ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/14 ojú ìwé 2-4
  • Ẹ Máa Rántí Àwọn Tó Wà Ní Ilé Ìtọ́jú Àwọn Arúgbó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Máa Rántí Àwọn Tó Wà Ní Ilé Ìtọ́jú Àwọn Arúgbó
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọn Ò Sí Láàárín Wa Àmọ́ A Kò Gbàgbé Wọn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • A Ń Fẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Púpọ̀ Sí I
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Bí O Ṣe Lè Jàǹfààní Látinú Àwùjọ Tí Ò Ń Dara Pọ̀ Mọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
km 6/14 ojú ìwé 2-4

Ẹ Máa Rántí Àwọn Tó Wà Ní Ilé Ìtọ́jú Àwọn Arúgbó

1. Kí nìdí tó fi yẹ ká wá bá a ṣe máa wàásù fáwọn àgbàlagbà tó wà ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó?

1 Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní àwọn àìlera tí ọjọ́ ogbó máa ń fà. (Oníw. 12:1-7) Ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó ni àwọn àgbàlagbà kan ń gbé, torí náà a kì í sábà rí wọn nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé. Kódà nǹkan ti yàtọ̀ láwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn ọmọ tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí ti sábà máa ń mú àwọn òbí wọn tó ti darúgbó sọ́dọ̀, àwọn àgbàlagbà míì ti ń gbé ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó báyìí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgbàlagbà tó wà nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó kì í sábà jáde, wọ́n sì lè tètè gbàgbé nǹkan, síbẹ̀ wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kí wọ́n mọ irú ẹni tó jẹ́, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Báwo la ṣe lè dé ọ̀dọ̀ wọn, kí a sì wàásù ìhìn rere nípa “ìrètí aláyọ̀” fún wọn?—Títù 2:13.

2. Báwo ni alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣe lè ṣètò ìbẹ̀wò sí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó?

2 Ohun Tó Yẹ Ká Kọ́kọ́ Ṣe: Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn lè ṣètò pé kí àwọn akéde tó tóótun lọ ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó. Tá a bá ṣètò ẹ̀ dáadáa, tá a sì gbára lé Jèhófà, ó ṣeé ṣe ká lè dá àwùjọ tí àá máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀ níbẹ̀.—Òwe 21:5; 1 Jòh. 5:14, 15.

3, 4. (a) Ta ló yẹ ká sọ fún pé a fẹ́ dá àwùjọ tí a ó máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sílẹ̀? (b) Báwo la ṣe lè ṣàlàyé ohun tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà wà fún àti bá a ṣe fẹ́ máa ṣe é?

3 Bí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó náà bá ṣe tóbi tó la máa fi mọ ẹni tó yẹ ká bá sọ̀rọ̀ ká lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀. Ní àwọn ilé ìtọ́jú arúgbó tí ó tóbi táwọn àgbàlagbà tó ń gbé níbẹ̀ àtàwọn òṣìṣẹ́ wọn pọ̀, ohun tó máa dára jù ni pé ká sọ fún olùgbàlejò tó wà níbẹ̀ pé a fẹ́ bá máníjà sọ̀rọ̀. Àmọ́ láwọn ibi tí kò tóbi púpọ̀, tó jẹ́ pé ìwọ̀nba làwọn àgbàlagbà tó ń gbé níbẹ̀ táwọn tó ń tọ́jú wọn ò sì ju méjì sí mẹ́ta lọ, ohun tó máa dáa jù ni pé ká bá ẹni tó ni ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó náà sọ̀rọ̀.

4 Ẹni yòówù ká bá sọ̀rọ̀, a lè ṣàlàyé pé à ń yọ̀ǹda àkókò wa láti fún àwọn tó fẹ́ràn láti máa ka Bíbélì kí wọ́n sì máa jíròrò rẹ̀ níṣìírí. A lè bi onítọ̀hún bí ẹnikẹ́ni lára àwọn tó ń gbé níbẹ̀ bá máa fẹ́ wà lára àwùjọ tí a ó máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún nǹkan bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Onírúurú ìwé la lè lò, àmọ́ ọ̀pọ̀ ti rí i pé àwọn èèyàn sábà máa ń nífẹ̀ẹ́ sí Ìwé Ìtàn Bíbélì àti ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. A lè fi àwọn ìwé náà han máníjà. Ohun tó dáa ni pé ká jọ yan ọjọ́, àkókò àti yàrá tá a ó máa lò fún ìjíròrò náà, wọ́n sì lè lẹ̀ ẹ́ mọ́ ara pátákó tí ìsọfúnni nípa ìgbòkègbodò wọn máa ń wà. Ẹ má ṣe tijú láti sọ fún wọn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni yín. Àmọ́, ẹ jẹ́ kó yé máníjà náà pé kì í ṣe ìpàdé ẹ̀sìn lẹ fẹ́ máa ṣe níbẹ̀, pé ẹ kàn fẹ́ máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni.

