Àpótí Ìbéèrè
◼ Kí ló yẹ kó o ṣe bí wọ́n bá ní kó o má wàásù níbìkan?
Láwọn ìgbà míì, àwọn ọlọ́pàá máa ń sọ fún àwọn akéde tó wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ pé ohun tí wọ́n ń ṣe lòdì sí òfin, wọ́n á sì ní kí wọ́n má ṣe wàásù mọ́. Bí wọ́n bá sọ bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o bọ̀wọ̀ fún wọn kó o sì tètè fi ìpínlẹ̀ ìwàásù náà sílẹ̀. (Mát. 5:41; Fílí. 4:5) Má ṣe gbìyànjú láti yanjú ìṣòro náà fúnra rẹ nípa ṣíṣàlàyé àwọn ẹ̀tọ́ tá a ní lábẹ́ òfin. Bó bá ṣeé ṣe, dọ́gbọ́n wo orúkọ àti nọ́ńbà ìdánimọ̀ ọlọ́pàá náà. Lẹ́yìn náà, tètè sọ fún àwọn alàgbà, kí wọ́n lè fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó ẹ̀ka ọ́fíìsì létí. Bákan náà, bí ẹnì kan tó ń bójú tó ilé tàbí ẹni tó ń ṣojú fún àwọn tó ń gbé nínú ilé elérò púpọ̀ bá ní kó o jáde nílé náà, yára fi ibẹ̀ sílẹ̀, kó o sì sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún àwọn alàgbà. Bá a bá fi sùúrù àti ìrẹ̀lẹ̀ bá àwọn tó wà ní ipò àṣẹ lò, èyí á jẹ́ ká yẹra fún àwọn ìṣòro tí kò pọn dandan.—Òwe 15:1; Róòmù 12:18.