Bí Àwọn Mẹ́ńbà Ìdílé Ṣe Máa Ń Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Láti Kópa Kíkún—Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Náà
1 Kí ló tún lè múni lọ́kàn yọ̀ ju ká rí tọkọtaya, ká rí àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọ́n tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ papọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni, tí wọ́n jọ ń yin orúkọ Jèhófà ní gbangba? (Sm. 148:12, 13) Gbogbo ìdílé pátá ló yẹ kó ní ètò tó gún régé fún kíkópa déédéé nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Ṣé ìdílé tìrẹ ní ọjọ́ kan pàtó lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tí ẹ máa ń lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́? Bẹ́ẹ bá ní, a jẹ́ pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ti mọ ohun tí òun yóò wéwèé fún àti bí òun ṣe lè kópa kíkún nínú rẹ̀.—Òwe 21:5a.
2 Ṣáájú jíjáde fún iṣẹ́ ìsìn gẹ́gẹ́ bí ìdílé, èé ṣe tí ẹ kò fi ṣètò pé kí gbogbo yín jókòó kí ẹ sì múra ìgbékalẹ̀ tí ìdílé yín yóò lò? Ṣíṣe ìfidánrawò lè ṣèrànwọ́ gidigidi, wọ́n sì lè jẹ́ kí a mú ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ rere dàgbà nínú ìdílé. Ẹ wo bó ti máa ń kún fún èrè jìngbìnnì tó nígbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá bá jẹ́ ohun tí gbogbo ìdílé kọ́wọ́ tì lẹ́yìn, tí gbogbo wọn sì múra sílẹ̀ dáadáa!
3 Alábòójútó arìnrìn-àjò kan ló ṣiṣẹ́ pẹ̀lú odindi ìdílé kan nínú iṣẹ́ pípín ìwé ìròyìn lọ́jọ́ kan. Bí òun àti ọ̀kan lára ọmọbìnrin tó jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé náà ṣe jọ ń ṣiṣẹ́, ọ̀dọ́mọbìnrin náà béèrè pé: “Báwo lẹ ṣe fẹ́ bá mi ṣiṣẹ́ pẹ́ tó?” Lẹ́yìn náà lọmọbìnrin náà wá ṣàlàyé pé tó bá ṣe díẹ̀ sí i, baba òun lòun fẹ́ bá ṣiṣẹ́. Ó ṣe kedere pé òun àti baba rẹ̀ ti máa ń gbádùn ṣíṣiṣẹ́ papọ̀. Ẹ̀mí rere tó yẹ kó máa wà nínú ìdílé mà lèyí o!
4 Ó lè ṣeé ṣe fún àwọn ìdílé kan láti jọ gba aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ papọ̀ lóṣù kan náà láàárín ọdún kan. Ó sì lè ṣeé ṣe pé, ó kéré tan, kí ẹnì kan nínú ìdílé náà máa ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lọ láìdáwọ́ dúró tàbí kó tiẹ̀ forúkọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé. Bí ìṣètò tó gún régé bá wà, tí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ sì wà, ó lè ṣeé ṣe kí gbogbo mẹ́ńbà ìdílé fi kún ipa tí wọ́n ń kó nínú iṣẹ́ ìsìn náà nípa kíkọ́wọ́ ti ẹni tó ń ṣe aṣáájú ọ̀nà náà lẹ́yìn. Ó dájú pé, ìgbòkègbodò tí a mú pọ̀ sí i yìí àti àwọn ìrírí amọ́kànyọ̀ tí wọ́n bá gbádùn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yóò mú ìbùkún wá fún ìdílé náà.—Mál. 3:10.
5 Kíkópa ní kíkún nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere náà yóò ṣèrànwọ́ láti mú kí ìdílé wà ní ìrẹ́pọ̀, kí wọ́n jẹ́ onítara, kí wọ́n méso rere jáde, kí wọ́n sì jẹ́ aláyọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà!—Fi wé Fílípì 2:1, 2.