5. Àwọn nǹkan wo ló máa jẹ́ kẹ́ ẹ gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà kó sì ṣàǹfààní?

5 Bí A Ṣe Máa Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Náà: Bí nǹkan bá ṣe rí ní ilé ìtọ́jú arúgbó kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bí ẹ ṣe máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, torí náà ó máa gba pé kí ẹ máa ṣe àwọn àyípadà kọ̀ọ̀kan, kí ẹ sì máa lo òye. Kí ẹni tó máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà rí i pé òun mú ẹ̀dà ìwé tí wọ́n máa lò tó pọ̀ tó dání, kó sì gbà wọ́n pa dà lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ó lè pọn dandan pé ká ṣe ẹ̀dà tí àwọn lẹ́tà rẹ̀ tóbi tàbí ká mú ẹ̀dà onílẹ́tà gàdàgbà wá fún àwọn kan. Ẹ lè ka ìpínrọ̀, kí ẹ béèrè ìbéèrè, kí ẹ sì jẹ́ kí wọ́n dáhùn rẹ̀ bí a ti sábà máa ń ṣe. A lè sọ pé káwọn tó mọ̀wé kà dáadáa ka àwọn ìpínrọ̀ tàbí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀ bí wọ́n bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ó yẹ ká jẹ́ kí wọ́n kópa níbẹ̀ dáadáa, kí wọ́n lóye ẹ̀kọ́ náà, ká sì mú kí ara tù wọ́n. Ẹ lè máa fi àwọn fídíò tí ètò Ọlọ́run ṣe hàn wọ́n lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, bí máníjà náà bá gbà kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀. Ó lè jẹ́ àwọn fídíò tó máa jẹ́ kí wọ́n gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì tàbí èyí tó máa jẹ́ kí wọ́n kọ́ ẹ̀kọ́ lára ìtan Bíbélì kan. Ẹ lè gbàdúrà ṣókí ní ìbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan àti ní ìparí rẹ̀. Àwọn akéde kan tiẹ̀ máa ń kọ orin Ìjọba Ọlọ́run.

6. Kí ló yẹ kẹ́ ẹ ṣe tí ẹnì kan ò bá fara mọ́ ohun tí ẹ sọ?

6 Kí ló yẹ kẹ́ ẹ ṣe tí ẹnì kan nílé ìtọ́jú náà bá sọ pé òun ò fara mọ́ ohun tẹ́ ẹ kà tàbí ohun tẹ́ ẹ sọ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà? Ẹ fi ọgbọ́n fèsì. (Kól. 4:6) Bóyá ní ṣókí kí ẹ ka ẹsẹ Bíbélì kan tó máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tí kò yé ẹni náà. Àmọ́ tẹ́ ẹ bá rí i pé kò yẹ kẹ́ ẹ ṣe bẹ́ẹ̀, ohun tó máa dáa ni pé kẹ́ ẹ jẹ́ kí onítọ̀hún mọ̀ pé ẹ gbọ́ ohun tó sọ, kí ẹ sì sọ fún un pé lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ẹ máa bá a jíròrò rẹ̀ lóun nìkan.

7. Kí lo lè ṣe tí ẹnì kan bá ní ìbéèrè tàbí tó fẹ́ mọ púpọ̀ sí i?

7 Nígbà míì, ẹnì kan níbẹ̀ lè béèrè ìbéèrè kan tàbí kó sọ pé òun fẹ́ mọ púpọ̀ sí i. Ohun tí arábìnrin kan máa ń sọ ni pé: “Ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání nìyẹn. Àmọ́ torí ìwọ lo fẹ́ mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn, jẹ́ ká parí ohun tá à ń kà yìí ná. Àwa méjèèjì á lè jọ jíròrò rẹ̀.” Lọ́pọ̀ ìgbà, a lè ṣètò láti máa kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní àkókò míì tó yàtọ̀ sí àkókó tí àwùjọ tó wà níbẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

8. Báwo ló ṣe yẹ ká máa ròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a bá ń ṣe pẹ̀lú àwùjọ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń bá ẹnì kan ṣe?

