò Ọlọ́run ti yọ lẹ́gbẹ́ tàbí kó jẹ́ apẹ̀yìndà paraku, kó wá máa purọ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun. (Gál. 2:4) Ìròyìn ti tẹ̀ wá lọ́wọ́ pé àwọn abọ́mọdé-ṣèṣekúṣe máa ń lo irú àwọn ìkànnì bẹ́ẹ̀ láti wá ẹni tó máa kó sí akóló wọn.
Ká tiẹ̀ sọ pó dá wa lójú pé ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀ ń ṣe dáadáa nínú ìjọ, síbẹ̀ jíjíròrò pẹ̀lú ẹ̀ nírú ibẹ̀ yẹn lè yí bírí kó sì di èyí tí ń kó èèyàn sí ìṣòro. Ìdí ni pé àwọn èèyàn kì í fẹ́ nà tán fẹ́ni tí wọn ò bá tíì rí rí lójú kojú. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń rí ìjíròrò orí kọ̀ǹpútà bí ohun tó ń wáyé níkọ̀kọ̀ tàbí kí wọ́n máa ronú pé òbí àwọn tàbí àwọn alàgbà ò ní mọ ohun táwọn ń dán wò. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ kan tó tilé tí wọ́n ti fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run wá pàápàá ti kó sínú pàkúté yẹn, àwọn náà sì ti dẹni tó ń sọ̀rọ̀ rírùn. (Éfé. 5:3, 4; Kól. 3:8) Àwọn kan lára wọn máa ń fi fọ́tò tó fi ara sílẹ̀ tàbí orúkọ kórúkọ sínú ìkànnì wọn. Tàbí kí wọ́n jẹ́ káwọn míì máa wo fídíò táwọn olórin ti ń ṣèṣekúṣe lórí ìkànnì wọn.
Pẹ̀lú àṣà tó dóde yìí, àfi káwọn òbí máa rí i pé àwọn ń bójú tó ohun táwọn ọmọ àwọn ń ṣe lórí kọ̀ǹpútà. (Òwe 29:15) Ewu ńlá ni láti sọ pé kẹ́ni tá ò mọ̀ rí máa bọ̀ nílé wa tàbí ká sọ pé kóun nìkan wà nílé pẹ̀lú àwọn ọmọ wa. Bákan náà, ó léwu fún àwa tàbí àwọn ọmọ wa láti yan ọ̀rẹ́ láàárín àwọn tá ò mọ̀ rí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, wọn ì báà tiẹ̀ sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn.—Òwe 22:3.