Gbogbo Ìgbà La Wà Lẹ́nu Iṣẹ́
1. Báwo la ṣe mọ̀ pé gbogbo ìgbà ni àwọn ajíhìnrere ní ọ̀rúndún kìíní máa ń wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?
1 Àwọn ajíhìnrere onítara ní ọ̀rúndún kìíní máa ń wàásù ìhìn rere “láìdábọ̀” níbikíbi tí wọ́n bá ti rí àwọn èèyàn. (Ìṣe 5:42) Torí náà, ó dájú pé nígbà tí wọ́n bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, wọn kì í wulẹ̀ kọjá lára àwọn tí wọ́n bá rí lójú ọ̀nà láìwàásù fún wọn. Bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò ní gbójú fo àǹfààní tí wọ́n bá ní láti wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà nígbà tí wọ́n bá ń ra nǹkan lọ́jà lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣíwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bíi ti Jésù, gbogbo ìgbà ni wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́.—Máàkù 6:31-34.
2. Kí la gbọ́dọ̀ máa ṣe tá a bá fẹ́ kí orúkọ wa máa rò wá?
2 Múra Tán Nígbà Gbogbo: Kì í ṣe ohun tá à ń ṣe nìkan ni orúkọ wa, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ń tọ́ka sí; ó tún ń tọ́ka sí ẹni tá a jẹ́. (Aísá. 43:10-12) Torí náà, ìgbà gbogbo ni a múra tán láti sọ ohun tó jẹ́ ìrètí wa, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé a kò sí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. (1 Pét. 3:15) Ǹjẹ́ o máa ń fojú sọ́nà fún àwọn ipò tó máa jẹ́ kó o lè wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà, ṣé o sì máa ń ronú lórí ohun tó o lè sọ? Ǹjẹ́ o máa ń kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ dání kó o lè fún àwọn tó bá fìfẹ́ hàn sí ọ̀rọ̀ rẹ? (Òwe 21:5) Ṣé ìwàásù ilé-dé-ilé nìkan lo máa ń ṣe àbí o máa ń wàásù ìhìn rere láwọn ọ̀nà míì, tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀?
3. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fojú kéré wíwàásù ní òpópónà, àwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí, ibi ìgbafẹ́, àwọn ilé ìtajà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ?
3 Wàásù “Ní Gbangba”: A máa ń wàásù ní òpópónà, àwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí, ibi ìgbafẹ́, àwọn ilé ìtajà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ǹjẹ́ irú àwọn ọ̀nà ìwàásù yìí ṣàjèjì, àbí wọn kì í ṣe ọ̀nà ìwàásù gidi tàbí pé ọ̀rọ̀ béèyàn bá fẹ́ ni? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé òun ń wàásù “ní gbangba” àti láti ilé dé ilé. (Ìṣe 20:20) Ìwàásù ilé-dé-ilé ló ṣì ń gbawájú, tó sì jẹ́ ọ̀nà tó rọrùn jù tá a gbà ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́ ṣá o, àwọn èèyàn ni àwọn ajíhìnrere ọ̀rúndún kìíní ń wá kiri, kì í ṣe àwọn ilé. Wọ́n máa ń lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n bá ní láti máa sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́, ní gbangba, lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà àti ní ilé dé ilé. Ǹjẹ́ kí àwa náà fi ṣe àfojúsùn wa láti máa wá àwọn èèyàn kiri kí ó lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún.—2 Tím. 4:5.