‘Kí Orúkọ Ọlọ́run Di Sísọ Di Mímọ́’
1. Kí ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àyíká wa ti ọdún 2012, ẹsẹ Bíbélì wo la sì gbé e kà?
1 Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa bá a ṣe ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run! Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ní ká máa jẹ́ orúkọ mọ́ òun, láti ọdún 1931 ni àwọn èèyàn sì ti mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ orúkọ tó dá yàtọ̀ náà, Jèhófà. (Aísá. 43:10) Ọwọ́ pàtàkì ni Jésù tó jẹ́ Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run fi mú orúkọ náà, ipò kìíní ló sì fi sí nínú àdúrà àwòṣe tó gbà. (Mát. 6:9) Orí ọ̀rọ̀ Jésù yìí la sì gbé ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àyíká wa ti ọdún 2012 kà. Ẹṣin ọ̀rọ̀ náà ni “Kí Orúkọ Ọlọ́run Di Sísọ Di Mímọ́.”
2. Àwọn ìsọfúnni wo là ń fojú sọ́nà fún?
2 Ohun Tá A Máa Gbọ́: Lọ́jọ́ Saturday, a máa gbọ́ àsọyé kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ẹ Fi Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún Sọ Orúkọ Ọlọ́run Di Mímọ̀.” Nínú àsọyé náà, a máa jíròrò ìdí tí iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe jẹ́ iṣẹ́ tó lérè nínú jù lọ téèyàn lè fi ayé rẹ̀ ṣe. A tún máa gbọ́ àpínsọ àsọyé kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Ṣọ́ra Kó O Má Ṣe Kó Ẹ̀gàn Bá Orúkọ Ọlọrun,” èyí tó máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa yẹra fún oríṣi nǹkan mẹ́rin tó lè dẹkùn mú wa. Nínú àsọyé tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ìdí Tó Fi Yẹ Kí Orúkọ Ọlọ́run Di Mímọ́,” a máa rí ìdáhùn sí ìbéèrè méjì yìí, Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fi ìtara wàásù nígbà tó bá jọ pé àwọn èèyàn kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa? àti, Kí ló máa jẹ́ ká lè máa ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó méso jáde? Lọ́jọ́ Sunday, a máa gbádùn àpínsọ àsọyé tó dá lórí bá a ṣe lè sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ nípasẹ̀ èrò inú wa, ọ̀rọ̀ ẹnu wa, àwọn ìpinnu tá à ń ṣe àti ìwà wa. Àwọn ẹni tuntun ní pàtàkì jù lọ máa gbádùn àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Jèhófà Máa Sọ Orúkọ Ńlá Rẹ̀ Di Mímọ́ ní Amágẹ́dọ́nì.”
3. Àǹfààní wo la ní, báwo sì ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé náà ṣe máa ràn wá lọ́wọ́?
3 Láìpẹ́-láìjìnnà, Jèhófà máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. (Ìsík. 36:23) Àmọ́ ní báyìí, a ní àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ kan láti máa ṣe gbogbo ohun tó máa gbé orúkọ mímọ́ Jèhófà ga. Ó dá wa lójú pé àpéjọ àyíká yìí máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa ṣe ojúṣe pàtàkì tá a ní, ìyẹn jíjẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run.