Ṣé O Lè Máa Kópa Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Láwọn Ọjọ́ Sunday?
1. Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ látinú ohun tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó bá a rìnrìn-àjò ṣe ní ìlú Fílípì?
1 Ọjọ́ Sábáàtì lọjọ́ náà, ọjọ́ tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó wà ní ìlú Fílípì máa ń sinmi. Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó bá a rìnrìn-àjò ń lọ láti ìlú kan sí ìlú míì nígbà ọ̀kan lára àwọn ìrìn-àjò míṣọ́nnárì rẹ̀. Kó sẹ́nì tíì bá sọ pé ohun tí wọ́n ṣe burú ká ní àwọn náà sinmi lọ́jọ́ yẹn. Àmọ́, wọ́n mọ̀ pé àwọn Júù pé jọ sí ojúde ìlú láti gbàdúrà, torí náà wọ́n lo àǹfààní yẹn láti wàásù fún wọn. Ó dájú pé inú Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n bá a rìnrìn-àjò á dùn gan-an nígbà tí Lìdíà gbọ́ ìwàásù wọn, tí gbogbo agbo ilé rẹ̀ sì ṣe ìrìbọmi! (Ìṣe 16:13-15) Níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ọjọ́ Sunday ni ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sinmi lóde òní, ṣé ìwọ náà lè lo àkókò díẹ̀ lọ́jọ́ náà láti wàásù fún wọn?
2. Àwọn àtakò wo láwọn èèyàn Jèhófà ti borí kí wọ́n lè máa wàásù lọ́jọ́ Sunday láìsí ìdílọ́wọ́?
2 Àwọn Àtakò Tó Bá Ìwàásù Ọjọ́ Sunday: Lọ́dún 1927, a rọ àwọn èèyàn Jèhófà láti máa lo díẹ̀ lára ọjọ́ Sunday láti fi kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àtakò sí wa. Wọ́n fàṣẹ ọba mú ọ̀pọ̀ àwọn ará lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pé wọ́n rú òfin Sábáàtì tí wọ́n ń ṣe ní ọjọ́ Sunday, pé wọ́n ń dí aláàfíà ìlú lọ́wọ́ àti pé wọ́n ń tàwé láìgbàṣẹ. Àmọ́ àwọn èèyàn Jèhófà kò rẹ̀wẹ̀sì. Láàárín ọdún 1930 sí 1939, a ṣètò “ìwàásù ẹlẹ́kùnjẹkùn,” níbi tí àwọn akéde tó wà ní àwọn ìjọ tí kò jìnnà síra ti máa ń pàdé láti kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù kan. Wọ́n máa ń pọ̀ débi pé bí àwọn aláṣẹ bá tiẹ̀ mú akéde kan, kò lè ṣeé ṣe fún wọn láti dá gbogbo àwọn tó kù dúró. Ǹjẹ́ o mọrírì ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ táwọn ará yẹn ní tó fi mú ká lè máa wàásù lọ́jọ́ Sunday láìsí ìdílọ́wọ́?
3. Kí ló mú kí ọjọ́ Sunday jẹ́ ọjọ́ tó dára láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́?
3 Ọjọ́ Tó Dára Gan-An fún Iṣẹ́ Ìwàásù: Ọ̀pọ̀ èèyàn kì í lọ síbi iṣẹ́ lọ́jọ́ Sunday. Ara wọn sì sábà máa ń balẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lè fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run lọ́jọ́ Sunday. Tó bá jẹ́ pé ọjọ́ Sunday là ń ṣe ìpàdé wa, a ti máa ń múra lọ́nà tó bójú mu fún iṣẹ́ ìsìn pápá, torí náà a kúkú lè ṣètò láti lọ sí òde ẹ̀rí ṣáájú ìpàdé wa tàbí lẹ́yìn ìpàdé. Tó bá pọn dandan, ẹ lè gbé oúnjẹ díẹ̀ dání.
4. Ayọ̀ wo la máa ní tá a bá lo àkókò díẹ̀ lóde ẹ̀rí lọ́jọ́ Sunday?
4 Tá a bá lo àkókò díẹ̀ lóde ẹ̀rí lọ́jọ́ Sunday, a ṣì máa ní àkókò díẹ̀ láti fún ara wa ní ìsinmi tó nílò. A máa ní ìtẹ́lọ́rùn pé a ti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ nígbà tá a bá ń fún ara wa ní ìsinmi. (Òwe 19:23) A sì tún lè ní ayọ̀ ríran ẹnì kan bíi Lìdíà lọ́wọ́!