ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/08 ojú ìwé 8
  • Ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé Ṣe Pàtàkì!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé Ṣe Pàtàkì!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ìdílé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Déédéé Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ẹ̀yin Ìdílé Kristẹni—“Ẹ Wà Ní Ìmúratán”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé Tí Ń Mú Ìdùnnú Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 10/08 ojú ìwé 8

Ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé Ṣe Pàtàkì!

1. Báwo lọ̀rọ̀ wa ti jẹ Ìgbìmọ̀ Olùdarí lógún tó lónìí, kí sì nìdí?

1 Bíi ti ọ̀rúndún kìíní, ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà jẹ àwọn Ìgbìmọ̀ Olùdarí lógún gan-an ni. (Ìṣe 15:6, 28) Bí ìpọ́njú ńlá náà tí wọlé dé tán yìí, ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà. Nítorí náà, báwo ni wàá ṣe máa ló àkókò tá a fi ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ báyìí? A rọ gbogbo wa pé ká máa fi àkókò yìí ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa. Tá a bá ń fi ọgbọ́n lo àkókò yìí, a óò lè ráyè walẹ̀ jìn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a óò sì máa mu omi ìyè tó ń fúnni.—Sm. 1:1-3; Róòmù 11:33, 34.

2. Báwo la ṣe lè ṣètò ìjọsìn ìdílé wa?

2 Ìjọsìn Ìdílé ní Ìrọ̀lẹ́: A gba àwọn olórí ìdílé níyànjú láti máa ṣe ojúṣe tí Jèhófà gbé lé wọn lọ́wọ́, kí wọ́n rí i pé àwọn ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tó nítumọ̀, tó sì ń lọ déédéé. (Diu. 6:6, 7) Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí kò tíì ní ìdílé náà á lè máa lo àkókò yìí fún ṣíṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ìwádìí. Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹni kọ̀ọ̀kan wa ‘ra àkókò tí ó rọgbọ padà’ fún ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò ká bàa lè máa ní okun tẹ̀mí láti kojú àwọn ‘ọjọ́ búburú’ yìí.—Éfé. 5:15, 16.

3, 4. Àwọn àbá wo la fún wa nípa àwọn ìwé tá a lè máa lò, kí la sì gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn?

3 Ohun Tí A Ó Máa Lò fun Ìkẹ́kọ̀ọ́: Ìwé Watch Tower Publications Index tàbí àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ṣe sórí àwo CD-ROM lè ràn wá lọ́wọ́ láti wá ìsọfúnni tó máa jẹ́ kí àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ náà gbádùn mọ́ni. Àwọn ìdílé lè máa lo àwọn àpilẹ̀kọ tó máa ń jáde déédéé nínú Ilé Ìṣọ́, irú àwọn àpilẹ̀kọ bí, “Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀,” “Kọ́ Ọmọ Rẹ,” àti “Abala Àwọn Ọ̀dọ́.” Bákan náà, ìtẹ̀jáde Jí! ní àwọn àpilẹ̀kọ bí “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” àtàwọn àpilẹ̀kọ míì tó fani mọ́ra nípa àwọn iṣẹ́ àrà inú ìṣẹ̀dá.

4 Tá a bá ń fara balẹ̀ ka Bíbélì, èyí á gbin àwọn ẹ̀kọ́ àti ìlànà Ọlọ́run sọ́kàn àwọn tó wà nínú ìdílé. (Héb 4:12) Láwọn ìgbà míì, ẹ lè wo àwọn fídíò tí ètò Ọlọ́run gbé jáde kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Àǹfààní ló jẹ́ láti wá ohun tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ fúnra wa ká sì tún pinnu bá a ṣe máa jíròrò rẹ̀. O lè béèrè lọ́wọ́ àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ ohun tí wọ́n á fẹ́ kẹ́ ẹ jíròrò àti bẹ́ ẹ ṣe máa ṣe é?

5. Kí nìdí tí ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé fi ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa nísinsìnyí?

5 Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Báyìí: Tá a bá ń fún ara wa lókun nípa tẹ̀mí, èyí á mú ká gbára dì láti ‘dúró gbọn-in-gbọn-in, kí á sì rí ìgbàlà Jèhófà.’ (Ẹ́kís. 14:13) Àwọn òbí nílò ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run láti lè tọ́ àwọn ọmọ wọn “láàárín ìran oníwà wíwọ́ àti onímàgòmágó” yìí. (Fílí. 2:15) Àwọn ọmọ nílò ìrànlọ́wọ́ kó má bàa di pé wọ́n kó èèràn ràn wọ́n nílé ìwé níbi tí ìwà ọmọlúwàbí ti ń pòórá. (Òwe 22:6) Bákan náà, àwọn tọkọtaya ní láti jẹ́ kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i, ìyẹn “okùn onífọ́nrán mẹ́ta.” (Oníw. 4:12) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa fọgbọ́n lo àkókò tó ṣẹ́ kù láti gbé ara wa ró lórí ‘ìgbàgbọ́ wa mímọ́ jù lọ’!—Júúdà 20.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́