8 Àwọn tó bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ tá à ń ṣe ní ilé ìtọ́jú arúgbó kan ló dára jù kí wọ́n máa ṣe é ní gbogbo ìgbà. Àwọn akéde tí wọ́n bá kópa nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lè ròyìn wákàtí tí wọ́n fi ṣe é. Akéde tó bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lè ròyìn ìpadàbẹ̀wò kan ní gbogbo ìgbà tí àwùjọ náà bá ti pàdé àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lóṣù kan. Bí ẹ bá bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹnikẹ́ni lára àwọn tó ń gbé ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó náà tó sì lóye ohun tó ń kọ́, ẹ lè ròyìn rẹ̀ bí a ṣe máa ń ròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

9, 10. Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ káwọn tó ń kọ́ àwọn tó wà nílé ìtọ́jú arúgbó lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní? Ṣàlàyé.

9 Bí Ẹ Ṣe Lè Rí I Pé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Náà Ń Bá A Nìṣó: Ohun tó dáa jù ni pé kẹ́ ẹ ní ọjọ́ àti àkókò kan pàtó tẹ́ ẹ ó máa kọ́ àwùjọ náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn àgbàlagbà tó wà níbẹ̀ àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ máa retí pé kẹ́ ẹ máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà déédéé, wọ́n á sì fẹ́ kó máa bẹ̀rẹ̀ kó sì máa parí lásìkò. (Mát. 5:37) Nítorí náà, ó gba pé kí ẹ fi ọwọ́ pàtàkì mú un, kí ẹ máa ṣe é tọkàntọkàn, kó sì máa wà létòlétò. A ti kíyè sí i pé ohun tó dára jù ni pé kí akéde méjì tó tóótun jọ máa ṣiṣẹ́ pọ̀ láti máa kọ́ àwùjọ náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Oníw. 4:9, 10) Àmọ́, ẹ lè lo àwọn akéde púpọ̀ sí i ní àwọn ilé ìtọ́jú arúgbó tí ó tóbi.

10 Ó tún ṣe pàtàkì pé ká mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́, ká sì jẹ́ kí wọ́n rí i pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún. (Fílí. 2:4) Nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá ṣèbẹ̀wò síbẹ̀, ẹ sapá láti bá ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó wá síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà sọ̀rọ̀. Ẹ kọ orúkọ wọn sílẹ̀, kí ẹ sì gbìyànjú láti mọ̀ ọ́n lórí kó tó di ọjọ́ tí ẹ máa pa dà lọ síbẹ̀. Tẹ́ ẹ bá ń ní sùúrù tí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ wọn, èyí máa jẹ́ kí gbogbo wọn túra ká kí wọ́n sì rí i pé ẹ mọyì àwọn.

11. Ọ̀nà wo ni àwọn tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lè gbà fi hàn pé àwọn bọ̀wọ̀ fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ àtàwọn mọ̀lẹ́bí àwọn àgbàlagbà náà?

11 Ó tún ṣe pàtàkì pé ká bọ̀wọ̀ fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó àti mọ̀lẹ́bí àwọn àgbàlagbà tó wà níbẹ̀, ká sì máa ṣoore fún wọn. Tẹ́ ẹ bá ti fohùnṣọ̀kan lórí àkókò àti ọ̀nà tẹ́ ẹ ó máa gbà ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ẹ kọ́kọ́ bá máníjà ibẹ̀ sọ ọ́ kí ẹ tó yì i pa dà. Látìgbàdégbà, ẹ bi máníjà náà pé kó sọ èrò rẹ̀ nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Tí àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn àgbàlagbà náà bá wá bẹ̀ wọ́n wò, ẹ wá bẹ́ ẹ ṣe máa bá wọn sọ̀rọ̀. Ẹ ṣàlàyé ìdí tí ẹ fi ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ ẹbí wọn tó wà níbẹ̀. Ẹ ní kí àwọn náà jókòó kí wọ́n rí bí ẹ ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.

12, 13. Sọ àwọn ìrírí tó jẹ́ ká mọ àǹfààní tó wà nínú ká máa kọ́ àwọn tó wà ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

12 Àwọn Àbájáde: Ohun tí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn ìjọ sọ nípa àbájáde kíkọ́ àwọn àgbàlagbà tó wà nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó lẹ́kọ̀ọ́ fúnni ní ìṣírí gan-an. Níbì kan, àwọn tó wá síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tó nǹkan bí ogún. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú mẹ́fà lára wọn. Ọ̀kan lára wọn sì ṣèrìbọmi nígbà tó yá. Níbòmíì, ẹ̀kọ́ tí obìnrin ẹni ọdún márùndínláàádọ́rùn-ún [85] kan ń kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé ní ìjọ tó wà nítòsí, ó sì sọ pé òun fẹ́ ṣe ìrìbọmi. Ilé ìtọ́jú kan fẹ́ dín àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ kù, ìyẹn sì túmọ̀ sí pé wọn ò ní fàyè gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti máa kọ́ àwùjọ tó wà níbẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ mọ́. Àwọn àgbàlagbà tó wà níbẹ̀ sọ fún máníjà ibẹ̀ pé àwọn ò fẹ́ kí wọ́n dá ètò náà dúró rárá. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn tó sì ń wá síbẹ̀ ń tó èèyàn márùndínlọ́gbọ̀n sí ọgbọ̀n.

