À Ń Dojú Àwọn Nǹkan Tó Fìdí Múlẹ̀ Gbọn-in Gbọn-in Dé
1 Ọjọ́ pẹ́ tí Sátánì ti ń fi ẹ̀kọ́ èké àti ẹ̀tàn ṣi ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà. Ó ti tan àwọn ẹ̀kọ́ èké bíi Mẹ́talọ́kan àti iná ọ̀run àpáàdì kálẹ̀, ó sì ti jẹ́ kí wọ́n gbà gbọ́ pé béèyàn bá kú, ṣe ni ẹ̀mí ẹni náà á jáde lọ láti máa lọ gbé ní ibòmíì. Ó ti mú káwọn kan máa rò pé kò sí Ẹlẹ́dàá, bẹ́ẹ̀ ló sì ń mú kí wọ́n máa ṣiyè méjì pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Ẹ̀yà ìran tèmi lọ̀gá àti ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tún jẹ́ ọ̀nà míì tó ń lò láti má ṣe jẹ́ káwọn èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (2 Kọ́r. 4:4) Báwo la ṣe wá lè dojú àwọn ẹ̀kọ́ èké tó ti fìdí múlẹ̀ gbọin gbọin yìí dé?—2 Kọ́r. 10:4, 5.
2 Ká Fọgbọ́n Ṣe É: Bó bá ti pẹ́ téèyàn ti gba ẹ̀kọ́ kan gbọ́, típẹ́ nirú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń lẹ̀ mọ́ ọpọlọ. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé, láti kékeré ni wọ́n ti gba irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ gbọ́. Láti lè ran irú wọn lọ́wọ́, a gbọ́dọ̀ rí i pé a ò tìtorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ tàbùkù sí wọn.—1 Pét. 3:15.
3 A lè fọ̀wọ̀ wọn wọ̀ wọ́n nípa jíjẹ́ kí wọ́n ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ìdí tí wọ́n fi gbà á gbọ́. (Ják. 1:19) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nítorí bó ṣe ń wù wọ́n láti rí àwọn èèyàn wọn tó ti kú ni wọ́n ṣe gbà gbọ́ pé béèyàn bá kú ẹ̀mí ẹ̀ ò kú. Tàbí kó jẹ́ pé nítorí bí wọ́n ṣe máa ń ráyè bá ìdílé wọn ṣeré lákòókò ọdún ló mú kí wọ́n máa ṣe é. Bá a bá ń fetí sílẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, á jẹ́ ká lè mọ bọ́ràn náà ṣe rí lára wọn, á sì ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bá a ṣe lè fèsì lọ́nà tó máa yé wọn.—Òwe 16:23.
4 Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù: Jésù fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lé lẹ̀ fún wa nígbà tó dáhùn ìbéèrè tí ọkùnrin kan tó jẹ́ ògbóǹkangí nínú Òfin bi í. Jésù ò sọ ohun tó máa ṣe fún un ní tààràtà, èyí tó ṣeé ṣe kí ọkùnrin yẹn kọ̀ nítorí ohun tó gbà gbọ́. Dípò ìyẹn, ńṣe ni Jésù tọ́ka rẹ̀ sí Ìwé Mímọ́, tó ní kó sọ èrò rẹ̀, lẹ́yìn náà ló wá lo àpèjúwe kan láti mú kó dórí ìpinnu tó tọ́.—Lúùkù 10:25-37.
5 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára láti mú káwọn èèyàn kọ ẹ̀kọ́ èké sílẹ̀. (Héb. 4:12) Bá a bá ń fara balẹ̀ ṣàlàyé òtítọ́ fún wọn, wọ́n á lè fetí sílẹ̀, á sì ṣeé ṣe fún wa láti ràn wọ́n lọ́wọ́ débi tí wọ́n á fi lè kọ ẹ̀kọ́ èké sílẹ̀ tí wọ́n á sì gba òtítọ́ tó lè sọ wọ́n dòmìnira.—Jòh. 8:32.