ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/14 ojú ìwé 3
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?—Apá Kejì
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Gbígbé Ìdílé Tó Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Máa Lo Ìkànnì Wa Láti Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
km 5/14 ojú ìwé 3

Àpótí Ìbéèrè

◼ Kí làwọn ọmọ gbọ́dọ̀ kọ́ kí ẹ̀kọ́ òtítọ́ lè jinlẹ̀ nínú wọn?

Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni máa ń ṣe kí wọ́n lè tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfé. 6:4) Bí àpẹẹrẹ, àwọn òbí ti rí i pé ó ṣàǹfààní káwọn máa jíròrò ẹsẹ ojúmọ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn láràárọ̀. Nígbà Ìjọsìn Ìdílé àti láwọn àkókò míì, ìdílé lè wo fídíò kan pa pọ̀ kí wọ́n sì jíròrò rẹ̀, wọ́n lè sọ̀rọ̀ nípa kókó kan pàtó nínú àpilẹ̀kọ Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè, wọ́n lè fi ìtàn Bíbélì kan ṣe àwòkẹ́kọ̀ọ́, tàbí kí wọ́n ṣe àwọn ìfidánrawò kan. Àmọ́, kí àwọn ọmọ lè “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú,” a gbọ́dọ̀ kọ́ wọn ní àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀.—Héb. 6:1.

Ẹ jẹ́ ká ronú nípa ohun tá a máa ń kọ́ àwọn tá à ń pàdé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa. Nígbà tá a bá kọ́kọ́ pàdé ẹnì kan tàbí nígbà tá a bá pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹni tá a ti wàásù fún, a sábà máa ń gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹni náà látinú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Tá a bá parí ìwé yẹn, a máa ń lo ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run.’ Kí nìdí? Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni máa jẹ́ kí ẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ inú Bíbélì. Nígbà tó jẹ́ pé ìwé ‘Ìfẹ́ Ọlọ́run’ máa kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa fi àwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù lójoojúmọ́ nínú ìgbésí ayé wọn. Táwọn ẹni tuntun bá kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé méjèèjì yìí, ó máa jẹ́ kí wọ́n lè “ta gbòǹgbò” nínú Kristi kí wọ́n sì “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.” (Kól. 2:6, 7) Ǹjẹ́ àwọn ìwé yìí náà máa ṣe àwọn ọmọ wa láǹfààní? Ó yẹ ká kọ́ àwọn náà nípa ìràpadà, Ìjọba Ọlọ́run àti ipò tí àwọn òkú wà. Ó yẹ kí wọ́n mọ ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà àti bá a ṣe mọ̀ pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí. Ó gbọ́dọ̀ dá wọn lọ́jú pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà là ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́. Ó tún yẹ kí àwọn ọ̀dọ́ lóye àwọn ìlànà Bíbélì, kí wọ́n sì mọ bí wọ́n ṣe lè kọ́ “agbára ìwòye wọn.” (Héb. 5:14) Àmọ́, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí ronú nípa ọjọ́ orí àwọn ọmọ wọn àti ibi tí òye wọn dé. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ọmọdé ló lè bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ kódà nígbà tí wọ́n ṣì kéré gan-an.—Lúùkù 2:42, 46, 47.

Ohun kan tá a gbé ka ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni máa wà lórí ìkànnì jw.org láìpẹ́, ó máa ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ lè rí i lórí Ìkànnì wa tẹ́ ẹ bá wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀWỌN Ọ̀DỌ́. Lọ́jọ́ iwájú, a tún máa ṣe èyí tá a gbé ka ìwé ‘Ìfẹ́ Ọlọ́run.’ Àmọ́ ṣá o, ẹ tún lè lo àwọn ìwé náà fúnra wọn. Àwọn òbí lè pinnu láti lo ohun tó wà lórí ìkànnì wa yìí nígbà Ìjọsìn Ìdílé wọn, tí wọ́n bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀kan lára ọmọ wọn, tàbí tí wọ́n bá ń kọ́ ọmọ kan bó ṣe lè máa dá kẹ́kọ̀ọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́