Àpótí Ìbéèrè
◼ Ṣó dáa kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn táwọn onísìn dá sílẹ̀?
Ọ̀pọ̀ àwọn onísìn ló ń dá ilé ìwòsàn sílẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìdí tí wọ́n fi dá àwọn ilé ìwòsàn wọ̀nyí sílẹ̀ kì í ṣe láti gbé Bábílónì Ńlá lárugẹ. (Ìṣí. 18:2, 4) Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n dá a sílẹ̀ láti fi ṣòwò. Lónìí, orúkọ nìkan làwọn ilé ìwòsàn kan fi jọ tàwọn onísìn, àwọn míì sì rèé àwọn tó ń múpò iwájú nínú ìjọ wọn wà lára àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà.
Ọwọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ló kù sí láti lọ tàbí láti má ṣe lọ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn tó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àwọn onísìn. Ẹ̀rí ọkàn ẹnì kan lè gbà á láyè láti lọ nígbà tí ẹ̀rí ọkàn ẹlòmíì lè má fàyè gbà á. (1 Tím. 1:5) Àmọ́, àwọn nǹkan kan wà tó lè nípa lórí ìpinnu wa, ó sì yẹ ká gbé àwọn nǹkan náà yẹ̀ wò.
Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilé ìwòsàn tó ń jẹ́ orúkọ ìsìn nìkan ló wà nítòsí. Ó sì lè jẹ́ pé ilé ìwòsàn míì wà nítòsí, àmọ́ kó jẹ́ pé èyí tó ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn onísìn yẹn gan-an ni wọ́n ti mọṣẹ́ jù lọ. Ó lè jẹ́ pé ilé ìwòsàn tó ń jẹ́ orúkọ ìsìn yẹn nìkan ló láwọn ẹ̀rọ tí wọ́n lè fi tọ́jú àìsàn tó ń ṣe ẹnì kan, ó sì lè jẹ́ pé ibẹ̀ nìkan ni wọ́n ti gba dókítà rẹ tàbí ẹni tó fẹ́ ṣiṣẹ́ abẹ fún ẹ láyè láti ṣiṣẹ́. Nígbà míì sì rèé, ó lè jẹ́ pé ilé ìwòsàn tó ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn onísìn ló máa bọ̀wọ̀ fún ìgbàgbọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí Kristẹni pé o kò fẹ́ kí wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sí ẹ lára, nígbà táwọn ilé ìwòsàn àdáni tàbí ilé ìwòsàn ìjọba lè máà fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn nǹkan tó o máa gbé yẹ̀ wò rèé kó o tó pinnu ilé ìwòsàn tí wà á ti gba ìtọ́jú.
Bó o bá pinnu láti lọ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn kan tó ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn onísìn, o lè wò ó bí ìgbà tó ò ń sanwó iṣẹ́ fún ẹni tó bójú tó ọ̀ràn ìlera rẹ. O sì tún lè wò ó bí ìgbà táwọn onísìn yẹn ń tajà, tó o rajà tó o sì sanwó ọjà tó o rà lọ́wọ́ wọn, kì í ṣe pé o fún wọn lówó láti gbé ìjọsìn èké lárugẹ.
Kò sí àníàní pé tó o bá bá ara rẹ nírú ipò yìí, o gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tó yẹ kó o ṣe gẹ́gẹ́ bí Kristẹni láti má ṣe lọ́wọ́ sí ìjọsìn èké lọ́nà èyíkéyìí. Kò sì ní dáa kó o lo àwọn orúkọ oyè táwọn onísìn máa ń lò bíi, “Wòlíì,” “Pásítọ̀,” tàbí “Ajíhìnrere” láti pe àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ tàbí àwọn tó wá bẹ ilé ìwòsàn náà wò. (Mát. 23:9) O tún gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àjọṣe tó wà láàárín yín ò kọjá ti aláìsàn tó wá gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn.
Gbàrà tó o bá ti dé ilé ìwòsàn náà ni kó o ti sọ fún wọn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́ àti pé àwọn alàgbà ìjọ tó ò ń dara pọ̀ mọ́ á máa wá wò ẹ́. Èyí á jẹ́ kó o lè rí ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí tó jíire gbà lásìkò tó o máa fi wà nílé ìwòsàn náà.—1 Tẹs. 5:14.
Àwọn mọ̀lẹ́bí tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, àwọn alàgbà ìjọ àtàwọn tó kù nínú ìjọ gbọ́dọ̀ rí sí i pé àwọn arúgbó tó ń gbé nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó ń rí ìrànlọ́wọ́ gbà nípa tẹ̀mí pàápàá tó bá jẹ́ pé àwọn onísìn ló ni irú ilé ìtọ́jú bẹ́ẹ̀. Bá a bá jẹ́ aláápọn nírú ọ̀nà yìí, a máa ran irú àwọn arúgbó bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti má ṣe lọ́wọ́ sáwọn ààtò ìsìn, ayẹyẹ ìsìn tàbí àwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ ìjọsìn èké tí wọ́n máa ń ṣe láwọn ilé ìtọ́jú náà.
Pẹ̀lú àwọn kókó wọ̀nyí lọ́kàn wa, ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tó yí ọ̀ràn náà ká dáadáa, kó sì wá pinnu ilé ìwòsàn tàbí ilé ìtọ́jú tó máa lò.—Gál. 6:5.