ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb23 May ojú ìwé 13
  • Ṣé O Máa Ń Lo Bíbélì Tá A Gbohùn Rẹ̀ Sílẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé O Máa Ń Lo Bíbélì Tá A Gbohùn Rẹ̀ Sílẹ̀?
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí A Ṣe Lè Lo Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Gbohùn Wọn Sílẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Àwọn Èrọ Tó Ń Gbé Ohùn àti Fídíò Jáde Ń Mú Ká Túbọ̀ Gbádùn Àwọn Àpéjọ Wa
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
  • Ìkànnì Wa Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì—Fi Ran Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì Lọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Kí Lèrò Rẹ?
    Jí!—2019
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
mwb23 May ojú ìwé 13
Àwòrán: Àwọn tó ń gbọ́ Bíbélì tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀. 1. Arákùnrin kan lo ẹ̀rọ tí wọ́n ń gbé sétí láti gbọ́ àtẹ́tísí Bíbélì lórí fóònù rẹ̀ bó ṣe ń gba atẹ́gùn níta. 2. Ìyá kan àti ọmọbìnrin rẹ̀ ń gbọ́ Bíbélì tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì ń fojú bá a lọ nínú Bíbélì tá a tẹ̀ sórí ìwé. 3. Arábìnrin kan ń fi ẹ̀rọ tí wọ́n máa ń kì bọ etí gbọ́ àtẹ́tísí Bíbélì bó ṣe wà nínú ọkọ̀ èrò.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣé O Máa Ń Lo Bíbélì Tá A Gbohùn Rẹ̀ Sílẹ̀?

Bíbélì tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ ni Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a kà sórí ẹ̀rọ. Díẹ̀díẹ̀ là ń gbé àwọn àtẹ́tísí yìí jáde lónírúurú èdè. Ọ̀kan lára ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa Bíbélì yìí ni pé ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ka ọ̀rọ̀ ẹni kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ẹ̀. Wọ́n ka àwọn ọ̀rọ̀ náà bó ṣe wà níbẹ̀ gẹ́lẹ́, wọ́n sì lo ìmọ̀lára tó yẹ láti gbé àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì jáde lọ́nà tó péye.

Àǹfààní wo làwọn kan ti rí bí wọ́n ṣe ń gbọ́ Bíbélì tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀? Ọ̀pọ̀ àwọn tó sábà máa ń gbọ́ àtẹ́tísí yìí sọ pé ó máa ń jẹ́ kó dà bíi pé àwọn wà níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé. Bí wọ́n ṣe ń gbọ́ onírúurú ohùn tí wọ́n lò fáwọn tó wà nínú Bíbélì jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti fojú inú yàwòrán àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì, kí wọ́n sì lóye ẹ̀ dáadáa. (Owe 4:5) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ti rí i pé táwọn bá ń gbọ́ àtẹ́tísí lásìkò tí àníyàn bá gbà wọ́n lọ́kàn, ó máa ń jẹ́ kára tù wọ́n.​—Sm 94:19.

Tí wọ́n bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí wa létí, ìyẹn lè mú ká máa ṣe ohun tó tọ́. (2Kr 34:19-21) Tó bá jẹ́ pé Bíbélì tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ wà lódindi tàbí lápá kan ní èdè tó o gbọ́, ṣé o lè máa tẹ́tí sí i déédéé kó sì jẹ́ apá kan lára nǹkan tẹ̀mí tó o máa ń ṣe?

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ BÍ A ṢE ṢE BÍBÉLÌ TÍ A GBOHÙN RẸ̀ SÍLẸ̀​—ÀYỌLÒ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

Kí ló wú ẹ lórí nípa bá a ṣe ṣe Bíbélì tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́