“Jẹ́rìí Kúnnákúnná” Nígbà Tó O Bá Ń Wàásù Nílé Elérò Púpọ̀
1. Kí ni “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere” ní nínú?
1 Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ohun tá a fẹ́ ni pé ká “jẹ́rìí kúnnákúnná sí ìhìn rere.” (Ìṣe 20:24) Ìdí nìyẹn tá a fi ń sapá láti wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa. Èyí sì kan ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tó ń gbé nílé elérò púpọ̀ (bí ọgbà tó láwọn ilé tó pọ̀, àwọn ilé alágbèékà àtàwọn ilé onígéètì tí kò rọrùn láti wọ̀). Nígbà míì, ó lè ṣòro láti wọlé lọ wàásù fún àwọn tó ń gbé irú ilé bẹ́ẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbé nírú àwọn ilé bẹ́ẹ̀, àǹfààní ló jẹ́ láti túbọ̀ jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbọ́ ìhìn rere náà.
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lo ọgbọ́n àti òye nígbà tá a bá ń wàásù nílé elérò púpọ̀?
2 Nítorí ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá tó túbọ̀ ń gbòde kan, ńṣe ni wọ́n máa ń ti ọ̀pọ̀ ilé pa, tí wọ́n á sì gba àwọn ẹ̀ṣọ́ sẹ́nu géètì tàbí kí wọ́n ní kámẹ́rà tí wọ́n fi ń ṣọ́ ohun tó ń lọ. (2 Tím. 3:1, 2) Àwọn tó nilé lè ṣòfin pé àwọn kò fẹ́ kí àlejò táwọn ò retí wọlé. Ẹni tó ń bójú tó ilé sì lè ní ká jáde kúrò lọ́gbà wọn, pàápàá tí ayálégbé bá sọ pé òun ò fẹ́. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa lo ọgbọ́n àti òye nígbà tá a bá ń wàásù nírú ilé bẹ́ẹ̀.
3. Ìgbà wo ló dáa jù láti lọ wàásù láwọn ilé elérò púpọ̀, kí sì nìdí?
3 Ìgbà Tó Yẹ Ká Lọ Wàásù Níbẹ̀: Bíi tàwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù míì, ìgbà tá a máa bá àwọn èèyàn nílé ló yẹ ká máa lọ wàásù láwọn ilé elérò púpọ̀. Àwọn èèyàn lè máa fura sí wa tó bá jẹ́ pé ìgbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò sí nílé la lọ síbẹ̀. Ọ̀pọ̀ akéde ló ti ṣeé ṣe fún láti bá àwọn èèyàn lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ tàbí lọ́wọ́ ọ̀sán Saturday àti Sunday. Àwọn ayálégbé lè fẹjọ́ sun àwọn tó ń bójú tó ilé, tá a bá lọ wàásù níbẹ̀ láàárọ̀ kùtùkùtù, àgàgà kó tún wá jẹ́ lópin ọ̀sẹ̀.
4, 5. Báwo la ṣe lè rọ́nà wọlé sínú àwọn ilé tí wọ́n máa ń tì pa?
4 Bá A Ṣe Máa Rí Ọ̀nà Wọlé: Àwọn akéde kò gbọ́dọ̀ sọ fún ẹni tó ń bójú tó ilé tàbí ẹlòmíì tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé náà ṣáájú kí wọ́n tó lọ wàásù níbẹ̀. Bí wọ́n bá ti ilé náà pa, àmọ́ tí wọ́n ní ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ lẹ́nu ọ̀nà, a lè lò ó láti fi wá ẹni táá jẹ́ ká wọlé wá bá òun sọ̀rọ̀. A tún lè máa lọ láti ẹnu ọ̀nà kan sí òmíràn nínú ilé náà lẹ́yìn tá a bá ti bá ẹni tó pè wá wọlé sọ̀rọ̀ tán, àmọ́ èyí sinmi lórí irú ilé tó bá jẹ́ o. Àmọ́, nínú àwọn ilé míì, ó lè bọ́gbọ́n mu pé ká jáde, ká tún wá lo ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tó wà lẹ́nu ọ̀nà láti kàn sí ẹlòmíì nínú ilé náà. Ó yẹ ká lo òye láti pinnu iye àwọn ayálégbé tá a máa kàn sí látorí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ lásìkò yẹn.