13 Kì í ṣe àwọn tó wà ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó nìkan ló máa ń mọyì rẹ̀ tá a bá fi tìfẹ́tìfẹ́ ran àwọn àgbàlagbà náà lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, lọ́pọ̀ ìgbà àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó máa ń jókòó síbi tá a ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì máa ń lóhùn sí i. Bá a ṣe ń sapá láti ran àwọn àgbàlagbà yẹn lọ́wọ́ máa ń mú kí àwọn tó wà ládùúgbò sọ dáadáa nípa wa. (1 Pét. 2:12) Àwọn ará lọ bá máníjà ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó kan, wọ́n sì ṣàlàyé ìdí tí àwọn fi fẹ́ máa kọ́ àwọn àgbàlagbà tó wà níbẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Máníjà náà sọ pé: “Ibo lẹ wà látijọ́ yìí? Ìgbà wo lẹ fẹ́ bẹ̀rẹ̀?” Máníjà míì kọ̀wé pé: “Inú mi máa dùn láti dábàá irú ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí fún àwọn ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó míì tó wà lágbègbè yìí. Ó wà lára iṣẹ́ tí ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lọ́fẹ̀ẹ́ fún àǹfààní àwọn èèyàn.” Ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó kan ní ìpínlẹ̀ Hawaii lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àmì ẹ̀yẹ kan nítorí ipa ribiribi tá à ń kó láwùjọ. Wọ́n kọ ọ́ sára àmì ẹ̀yẹ náà pé “ìṣura iyebíye” ni àwọn Ẹlẹ́rìí tó yọ̀ǹda ara wọn yẹn jẹ́ fún àwọn àgbàlagbà tó wà ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó náà.

14. Kí nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń gbé ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó?

14 Jèhófà ní kí àwọn àgbàlagbà máa yin òun. (Sm. 148:12, 13) Àwọn àgbàlagbà tó wà nílé ìtọ́jú àwọn arúgbó náà wà lára àwọn tí Jèhófà ní kó máa yin òun. Ṣé àwọn ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó wà ní ìpínlẹ̀ ìwáàsù ìjọ yín? Ṣé àwọn àgbàlagbà tó wà níbẹ̀ sì lè jàǹfààní tí wọ́n bá gbọ́ ìhìn rere? Àwọn alàgbà ìjọ àtàwọn máníjà ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó lè ṣèrànwọ́ gan-an ká lè wàásù fún àwọn tó ń gbé ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó. Tá a bá ń rántí àwọn tó ti dàgbà, ńṣe la fìwà jọ Jèhófà.—Sm. 71:9, 18.

Àwọn Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe

  • Tó o bá ti débẹ̀ lákòókò tẹ́ ẹ fi àdéhùn sí, jẹ́ kí olùgbàlejò àti máníjà mọ̀ pé o ti dé.

  • Mú ẹ̀dà ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ẹ máa lò tí ó pọ̀ tó dání. Rí i pé báàgì tó o kó àwọn ìwé náà sí bójú mu, kó o sì gba àwọn ìwé náà pa dà lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́.

  • Fara balẹ̀, kó o mú kí ara tù wọ́n, kó o sì máa bá wọn sọ̀rọ̀.

  • Tí ẹ bá ti ka ìpínrọ̀ kan tán, ẹ jíròrò rẹ̀ kí ẹ tó lọ sí èyí tó kàn.

  • Lo ìbéèrè ṣókí. Máa gbóríyìn fún wọn tí wọ́n bá lóhùn sí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.

  • Tí ẹnì kan bá béère ìbéèrè nípa ẹ̀kọ́ wa tàbí nípa ohun kan tí kò fara mọ́, sọ fún un pé ẹ máa jọ jíròrò kókó náà lákòókò míì.

  • Tí àwọn òṣìṣẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí àwọn àgbàlagbà náà bá béèrè ìbéèrè, rí i pé o dáhùn rẹ̀ lọ́nà tí kò lọ́jú pọ̀, tó sì ṣe tààrà.

  • Wá bó o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tó ń gbé níbẹ̀, àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́