Ǹjẹ́ O Ti Lo Ẹ̀yìn Ìwé Ìròyìn?
Ohun tó wà ní iwájú ìwé ìròyìn ló máa ń kọ́kọ́ gba àfiyèsí àwọn èèyàn, lẹ́yìn náà wọ́n lè wo ẹ̀yìn ìwé náà gààràgà. Àwọn ìbéèrè àti àwọn ọ̀rọ̀ mélòó kan táwọn èèyàn máa ń nífẹ̀ẹ́ sí àti ojú ìwé tí wọ́n ti máa rí ìsọfúnni nípa rẹ̀ ló máa ń wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tá a máa ń fi sóde.
Àwọn ìsọfúnni tó máa ń wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn yìí lè jẹ́ ká mọ àwọn ìbéèrè tá a lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn. Tá a bá ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tá a máa ń ṣe léraléra, a lè máa yí ọ̀nà tá a gbà ń gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ pa dà nípa lílo ìbéèrè tó yàtọ̀ síra jálẹ̀ oṣù. Tí ọwọ́ ẹni tá a fẹ́ wàásù fún bá dí, a lè dín ọ̀rọ̀ wa kù nípa fífi ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn náà hàn án, ká wá sọ pé: “Bó o bá fẹ́ mọ ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn, mo lè fún ẹ ní ìwé ìròyìn yìí, a ó sì máa bá ọ̀rọ̀ wa lọ nígbà míì tí àyè bá wà.” Àwọn akéde kan lè fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò wọn nípa fífi ẹ̀yìn ìwé náà han ẹni tí wọ́n ń wàásù fún, kí wọ́n sì ní kó yan ìbéèrè tó nífẹ̀ẹ́ sí. Lẹ́yìn náà, wọ́n lè fi ibi tí ìdáhùn náà wà hàn án, wọ́n á sì ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ti múra sílẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ronú kan àwọn ọ̀nà míì tó o lè gbà lo ẹ̀yìn ìwé láti mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́.