5 Àwọn ayálégbé kan lè fẹ́ kó o sọ ohun tó o bá wá fáwọn lórí ẹ̀rọ̀. Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, sọ ọ́ lọ́nà tó máa tu ẹni náà lára. Fi orúkọ onílé náà pè é, tó bá wà nínú ìwé tí wọ́n máa ń fi sí ẹ̀gbẹ́ tẹlifóònù tí wọ́n kọ orúkọ àwọn tó ń gbé nínú ilé náà sí. Ní ṣókí, sọ ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé. Àwọn kan ti kẹ́sẹ járí nípa kíka ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn jáde tààràtà látinú ìwé Reasoning.
6. Kí ló yẹ ká ṣe nígbà tá a bá ń wàásù nínú ilé tó ní ẹ̀ṣọ́ tó wà lẹ́nu géètì?
6 Bí ẹ̀ṣọ́ tó wà lẹ́nu géètì ilé kan kò bá fẹ́ ká wọlé, a kúkú lè wàásù fún òun fúnra rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ ló máa ń gbádùn kíka àwọn ìwé wa. A tiẹ̀ lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ náà, ká sì máa lo ibi táwọn àlejò máa ń dúró sí fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Tí ẹ̀ṣọ́ náà bá gbà wá láyè láti lọ bá ayálégbé kan tó fìfẹ́ hàn, kò ní dáa ká wá lo àǹfààní yìí láti lọ máa kan ilẹ̀kùn àwọn ẹlòmíì nínú ilé náà.
7. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa báàgì tá à ń gbé lọ sóde ẹ̀rí?
7 Ìrísí tó Dára àti Ìwà Ọmọlúwàbí: Àwọn èèyàn lè máa fura sí wa tó bá jẹ́ àpò ńlá gbàǹgbà la gbé. Torí náà, báàgì kékeré ló máa dáa jù ká gbé tàbí ká má tiẹ̀ gbé ìkankan rárá. Inú báàgì pẹlẹbẹ làwọn akéde kan máa ń fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fẹ́ lò sí, wọ́n á wá mú Bíbélì wọn sọ́wọ́ tàbí kí wọ́n fi sínú àpò aṣọ tí wọ́n wọ̀.
8. Báwo ló ṣe yẹ ká ṣètò àwọn ará nígbà tá a bá ń wàásù nínú ilé elérò púpọ̀?
8 Kò dáa ká kóra jọ síwájú ilé tàbí àwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí torí pé èyí á gbàfiyèsí àwọn èèyàn. Ó sì yẹ ká ṣe àwọn ètò tó bá yẹ ṣáájú tá a bá fẹ́ lọ wàásù nínú ilé elérò púpọ̀ láwọn àdúgbò tí ìwà ọ̀daràn ti pọ̀ gan-an. (Òwe 22:3) Bí àpẹẹrẹ, a lè ní káwọn akéde mẹ́rin tàbí mẹ́fà, tá a pín ní méjì-méjì ṣiṣẹ́ ní àjà kan náà nínú ilé, kí wọ́n má sì jìnnà síra wọn kí wọ́n baà lè máa gbóhùn ara wọn, wọ́n tiẹ̀ lè máa pín iṣẹ́ náà ṣe láàárín ara wọn, káwọn kan dúró nígbà táwọn kan bá ń wàásù lọ́wọ́.
9. Báwo la ṣe lè hùwà tó bójú mu, kí sì nìdí tó fi yẹ bẹ́ẹ̀?
9 Nígbà tẹ́ ẹ bá wọ ilé kan, kẹ́ ẹ nu bàtà yín dáadáa, kẹ́ ẹ sì rí i pé ẹ tilẹ̀kùn kẹ́ ẹ tó kúrò lẹ́nu ọ̀nà. Tá a bá hùwà lọ́nà tó bójú mu báyìí, ìyẹn lè mú kí àròyé táwọn onílé lè ṣe mọ níwọ̀n. Tẹ́ ẹ bá ti wọlé, dípò tẹ́ ẹ ó fi máa fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri inú ilé, ńṣe ni kẹ́ ẹ lọ síbi tẹ́ ẹ ti fẹ́ lọ wàásù ní tààràtà. Èyí kò ní jẹ́ káwọn tó ń wò wá máa fura sí wa.
