Bí Ìdílé Ṣe Lè Jọ Máa Sin Jèhófà
1 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìdílé máa ń pawọ́ pọ̀ ṣe lákòókò tí wọ́n kọ Bíbélì. Wọ́n jọ máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ ilé, àti pé ju ohun gbogbo lọ, wọ́n jọ máa ń sin Jèhófà. (Léf. 10:12-14; Diu. 31:12) Ibi yòówù ká yíjú sí lóde òní, díẹ̀ lohun tó kù tó ń pa ìdílé pọ̀. Àmọ́ o, àwọn Kristẹni ṣì mọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kí ìdílé jọ máa ṣe àwọn nǹkan, àgàgà tó bá dọ̀rọ̀ ìjọsìn. Kò sí àní-àní pé inú Olùdásílẹ̀ ìdílé á dùn láti rí i tí ìdílé jọ ń sin òun níṣọ̀kan!
2 Ẹ Jọ Máa Wàásù: Ìdílé túbọ̀ máa ń wà níṣọ̀kan bí wọ́n bá jọ ń wàásù ìhìn rere. Nítorí náà, bá a bá yọwọ́ pé alàgbà kan ń bá aya ẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹ̀ ṣiṣẹ́ déédéé lóde ẹ̀rí, á tún máa báwọn akéde míì nínú ìjọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. (1 Tím. 3:4, 5) Kódà pẹ̀lú bí ìgbòkègbodò àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò ṣe máa ń mú kí ọwọ́ wọ́n dí púpọ̀, wọ́n ṣì máa ń fàyè sílẹ̀ láti máa bá aya wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí.
3 Ó máa ń ṣeé ṣe fáwọn òbí tó bá ń bá àwọn ọmọ wọn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí láti ran àwọn ọmọ náà lọ́wọ́ láti túbọ̀ já fáfá lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Yàtọ̀ sí pé àwọn ọmọ á rí bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń fáwọn òbí wọn láyọ̀, tọ́kàn wọn sì balẹ̀, wọ́n á tún rí báwọn òbí wọn ṣe ń fìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà àti ọmọlàkejì hàn. (Diu. 6:5-7) Pé ọmọ kan ti dàgbà kò ní kí òun àtòbí má jọ ṣiṣẹ́ mọ́ lóde ẹ̀rí. Tọkọtaya kan tí wọ́n lọ́mọ ọkùnrin mẹ́ta tí èyí tó kéré jù ò dín lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tí èyí àgbà ò sì ju ọmọ ọdún mọ́kànlélógún lọ, ṣì máa ń báwọn ọmọ náà ṣiṣẹ́ déédéé lóde ẹ̀rí. Bàbá àwọn ọmọ náà sọ pé: “A máa ń rí i pé wọ́n rí ohun kan kọ́ nígbà yòówù tá a bá jọ ṣiṣẹ́. A máa ń gbà wọ́n níyànjú, a sì máa ń mú kára tù wọ́n.”
4 Ẹ Jọ Máa Múra Sílẹ̀: Àwọn ìdílé kan ti kíyè sí i pé ó ṣàǹfààní láti jọ máa múra iṣẹ́ ìsìn pápá sílẹ̀. Àwọn ọmọdé tiẹ̀ sábà máa ń fẹ́ràn kí ìdílé máa ṣe ìdánrawò nínú èyí tí ẹnì kan á ti ṣe onílé tẹ́lòmíì á sì wàásù, tàbí kí wọ́n máa gbà á ṣe fúnra wọn. Àwọn kan máa ń lo ìṣẹ́jú díẹ̀ láti fi ṣe ìdánrawò yìí lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé.
5 Ayọ̀ wa máa ń pọ̀ sí i nígbà táwa àtàwọn èèyàn wa bá jọ ń lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò pàtàkì tí ń fini lọ́kàn balẹ̀ bẹ́ẹ̀. Á ti lọ wà jù bí ìdílé bá jọ ń wàásù láti ilé dé ilé, tí wọ́n jọ ń ṣe ìpadàbẹ̀wò tí wọ́n sì jọ ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì! Nítorí náà, bí ìwọ àti ìdílé rẹ ṣe ń sin Jèhófà, o lè fìdùnnú sọ pé: “Ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”—Jóṣ. 24:15.