Àpótí Ìbéèrè
◼ Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa pín àsọyé tá a gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ tàbí àwọn àkọsílẹ̀ tá a ṣe nígbà tá à ń gbọ́ àsọyé?
Àwọn àsọyé tá a gbé ka Bíbélì máa ń fún wa lókun, wọ́n sì máa ń fún wa ní ìṣírí. (Ìṣe 15:32) Torí náà, ó máa ń wù wá láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó fún wa níṣìírí yẹn fún àwọn tí kò wá sípàdé. Ní báyìí tí àwọn ẹ̀rọ tá a lè fi gbohùn sílẹ̀ ti pọ̀ lóríṣiríṣi, ó rọrùn gan-an láti gba ọ̀rọ̀ àsọyé sílẹ̀ ká sì wá máa pín in fún àwọn ẹlòmíì. Àwọn kan ti gba ọ̀pọ̀ àsọyé sílẹ̀, títí kan èyí tá a ti sọ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, èrò tó dáa ni wọ́n sì ní lọ́kàn nígbà tí wọ́n ń yá àwọn míì láwọn àsọyé náà tàbí tí wọ́n ṣe ẹ̀dà rẹ̀ fún àwọn ọ̀rẹ́ wọn. Àwọn míì tiẹ̀ ní ìkànnì lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, wọ́n sì ti gbé àwọn àsọyé síbẹ̀ kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ lè wà á jáde.
Òótọ́ ni pé kì í ṣe ohun tó burú bí ẹnì kan bá gba ọ̀rọ̀ àsọyé sílẹ̀ fún àǹfààní ara rẹ̀ tàbí ìdílé rẹ̀. Bákan náà, àwọn alàgbà lè ṣètò pé kí wọ́n gba àsọyé sílẹ̀ fún àǹfààní àwọn tí ara wọn kò le nínú ìjọ tí wọn ò sì lè wá sí ìpàdé. Àmọ́, àwọn ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ wà tí a kò gbọ́dọ̀ fi máa pín àsọyé tá a gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ tàbí ká máa pín àwọn àkọsílẹ̀ tá a ṣe nígbà tá à ń gbọ́ àsọyé.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ sábà máa ń pinnu bí alásọyé ṣe máa gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀, ó ṣeé ṣe ká ṣi àwọn kókó tó wà nínú àsọyé tá a ti gbà sílẹ̀ náà lóye, torí a kò mọ ìdí tí alásọyé fi gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́nà bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ó lè ṣòro fún wa láti mọ ẹni tó sọ àsọyé náà àti ìgbà tó sọ ọ́, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó dá wa lójú pé àwọn ìsọfúnni inú àsọyé náà bágbà mu ó sì jóòótọ́. (Lúùkù 1:1-4) Síwájú sí i, tá a bá ń pín ọ̀rọ̀ àsọyé tá a ti gbà sílẹ̀ tàbí àkọsílẹ̀ tá a ṣe nígbà tá à ń gbọ́ àsọyé, èyí lè jẹ́ káwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí pe àfiyèsí tí kò yẹ sí ara wọn tàbí kí àwọn míì máa fúnni láfiyèsí àti ọ̀wọ̀ tí kò yẹ.—1 Kọ́r. 3:5-7.
Ẹrú olóòótọ́ àti olóye ń ṣiṣẹ́ kára láti pèsè “ìwọ̀n” oúnjẹ tẹ̀mí tá a nílò àti ní “àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Lúùkù 12:42) Èyí sì kan ètò tí wọ́n ṣe pé ká máa sọ àsọyé ní àwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ká sì máa wa àwọn ọ̀rọ̀ tá a ti gbà sílẹ̀ jáde láti orí ìkànnì jw.org. Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé ẹrú olóòótọ́ àti olóye àti Ìgbìmọ̀ Olùdarí rẹ̀ máa pèsè ohun tá a nílò ká bàa lè dúró gbọin-in nínú ìgbàgbọ́.—Ìṣe 16:4, 5.