ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/08 ojú ìwé 3
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jèhófà Ń Dá Wa Lẹ́kọ̀ọ́ Láti Ṣe Iṣẹ́ Yìí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Ilé Ẹ̀kọ́ Tó Ń Mú Wa Gbára Dì fún Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nígbèésí Ayé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fi Ìmoore Hàn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Ìlànà Fún Àwọn Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 5/08 ojú ìwé 3

Àpótí Ìbéèrè

◼ Ṣé ó yẹ ká máa pàtẹ́wọ́ fún gbogbo ẹni tó bá ṣiṣẹ́ nípàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn?

Nígbà tí Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa ṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé, ‘àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ fi ìdùnnú ké jáde, gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn.’ (Jóòbù 38:7) Ìfẹ́ ọkàn àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ọlọ́run wọ̀nyí ni láti yin Jèhófà lógo fún ọ̀nà tó ta yọ tó gbà ṣẹ̀dá àwọn nǹkan, èyí sì jẹ́ ọ̀nà tuntun tó gbà fi ọgbọ́n, inúure àti agbára rẹ̀ hàn.

Kò sóhun tó burú nínú ká fi hàn pé tọkàntọkàn la mọrírì ìsapá àwọn ará wa àti iṣẹ́ tí wọ́n bá ṣe láwọn ìpàdé ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, a sábà máa ń pàtẹ́wọ́ fáwọn tó bá ṣiṣẹ́ láwọn àpéjọ àkànṣe, àyíká àti agbègbè, torí ìsapá kékeré kọ́ ni wọ́n ṣe láti múra iṣẹ́ wọn. Kì í ṣe torí pé a mọrírì ìsapá àwọn olùbánisọ̀rọ̀ nìkan la ṣe máa ń pàtẹ́wọ́, àmọ́ àtẹ́wọ́ wa tún máa ń fi hàn pé a mọrírì ìtọ́ni tí Jèhófà ń fún wa nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀.—Aísá. 48:17; Mát. 24:45-47.

Pípàtẹ́wọ́ fáwọn tó bá ṣiṣẹ́ nípàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ńkọ́? Kò sí òfin tó dè é tó bá jẹ́ látọkàn wá ni, irú bí ìgbà tẹ́nì kan bá kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ nípàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́, ó yẹ ká ṣọ́ra, ká má lọ sọ àtẹ́wọ́ pípa di àṣà lásán, ká sì wá gbàgbé ohun tó wà fún gan-an. Nítorí náà, kì í ṣe gbogbo àwọn tó bá ṣiṣẹ́ láwọn ìpàdé wọ̀nyí la sábà máa ń pàtẹ́wọ́ fún.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í sábà pàtẹ́wọ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn tó bá ṣiṣẹ́ nípàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, síbẹ̀ àwọn ọ̀nà míì wà tá a lè gbà fi hàn pé a mọrírì ìtọ́ni tá a rí gbà àti ìsapá wọn. A lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa wíwà lójúfò ká sì fetí sílẹ̀ dáadáa sáwọn olùbánisọ̀rọ̀. A tún lè sọ fún wọn lẹ́yìn ìpàdé pé a gbádùn iṣẹ́ wọn.—Éfé. 1:15, 16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́