Máa Lo Ìkànnì Wa Láti Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ
1. Kí nìdí tá a fi ṣe apá tá a pè ní “Àwọn Ọmọdé” lórí Ìkànnì wa?
1 Gbogbo èèyàn lọ́mọdé lágbà ni Ìkànnì jw.org wà fún. Apá tá a pè ní “Àwọn Ọmọdé” (lábẹ́ abala Ẹ̀kọ́ Bíbélì lo ti máa rí ìlujá tá a pè ní Àwọn Ọmọdé) máa jẹ́ kí àwọn ọ̀dọ́ túbọ̀ sún mọ́ àwọn òbí wọn, kí wọ́n sì tún sún mọ́ Jèhófà. (Diu. 6:6, 7) Báwo lo ṣe lè fi apá yìí kọ́ àwọn ọmọ rẹ?
2. Báwo lo ṣe lè yan ẹ̀kọ́ tó bá ọjọ́ orí àwọn ọmọ rẹ mu?
2 Lo Ẹ̀kọ́ Tó Bá Kálukú Mu: Àwọn ọmọ máa ń yàtọ̀ síra. (1 Kọ́r. 13:11) Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kó o yan ẹ̀kọ́ tó bá ọjọ́ orí ọmọ kọ̀ọ̀kan mu. Báwo lo ṣe lè ṣe é? Bi ara rẹ ní àwọn ìbéèrè yìí: ‘Kí ni àwọn ọmọ mi máa ń nífẹ̀ẹ́ sí? Báwo lohun tí wọ́n lè lóye ṣe pọ̀ tó? Báwo ló ṣe máa ń pẹ́ tó kí nǹkan tó bẹ̀rẹ̀ sí í sú wọn?’ Bí àwọn ọmọ rẹ kò bá tíì ju ọmọ ọdún mẹ́ta lọ, o lè jíròrò àwọn ìtàn tó wà ní apá tá a pè ní “Ẹ̀kọ́ Bíbélì” pẹ̀lú wọn. Àwọn ìdílé míì máa ń gbádùn àwọn ìtàn Bíbélì tó wà ní apá tá a pè ní “Kọ́ Ọmọ Rẹ.” Jẹ́ ká tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan míì tó o tún lè ṣe.
3. Ọ̀nà tó ṣàǹfààní wo làwọn òbí lè gbà lo àwọn ìtàn àtàwọn ẹ̀kọ́ tó wà níbi tá a pè ní “Family Worship Projects,” ìyẹn iṣẹ́ ìjọsìn ìdílé?
3 Iṣẹ́ Ìjọsìn Ìdílé: Àwọn olórí ìdílé lè lo àwọn iṣẹ́ yìí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tó o bá fẹ́ mọ bó o ṣe máa lo àwọn ìtàn àtàwọn ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀, tẹ bọ́tìnnì tá a pè ní wàá jáde, kí o lè ka “Parents’ Guide,” ìyẹn ìtọ́ni tó wà fún àwọn òbí nípa iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan. Fi àwọn eré aláwòrán irú bíi kíkun àwòrán kọ́ àwọn ọmọ rẹ kékeré. Ran àwọn ọmọ tó bá dàgbà díẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè parí ẹ̀kọ́ tó wà níbẹ̀. Ìtàn tàbí ẹ̀kọ́ Bíbélì kan náà ni gbogbo ẹ̀kọ́ tó wà lábẹ́ iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan tọ́ka sí, torí náà gbogbo àwọn ọmọ ló lè jọ ṣe iṣẹ́ kan náà nígbà Ìjọsìn Ìdílé, láìka ọjọ́ orí wọn sí.
4. Kí ló wà nínú apá tá a pè ní “Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà”?
4 Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà: Àwọn fídíò, orin àtàwọn ẹ̀kọ́ tó wà ní apá yìí lórí Ìkànnì wa máa ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti gbin Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú àwọn ọmọ wọn kéékèèké. (Diu. 31:12) Fídíò kékeré kọ̀ọ̀kan kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì. Àwọn eré bíi wíwá-nǹkan-rí máa ń jẹ́ kí àwọn ẹ̀kọ́ náà túbọ̀ ṣe kedere. Àwọn ọmọdé fẹ́ràn orin, ó sì máa ń jẹ́ kí wọ́n lè rántí ohun tí wọ́n kọ́, torí náà, a máa ń gbé àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run àti àwọn orin tá a dìídì kọ fún àwọn ọmọdé sórí ìkànnì wa déédéé.
5. Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn òbí bẹ Jèhófà pé kó ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè kọ́ àwọn ọmọ wọn?
5 Ẹ̀yin òbí, Jèhófà fẹ́ kẹ́ ṣe ojúṣe yín gẹ́gẹ́ bí bàbá àti ìyá ní àṣeyanjú. Nítorí náà, ẹ bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn yín lọ́wọ́ kẹ́ ẹ lè kọ́ àwọn ọmọ yín ní òtítọ́. (Oníd. 13:8) Pẹ̀lú àtìlẹ́yìn Jèhófà, ẹ máa kọ́ àwọn ọmọ yín kí wọ́n lè di “ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.”—2 Tím. 3:15; Òwe 4:1-4.