Bí A Ṣe Lè Lo Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Gbohùn Wọn Sílẹ̀
1. Láfikún sí àwọn ìtẹ̀jáde wa tó wà lórí ìwé, nǹkan míì tó máa ṣe wá láǹfààní wo la ní?
1 Ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ràn láti máa ka àwọn ọ̀rọ̀ tó ń múnú ẹni dùn, tó jẹ́ òótọ́, tó sì tọ̀nà lórí ìkànnì jw.org/yo. (Oníw. 12:10) Àmọ́, ṣé o máa ń tẹ́tí sí àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbohùn wọn sílẹ̀? Wọ́n á jẹ́ ká lè gbọ́ ọ̀pọ̀ ìsọfúnni tó wà lórí ìkànnì wa. Báwo ni wọ́n ṣe lè ṣe wá láǹfààní?
2. Báwo la ṣe lè lo àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbohùn wọn sílẹ̀ nígbà ìdákẹ́kọ̀ọ́ tàbí ìjọsìn ìdílé wa?
2 Ó Wúlò Nígbà Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Tàbí Ìjọsìn Ìdílé: Tá a bá ń tẹ́tí sí àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbohùn wọn sílẹ̀, irú bíi Bíbélì, àwọn ìwé ìròyìn tàbí àwọn ìtẹ̀jáde míì nígbà tá a bá ń rìnrìn-àjò tàbí tá a bá wà lẹ́nu àwọn ìgbòkègbodò ojoojúmọ́, èyí á jẹ́ ká lè máa fi ọgbọ́n lo àkókò wa. (Éfé. 5:15, 16) A tún lè mú kí ọ̀nà tá a gbà ń ṣe ìjọsìn ìdílé wa túbọ̀ gbádùn mọ́ni tá a bá ń tẹ́tí sí àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbohùn wọn sílẹ̀, ká sì máa fojú bá a lọ nínú ìwé wa. Tí a bá ń tẹ́tí sí àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbohùn wọn sílẹ̀ nígbà ìdákẹ́kọ̀ọ́, èyí á jẹ́ ká lè mú ọ̀nà tí a gbà ń kàwé ní èdè wa sunwọ̀n sí i tàbí ká lò ó tá a bá ń kọ́ èdè míì.
3. Àwọn wo ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ló máa jàǹfààní nínú àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbohùn wọn sílẹ̀?
3 Ó Wúlò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù: Àwọn kan ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa tí kì í ráyè láti ka ìwé lè nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbohùn wọn sílẹ̀. A tún lè lò ó tá a bá pàdé àwọn èèyàn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa, tí wọ́n á sì fẹ́ gbọ́ ìwàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run tá a bá sọ fún wọn ní ‘èdè wọn.’ (Ìṣe 2:6-8) Ní àwọn ibì kan, ó jẹ́ àṣà wọn láti máa tẹ́tí sí ohun tí àwọn èèyàn bá sọ. Bí àpẹẹrẹ, nínú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn ará Ṣáínà kan tí wọ́n ń pè ní Hmong, wọ́n máa ń sọ ìtàn ìran wọn fáwọn ọmọ wọn kékeré, àwọn ọmọ yìí sì máa ń rántí ohun tí wọ́n bá sọ fún wọn dáadáa. Ní ọ̀pọ̀ ibi nílẹ̀ Áfíríkà, ìtàn la sábà máa fi ńkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́.
4. Àwọn ìbéèrè wo la lè bi ara wa nípa bí a ṣe lè ran àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa lọ́wọ́?
4 Ǹjẹ́ o rò pé ó máa ṣe ẹni tó o bá sọ̀rọ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín láǹfààní tó o bá jẹ́ kó gbọ́ ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ tó wà lédè rẹ̀? Tó o bá fi ìtẹ̀jáde kan tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ ránṣẹ́ sí ẹnì kan nípasẹ̀ lẹ́tà orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ǹjẹ́ o rò pé ó máa ṣe é láǹfààní? Ǹjẹ́ o lè wa ìtẹ̀jáde kan tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ jáde lórí ìkànnì, kó o gbé e sórí àwo CD, kó o sì fún ẹni tó o wàásù fún ní àwo yìí àti ìtẹ̀jáde náà tá a tẹ̀ sórí ìwé? A lè ròyìn odindi ìtẹ̀jáde wa tó ṣe é kà lórí ẹ̀rọ, irú bí ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé ìròyìn tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú tá a bá fún àwọn èèyàn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. A ṣe àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbohùn wọn sílẹ̀ yìí ká lè máa fi ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ ká sì máa lò ó láti fún irúgbìn òtítọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run.—1 Kọ́r. 3:6.