10. Báwo la ṣe lè yẹra fún fífi ariwo dí àwọn onílé lọ́wọ́?
10 Ní ọ̀pọ̀ ilé elérò, àwọn tó wà nínú yàrá sábà máa ń gbọ́ ohun téèyàn bá ń sọ ní ọ̀ọ̀dẹ̀. Torí náà, má ṣe sọ̀rọ̀ sókè ju bó ṣe yẹ lọ tó o bá ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀. Tó bá sì jẹ́ pé akéde kan lò ń bá sọ̀rọ̀, jẹ́ kí ohùn rẹ lọ sílẹ̀, àmọ́ kì í ṣe pé ká wá máa sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ o, torí ìyẹn lè mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í fura. Bákan náà, ọgbọ́n táwọn akéde kan máa ń dá kí wọ́n má bàa máa dí àwọn onílé lọ́wọ́ ni pé, wọn kì í kan àwọn ilẹ̀kùn bí wọ́n ṣe tò tẹ̀ léra. Kaka bẹ́ẹ̀, bí wọ́n bá wàásù díẹ̀ lápá òkè nínú ilé kan, wọ́n á tún lọ sọ́wọ́ ìsàlẹ̀ ilé náà láti lọ wàásù díẹ̀, kí wọ́n tún tó pa dà wá síbi tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀. Lọ́nà yìí, ìró ilẹ̀kùn tí wọ́n ń kàn ò ní máa dí àwọn onílé tí yàrá wọ́n bá sún mọ́ra lọ́wọ́. Láfikún sí i, kò yẹ ká máa kanlẹ̀kùn gbà-gbà-gbà, torí pé ó lè ṣẹ̀rù ba àwọn tó wà nínú ilé.
11. Kí làwọn ohun tá a lè ṣe nígbà tá a bá kan ilẹ̀kùn tó ní ihò téèyàn lè gbà yọjú?
11 Tí ilẹ̀kùn kan bá ní ihò tí ẹni tó wà nínú ilé lè gbà yọjú wo ẹni tó ń kanlẹ̀kùn, á dáa kó o dúró síbi tí ẹni tó wà nínú ilé ti lè rí ìwọ àtẹni tẹ́ ẹ jọ ṣiṣẹ́. Máa wo ojú ihò yẹn tààrà, tó o bá sì rí i pé ẹnì kan ń yọjú, kí onítọ̀hún pẹ̀lú ọ̀yàyà, kó o sì bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. Tí ẹni náà bá béèrè pé ‘Ta ni yẹn?’ ó máa dáa kó o sọ orúkọ rẹ àti tẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́. Ìyẹn lè fọkàn onílé balẹ̀, kó sì ṣílẹ̀kùn. Tí kò bá ṣílẹ̀kùn, o ṣì lè sọ ohun tó o fẹ́ sọ.
12. Kí la lè ṣe tá ò fi ní dá wàhálà sílẹ̀ nígbà tá a bá ń fìwé sílẹ̀ fáwọn tí kò sí nílé?
12 Àwọn Tí Kò Bá Sí Nílé: Ohun táwọn tó ń bójú tó ilé sábà máa ń sọ ni pé, ńṣe làwọn máa ń ṣa àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa láàárín ọ̀ọ̀dẹ̀ tàbí nílẹ̀. Tá a bá fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sẹ́nu ilẹ̀kùn, ó lè já bọ́ kó sì dá ìdọ̀tí sílẹ̀. Torí náà, àwọn ìwé tá a bá fi sílẹ̀ fáwọn tí kò sí nílé gbọ́dọ̀ wà níbì táwọn tó ń kọjá ò ti ní rí i.
13. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá pàdé onílé tínú ń bí?
13 Tí Onílé Bá Ń Bínú: Bá a bá pàdé ẹni tínú ń bí, tó sì fẹ́ pe ẹni tó ń bójú tó ilé náà sí wa, ohun tó dáa jù ni pé ká kúrò níbẹ̀, ká sì pa dà lọ lọ́jọ́ míì. Nígbà míì, ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé ohun tó máa dáa ni pé ká kúrò nínú ilé náà pátápátá, kó má bàa di pé ẹni tó ń bójú tó ilé náà á wá kò wá lójú. Kódà, bí onílé náà ò bá dìídì sọ pé ká má pa dà wá nígbà míì, ó máa dáa ká kọ nọ́ńbà ilé yẹn ká sì lẹ̀ ẹ́ mọ́ ara káàdì tá a ya àwòrán ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ sí, ìyẹn territory card, ká sì kà á mọ́ ara ilé tí wọ́n ò ti fẹ́ ká ìwàásù. Bíi táwọn ilé míì tí wọ́n ò ti fẹ́ ká wàásù, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan a lè kàn sí ilé yẹn láti mọ̀ bóyá èrò àwọn tó ń gbé ilé yẹn ti yí pa dà.
