ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/11 ojú ìwé 1
  • A Máa Jẹ́rìí Lọ́nà Tó Múná Dóko

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Máa Jẹ́rìí Lọ́nà Tó Múná Dóko
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ Fi Ọ̀yàyà Kí Wọn Káàbọ̀!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Báwo La Ṣe Lè Ran Àwọn Tó Bá Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Lọ́wọ́?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ẹ Kí Àwọn Tá A Pè Káàbọ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Ẹ Fi Ọpẹ́ fún Jèhófà Nítorí Inú Rere Rẹ̀ Onífẹ̀ẹ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 4/11 ojú ìwé 1

A Máa Jẹ́rìí Lọ́nà Tó Múná Dóko

1. Ní àfikún sí àsọyé, kí ló tún lè wú àwọn àlejò lórí nígbà Ìrántí Ikú Kristi? Ṣàlàyé.

1 Nígbà wo? Ní alẹ́ tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. A ti sapá gan-an láti pe àwọn èèyàn. Kì í ṣe ohun tí àwọn àlejò bá gbọ́ nìkan ló máa wú wọn lórí. Lẹ́yìn tí obìnrin kan lọ síbi Ìrántí Ikú Kristi, ó sọ ohun tó rí níbẹ̀, ó rí i bí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ṣe ń fi ọ̀yàyà kí ara wọn, bí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà ṣe lẹ́wà tó sì mọ́ tónítóní, tó sì jẹ́ pé àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ló kọ́ ọ tí wọ́n sì ń bójú tó o. Torí náà, kì í ṣe alásọyé nìkan ló máa ń jẹ́rìí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọdún tí a máa ń sẹ yìí, gbogbo wa la máa ń jẹ́rìí.—Éfé. 4:16.

2. Báwo ni ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè jẹ́rìí fún àwọn àlejò?

2 Fi Ọ̀yàyà Kí Àwọn Àlejò: Tá a bá kí àwọn àlejò pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ àti ọ̀yàyà, ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́rìí fún wọn. (Jòh. 13:35) Ká tiẹ̀ sọ pé kò lè ṣeé ṣe fún ẹ láti bá gbogbo èèyàn sọ̀rọ̀, o ṣì lè bá àwọn tó wà nítòsí rẹ sọ̀rọ̀ tọ̀yàyàtọ̀yàyà kẹ́ ẹ lè túbọ̀ mọ ara yín. (Héb. 13:1, 2) Fara balẹ̀ ṣàkíyèsí àwọn àlejò tó jọ pé wọn ò mọ ẹnikẹ́ni. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tá à ń ṣe ìpolongo ni wọ́n gba ìwé ìkésíni. O lè bi wọ́n pé, “Ṣé ìgbà àkọ́kọ́ tó o máa wá síbí rèé?” O lè ní kí wọ́n wá jókòó sọ́dọ̀ rẹ, kó o sì sọ fún wọn pé wàá dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí tí wọ́n bá ní. Tó bá jẹ́ pé gbàrà tí ìjọ yín bá ṣe tan lẹ ti máa jáde kí ìjọ míì lè ráyè lo gbọ̀ngàn náà, o lè sọ pé: “Màá fẹ́ láti mọ bó o ṣe gbádùn Ìrántí Ikú Kristi náà tó. Ṣé o lè sọ ibi tó ò ń gbé fún mi?”

3. Báwo la ṣe lè fi ìfẹ́ hàn sí àwọn aláìṣedéédéé?

3 Ẹ Fìfẹ́ Hàn sí Àwọn Aláìṣedéédéé: Kò sí àní-àní pé àwọn akéde tí wọ́n ti di aláìṣedéédéé máa wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lọ́jọ́ yẹn, tó fi mọ́ àwọn tó jẹ́ pé kìkì Ìrántí Ikú Kristi tá à ń ṣe lẹ́ẹ̀kàn lọ́dún nìkan ni wọ́n máa ń wá. Fìfẹ́ hàn sí wọn, kó o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé inú rẹ dùn gan-an láti rí wọn. (Róòmù 15:7) Àwọn alàgbà lè lọ sí ilé wọn lẹ́yìn náà, kí wọ́n lè lọ fún wọn ní ìṣírí pé kí wọ́n máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ nìṣó. Àdúrà wa ni pé kí ọ̀pọ̀ lára àwọn tó máa wá síbi Ìrántí Ikú Kristi rí ìṣírí gbà láti máa fògo fún Ọlọ́run, kì í ṣe nítorí ohun tí wọ́n gbọ́ nìkan, àmọ́ nítorí ‘àwọn iṣẹ́ àtàtà wa tí wọ́n fojú rí.’—1 Pét. 2:12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́