ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb23 July ojú ìwé 3
  • ‘À Ń Gbèjà Ìhìn Rere, A sì Fìdí Rẹ̀ Múlẹ̀ Lọ́nà Òfin’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘À Ń Gbèjà Ìhìn Rere, A sì Fìdí Rẹ̀ Múlẹ̀ Lọ́nà Òfin’
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Dídáàbò Bo Ìhìn Rere Lọ́nà Òfin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀ Kó O sì Gbà Pé Àwọn Nǹkan Kan Wà Tó Ò Mọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
mwb23 July ojú ìwé 3
Àwòrán: 1. Gathie àti Marie Barnett. 2. Arákùnrin Kokkinakis àtàwọn míì ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù. 3. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ilé Ẹjọ́ Rostov ní Rọ́ṣíà. 4. Àwọn arákùnrin kan níwájú Ilé Ẹjọ́ Ìjọba Ilẹ̀ South Korea.

Kokkinakis àti Greece: Droit réservé

Láti apá òsì lókè sápá ọ̀tún: West Virginia State Board of Education àti Barnette; Kokkinakis àti Greece; Taganrog LRO and Others àti Russia; Cha and Others àti South Korea

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

‘À Ń Gbèjà Ìhìn Rere, A sì Ń Fìdí Rẹ̀ Múlẹ̀ Lọ́nà Òfin’

Nígbà táwọn alátakò fẹ́ dá iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì dúró, ṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fọ̀rọ̀ náà tó àwọn aláṣẹ létí, kí wọ́n lè lómìnira láti máa bá iṣẹ́ náà lọ. (Ẹsr 5:11-16) Bákan náà lónìí, àwa Kristẹni máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti gbèjà ìhìn rere, ká sì fìdí ẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ òfin. (Flp 1:7) Torí náà lọ́dún 1936, a dá Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Òfin sílẹ̀ ní orílé-iṣẹ́ wa ká lè máa fi gbèjà ìhìn rere. Lónìí, ẹ̀ka yìí máa ń ṣètò bá a ṣe lè gbèjà ìhìn rere kárí ayé. Àwọn nǹkan wo ni ẹ̀ka yìí ti ṣe kí iṣẹ́ ìwàásù lè máa tẹ̀ síwájú, káwa èèyàn Ọlọ́run sì lómìnira láti máa jọ́sìn Ọlọ́run wa?

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ ÌBẸ̀WÒ SÍ Ẹ̀KA TÓ Ń RÍ SỌ́RỌ̀ ÒFIN LÓRÍLÉ-IṢẸ́, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwọn ìṣòro wo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dojú kọ lábẹ́ òfin?

  • Àwọn àṣeyọrí wo la sì ti ṣe? Sọ àpẹẹrẹ kan

  • Kí ni àwa náà lè ṣe láti ‘gbèjà ìhìn rere, ká sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin’?

  • Ibo lórí ìkànnì wa lo ti lè rí ìsọfúnni nípa ọ̀rọ̀ òfin tó kan àwa èèyàn Ọlọ́run àti orúkọ àwọn ará wa tí wọ́n ti fi sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn?

Ká sọ pé lọ́jọ́ kan ò ń wàásù, àwọn aláṣẹ wá sọ fún ẹ pé ṣe lò ń tẹ òfin lójú, má ṣe gbìyànjú láti dá yanjú ọ̀rọ̀ náà, má sì bá wọn jiyàn pé o lẹ́tọ̀ọ́ láti wàásù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o gbà pẹ̀lú wọn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, tó bá jẹ́ pé ọlọ́pàá ló sọ fún ẹ pé o ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́, tó bá ṣeé ṣe, fọgbọ́n wo orúkọ àti nọ́ńbà tó wà lára aṣọ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, sọ fáwọn alàgbà kí wọ́n lè kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì láti bójú tó ọ̀rọ̀ náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́