Àpótí Ìbéèrè
◼ Ṣé ó yẹ kí arábìnrin kan borí rẹ̀ tóun àti arákùnrin kan bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́nu ọ̀nà?
Tí arábìnrin kan bá lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹnì kan tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, arábìnrin náà gbọ́dọ̀ fi nǹkan borí bí arákùnrin tó jẹ́ akéde Ìjọba Ọlọ́run bá wà níbẹ̀. (1 Kọ́r. 11:3-10) Ilé Ìṣọ́ July 15, 2002, ojú ìwé 27 sọ pé: “Èyí jẹ́ ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá a ti ṣètò rẹ̀ tẹ́lẹ̀, èyí tí ẹni tí ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ti jẹ́ olùdarí ní ti gidi. Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, ìkẹ́kọ̀ọ́ náà kò yàtọ̀ sí kíkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ nínú ìjọ. Bó bá jẹ́ pé obìnrin Ẹlẹ́rìí tó ti ṣèrìbọmi ló fẹ́ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ níbi tí ọkùnrin Ẹlẹ́rìí tó ti ṣèrìbọmi wà, ó di dandan kí obìnrin náà fi nǹkan borí.” Ìlànà yìí kan náà ni wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé níbi yòówù kí wọ́n ti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ì báà jẹ́ nínú ilé tàbí lẹ́nu ọ̀nà tàbí láwọn ibòmíì.
Àmọ́ tí wọn kò bá tíì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹnu ọ̀nà pẹ̀lú ẹni tí wọ́n lọ bẹ̀ wò náà, kò pọn dandan pé kí arábìnrin náà fi nǹkan borí tí akéde Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ arákùnrin bá wà níbẹ̀, kódà tó bá jẹ́ pé ìdí tí wọ́n fi pa dà lọ bẹ ẹni náà wò ni láti fi bí a ṣe máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án tàbí láti fi ohun tó wà nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án. Kí a tó lè dá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́nu ọ̀nà sílẹ̀ a gbọ́dọ̀ ti kọ́kọ́ máa ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ onítọ̀hún léraléra, ká sì ti kíyè sí i pé ẹni náà ń tẹ̀ síwájú, gbogbo èyí sì máa gba àkókò díẹ̀. Nítorí náà, àwọn akéde ní láti gbé ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan yẹ̀ wò, kí wọ́n má sì retí ohun tó pọ̀ jù tí wọ́n bá fẹ́ pinnu ìgbà tó yẹ kí arábìnrin fi nǹkan borí.