14, 15. Tí ẹnì kan tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé kan bá ni ká máa lọ, kí lo yẹ ká ṣe?
14 Tí Wọ́n Bá Ní Kó O Máa Lọ: Tó o bá ń wàásù nínú ilé kan, tí ẹni tó ń bójú tó ilé, ẹ̀ṣọ́, ẹni tó ń tún ohun tó bà jẹ́ nínú ilé ṣe tàbí òṣìṣẹ́ míì nínú ilé náà bá wá sọ fún ẹ pé kó o máa lọ, á dáa kó o fibẹ̀ sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ó yẹ ká máa yẹra fún ohun tó lè mú káwọn èèyàn kò wá lójú, kí wọ́n sì máa fi òfin halẹ̀ mọ́ wa tàbí pé àwọn á fi ọlọ́pàá mú wa. Kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé elérò púpọ̀ ló kórìíra àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ iṣẹ́ tí wọ́n rán wọn ni wọ́n ń jẹ́.
15 Nígbà míì, bí ẹni tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé elérò púpọ̀ bá ní kó o máa lọ, o lè fi sùúrù àti ọgbọ́n ṣàlàyé ìdí tó o fi wá fún un. (1 Pét. 3:15) A mọ̀ pé ojúṣe ẹ̀ ló ń ṣe láti mú kí ilé náà tu àwọn tó ń gbé ibẹ̀ lára kó sì rí sí ọ̀ràn ààbò ilé náà. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó fún ẹ láyé láti dúró. Láìjẹ́ bẹ́ẹ̀, fibẹ̀ sílẹ̀ láìjanpata. Bí àyè bá wà, ó lè ni kó jẹ́ kó o fi àwọn ìwé wa síbi táwọn àlejò máa ń dúró sí tàbí síbi tí wọ́n tí ń fọṣọ. (Kól. 4:6) Ká sì jẹ́ kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn mọ̀ nípa ohun tó wáyé náà.
16. Kí ló yẹ ká ṣe tí ìṣòro tá a bá pàdé nígbà tá a fẹ́ wàásù nínú ilé elérò púpọ̀ ò bá yanjú?
16 Bó bá ṣeé ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, àwọn akéde tún lè fọgbọ́n wá bí wọ́n á ṣe ṣíṣẹ́ nínú ilé yẹn. Àmọ́, tí ò bá sí ìyàtọ̀, káwọn alàgbà kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì fún ìrànlọ́wọ́, dípò táwọn akéde á fi máa gbìyànjú láti bójú tó ìṣòro náà fúnra wọn. Báwọn akéde ò bá lè ṣiṣẹ́ nínú ilé náà, kí wọ́n wá ọ̀nà míì tí wọ́n á fi rí àwọn tó ń gbé ilé yẹn bá sọ̀rọ̀, irú bíi kíkàn sí wọn nípa ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù tàbí nípasẹ̀ lẹ́tà. Àwọn akéde kan tiẹ̀ máa ń ṣe ìjẹ́rìí òpópónà níwájú irú ilé bẹ́ẹ̀ tàbí níbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ilé yẹn lọ́wọ́ àárọ̀ nígbà táwọn èèyàn bá ń lọ síbi iṣẹ́ tàbí nírọ̀lẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń pa dà bọ̀ nílé.
17. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa wàásù nínú ilé elérò púpọ̀?
17 Òpin ètò àwọn nǹkan yìí kò ní pẹ́ dé mọ́. Kìkì àwọn tó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ló sì máa rí ìgbàlà. “Àmọ́ ṣá o, báwo ni wọn yóò ṣe ké pe ẹni tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀?” (Róòmù 10:13, 14) Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” ló ń gbé nínú ilé elérò púpọ̀. (Ìṣe 13:48) Bá a bá ń lo ọgbọ́n àti òye, a ṣeé ṣe fún wa láti mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ wọn.