Kí Ni Ìdí Tó O Fi Ní “Ayọ̀ Ńláǹlà”?
1. Kí ni ìdí tí a fi máa ń ní ayọ̀ ńláǹlà ní ìparí oṣù kọ̀ọ̀kan?
1 Lẹ́yìn tí oṣù bá parí, tí wọ́n sì ní kí gbogbo wa fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wa sílẹ̀, kí ni ìdí tó o fi máa ń ní “ayọ̀ ńláǹlà”? (Gál. 6:4) Yálà a jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tó ń ròyìn àádóje [130] wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí a jẹ́ ara àwọn akéde tó láǹfààní láti máa ròyìn ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, ó yẹ kí gbogbo wa máa láyọ̀ pé a ti fi tọkàntọkàn ṣe iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà.—Sm. 100:2.
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?
2 Torí pé Jèhófà ni Olúwa Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, òun ló lẹ́tọ̀ọ́ ká fún ní ohun tó dára jù lọ tá a ní. (Mál. 1:6) Nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ya ara wa sí mímọ́ láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Torí náà, tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la ti yọ̀ǹda ohun tá a lè pè ní “àkọ́so” nínú àkókò wa, ẹ̀bùn àbínibí wa àti okun wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, lópin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tàbí ní ìparí oṣù, àwa fúnra wa yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà. (Òwe 3:9) Àmọ́ ṣá o, bí ẹ̀rí ọkàn wa bá ń sọ fún wa pé a ṣì lè ṣe ju ohun tí à ń ṣe báyìí lọ, ó yẹ ká ronú nípa àtúnṣe tá a bá lè ṣe.—Róòmù 2:15.
3. Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti máa fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì?
3 ‘Kì Í Ṣe Ní Ìfiwéra Pẹ̀lú Ẹlòmíràn’: Kò bọ́gbọ́n mu láti máa fi ara wa wé àwọn ẹlòmíràn tàbí ká máa fi ohun tá a lè ṣe nísinsìnyí wé ohun tá a ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ nígbà tára wa ṣì le dáadáa. Ipò téèyàn wà máa ń yí pa dà. Ohun tí agbára wa gbé sì yàtọ̀ síra. Fífi ara wa wé àwọn ẹlòmíì sábà máa ń fa ẹ̀mí ìbánidíje tàbí kéèyàn máa rò pé òun ò já mọ́ nǹkan kan. (Gál. 5:26; 6:4) Jésù kò fi àwọn èèyàn wé ara wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń gbóríyìn fún wọn ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá ṣe.—Máàkù 14:6-9.
4. Àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la lè kọ́ nínú àkàwé Jésù nípa tálẹ́ńtì?
4 Nínú àkàwé Jésù nípa tálẹ́ńtì, òṣìṣẹ́ kọ̀ọ̀kan gba tálẹ́ńtì “ní ìbámu pẹ̀lú agbára ìlèṣe-nǹkan tirẹ̀.” (Mát. 25:15) Nígbà tí ọ̀gá náà dé, tó sì béèrè nípa bí wọ́n ṣe ṣiṣẹ́ sí, ó gbóríyìn fún àwọn òṣìṣẹ́ tó ti ṣiṣẹ́ kára ní ìbámu pẹ̀lú bí agbára àti ipò wọn ṣe mọ, wọ́n sì bọ́ sínú ìdùnnú ọ̀gá wọn. (Mát. 25:21, 23) Bí àwa náà ṣe ń jẹ́ kí ọwọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé inú Ọlọ́run ń dùn sí wa, ìyẹn ló sì máa jẹ́ ká ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà!