Kí Làwọn Èèyàn Máa Ń Kọ́ Lára Rẹ?
1. Ẹ̀kọ́ wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ́ lára rẹ̀?
1 Jésù sọ pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi.” (Mát. 11:29) Ó ṣe kedere pé ó kọ́ àwọn èèyàn nípasẹ̀ àpẹẹrẹ rere tó fi lélẹ̀, kì í ṣe nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìkan. Ronú nípa ẹ̀kọ́ táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ́ lára rẹ̀. Ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́, onínúure ni, ó sì nífẹ̀ẹ́. (Mát. 8:1-3; Máàkù 6:30-34) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Jésù kì í ṣe ti ojú ayé lásán. (Jòh. 13:2-5) Bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n rí i pé akíkanjú èèyàn ni, ó sì máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́. (Lúùkù 8:1; 21:37, 38) Ipa wo ni ohun táwọn èèyàn bá kíyè sí lára wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ lè ní lórí wọn?
2. Báwo ni ìrísí àti ìwà rere wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣe lè ní ipa tó dáa lórí àwọn tá à ń wàásù fún?
2 Àwọn Tá À Ń Wàásù Fún: Bá a bá múra níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tá a ní ìwà rere, tá a sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn tá à ń wàásù fún jẹ wá lógún, èyí lè ní ipa rere lórí wọn. (2 Kọ́r. 6:3; Fílí. 1:27) Wọ́n máa ń kíyè sí pé a ń lo Bíbélì nígbà gbogbo. Inú àwọn míì máa ń dùn pé à ń tẹ́tí sí wọn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀. Bá a bá ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ ní àwọn ọ̀nà yìí, ó lè mú kí àwọn èèyàn fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run.
3. Ipa rere wo la lè ní lórí àwọn ara wa?
3 Àwọn Ará Wa: Tún ronú lórí ipa rere tá a lè ní lórí àwọn ará wa. Bá a bá ní ìtara lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, èyí lè mú káwọn ará wa mìíràn pẹ̀lú ní ìtara. Gẹ́gẹ́ bí irin ṣe máa ń pọ́n irin, bá a bá múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ wa dáadáa, èyí lè mú kí àwọn míì pẹ̀lú mú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà wàásù sunwọ̀n sí i. (Òwe 27:17) Bá a bá ń sapá gidigidi láti máa ṣe àkọsílẹ̀ tó péye nípa àwọn tó fetí sí ìwàásù wa, tá a sì tètè ń pa dà lọ sọ́dọ̀ wọn, èyí á mú káwọn míì pẹ̀lú fẹ́ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. A máa ní ipa tó dáa gan-an lórí àwọn ará wa tá a bá ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún.—2 Tím. 4:5.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣàyẹ̀wò irú àpẹẹrẹ tá à ń fi lélẹ̀ látìgbàdégbà?
4 Á dáa ká máa ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa látìgbàdégbà, ká sì máa ronú lórí irú àpẹẹrẹ tá à ń fi lélẹ̀ fáwọn ẹlòmíì. Bá a bá jẹ́ àpẹẹrẹ rere, èyí á mú inú Jèhófà dùn, àwa náà á sì lè sọ gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti sọ pé: “Ẹ di aláfarawé mi, àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti di ti Kristi.”—1 Kọ́r. 11:1.