ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/13 ojú ìwé 2
  • Ẹ Fi Ọ̀yàyà Kí Wọn Káàbọ̀!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Fi Ọ̀yàyà Kí Wọn Káàbọ̀!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Máa Jẹ́rìí Lọ́nà Tó Múná Dóko
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Ẹ Kí Àwọn Tá A Pè Káàbọ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Báwo La Ṣe Lè Ran Àwọn Tó Bá Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Lọ́wọ́?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ẹ Fi Ọpẹ́ fún Jèhófà Nítorí Inú Rere Rẹ̀ Onífẹ̀ẹ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 3/13 ojú ìwé 2

Ẹ Fi Ọ̀yàyà Kí Wọn Káàbọ̀!

1. Ìgbà wo la máa ń láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti jẹ́rìí fún àwọn èèyàn? Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

1 A máa ń láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti jẹ́rìí fún àwọn èèyàn nígbà Ìrántí Ikú Kristi. Lọ́dún yìí, à ń retí àwọn àlejò tó máa lé ní mílíọ̀nù mẹ́wàá kárí ayé. Wọ́n máa gbọ́ nípa ẹni méjì pàtàkì tó fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ jù lọ hàn sí wa nípasẹ̀ ìràpadà. (Jòh. 3:16; 15:13) Wọ́n tún máa kọ́ nípa àwọn ìbùkún tí wọ́n máa rí gbà látàrí ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa. (Aísá. 65:21-23) Àmọ́ olùbánisọ̀rọ̀ nìkan kọ́ ló máa jẹ́rìí lọ́jọ́ náà. Gbogbo wa pátá la máa láǹfààní láti jẹ́rìí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ nípa fífi ọ̀yàyà kí àwọn àlejò káàbọ̀.—Róòmù 15:7.

2. Báwo la ṣe lè fi ọ̀yàyà kí àwọn àlejò káàbọ̀?

2 Dípò tí wàá fi lọ jókòó jẹ́ẹ́, tí wàá sì máa retí pé kí ìtòlẹ́ṣẹẹṣẹ bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ náà, o lè lo ìdánúṣe láti kí àwọn tó bá jókòó nítòsí rẹ, kó o sọ orúkọ rẹ fún wọn, kó o sì kí wọn káàbọ̀. Àwọn àlejò lè má mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ àti ohun tó yẹ káwọn ṣe. Àmọ́ tá a bá fi ọ̀yàyà kí wọn káàbọ̀, tá a sì rẹ́rìn-ín músẹ́ sí wọn, ìyẹn á fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Tá a bá fẹ́ mọ̀ bóyá ìwé ìkésíni tí ẹnì kan rí gbà ló mú kó wá, a lè béèrè bóyá ìgbà àkọ́kọ́ tó máa wá sí ìpàdé wa nìyẹn tàbí bóyá ó mọ ẹnì kan nínú ìjọ wa. A tiẹ̀ lè ní kó jókòó tì wá, ká lè jọ lo Bíbélì àti ìwé orin wa. Tó bá jẹ́ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba la ti fẹ́ ṣe Ìrántí Ikú Kristi, a lè mú un rìn yíká Gbọ̀ngàn Ìjọba. Tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà bá parí, á dáa ká sún mọ́ wọn ká lè dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n bá ní. Tó bá jẹ́ pé ẹ máa ní láti tètè kúrò nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, kí àwọn tó kàn lè tètè wọlé, o lè sọ pé: “Màá fẹ́ láti mọ bẹ́ ẹ ṣe gbádùn ìpàdé wa yìí sí. Báwo ni mo ṣe lè rí yín?” Kó o sì ṣètò bí wàá ṣe lọ bẹ̀ ẹ́ wò. Kí àwọn alàgbà rí i pé àwọn sún mọ́ àwọn akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ tó bá wá, kí wọ́n sì gbà wọ́n níyànjú.

3. Kí nìdí tó fi yẹ ká lo ìdánúṣe láti kí àwọn àlejò káàbọ̀ síbi Ìrántí Ikú Kristi?

3 Ìgbà àkọ́kọ́ ló máa jẹ́ fún ọ̀pọ̀ àwọn àlejò tó máa wá lọ́jọ́ yẹn láti fojú ara wọn rí bí àwa èèyàn Jèhófà ṣe ń láyọ̀, tá a sì ń gbádùn àlàáfíà àti ìṣọ̀kan nínú Párádísè tẹ̀mí. (Sm. 29:11; Aísá. 11:6-9; 65:13, 14) Irú ojú wo ni wọ́n á máa fi wo àwa èèyàn Jèhófà lẹ́yìn ọjọ́ yẹn? Bá a bá ṣe kí wọn káàbọ̀ wà lára ohun tó máa pinnu irú ojú tí wọ́n á fi máa wò wá.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́